2025
Ẹ̀wọ̀n Liberty
Oṣù Kẹjọ 2025


“Ẹ̀wọ̀n Liberty,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹjọ 2025, 26–28.

Àwọn ọ̀rọ̀ oṣoòṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹjọ 2025

Ẹ̀wọ̀n Liberty

Àwọn ilé tó njóná àti àwọn ọkùnrin tó nbínú pẹ̀lú ìbọn

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní Missouri kò fẹ́ràn àwọn ènìyàn mímọ́. Gómìnà rán àwọn ọmọ-ogun láti mú kí wọ́n lọ.

Ọkùnrin tí ó wà lórí ẹṣin kan ntọ́ka idà sí Joseph Smith

Àwọn ọmọ-ogun mú Joseph Smith àti àwọn olórí Ìjọ míràn. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ nrẹ́rin nípa àwọn ohun búburú tí wọ́n ti ṣe sí àwọn Ènìyàn-Mímọ́.

Joseph Smith pẹ̀lú àwọn ẹ̀wọ̀n ní àwọn ọrùn ọwọ́ rẹ̀, ní ìdìde dúró tí ó sì nbá àwọn ọkùnrin sọ̀rọ̀.

Joseph dìde ó sì kígbe, “Ìdákẹ́jẹ́!” Ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára Ọlọ́run. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà bẹ̀bẹ̀ wọ́n sì dẹ́kun ọ̀rọ̀ sísọ.

Joseph Smith àti àwọn ọkùnrín miran nínú ẹ̀wọ̀n Liberty nwò pẹ̀lú ìbànújẹ́ àti ojú kíkorò

Lẹ́hìnwá, wọ́n fi Jósẹ́fù àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí ẹ̀wọ̀n ní ìlú kan tí a pè ní Liberty. Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tutù, ó kéré, ó sì dúdú. Koríko ẹlẹ́gbin nìkan ni wọ́n ní láti sùn lé lórí. Oúnjẹ tí wọ́n fún wọn mú wọn ṣàìsàn.

Joseph Smith nsọkún ọkùnrin kan sì ntù ú nínú

Joseph ṣàníyàn nìtorí àwọn Ènìyàn-Mímọ́. Ṣùgbọ́n kò le ṣe ohunkohun láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Joseph Smith ní ìkunlẹ̀ láti gbàdúrà nínú ẹ̀wọ̀n

Joseph gbàdúrà púpọ̀. Ó béèrè bóyá Ọlọ́run ti gbàgbé nípa òun àti àwọn ọmọ Ìjọ.

Joseph Smith ní ìkunlẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n, tí nwo òkè sí ìhà ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó ntàn nínú fèrèsé kékeré kan

Ọlọ́run dáhùn àdúrà Joseph. Ó wí pé, “Ọmọ mi, àlàáfíà ni fún ọkàn rẹ.” Ọlọ́run sọ fún Joseph pé àwọn ìpọ́njú rẹ̀ kì yíò wà títí láé àti pé yíò jẹ́ fún rere rẹ̀. Ó ṣèlérí pé òun yíò wà pẹ̀lú Joseph “láé àti títí láéláé” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 121:7, 46).

Ojú-ewé Kíkùn

Mo Lè Jẹ́ Bíi Ìmọ́lẹ̀ Kan Sí Àwọn Ẹlòmíràn

Iṣẹ́ ṣíṣe ojú-ewé kíkùn pẹ̀lú ilé ìmọ́lẹ̀ kan, etí òkun àpáta, àti ọkọ̀ ojú omi kékeré kan nínú òkun

Ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert

Báwo ni o ṣe jẹ́ àpẹrẹ rere fún àwọn elòmíràn?