2025
Ẹnití Ọlọ́run Kìí Ṣe
Oṣù Kẹjọ 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣoòṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹjọ 2025

Ẹnití Ọlọ́run Kìí Ṣe

Àwọn Òtítọ́ Márun nípa Baba Wa Ọ̀run

A lè kọ́ ẹ́kọ́ púpọ̀ nípa ẹnití Ọlọ́run jẹ́ nígbà tí a bá ní òye ẹnití Òun kìí ṣe.

Ọ̀dà àti búrọ̀ṣì-ọ̀dà

ìjúwe láti ọwọ́ Thomas Arnaud

Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún títóbi jùlọ ti ìmúpadàbọ̀sípò ni pé Ọlọ́run ti tún fi ara Rẹ̀ àti ìwà Rẹ̀ hàn bíi olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Ṣùgbọ́n nígbà míran a nní àwọn ìrònú tàbí àwọn èrò iorí nípa Ọlọ́run tí ó kàn jẹ́ pé kìí ṣe òtítọ́. Nígbàtí èyí bá ṣẹlẹ̀, a lè kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ nípa ẹnití Ọlọ́run jẹ́ nípa níní òye ẹnití Òun kìí ṣe.

Ọlọ́run kìí ṣe ènìyàn àìdámọ̀ tí ó wà lórí ìtẹ́ jìna, jìnà réré.

Òun ni Baba wa, ó jẹ́ ìyanu àní ju baba ayé tó dára jùlọ tí o lè fojú-inú wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rántí ìwàláàyè wa ṣáájú ayé íkú pẹ̀lú Rẹ̀, Ó mọ̀ wá bí ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ní pípé. Ó ní àgọ́ ara pípé ẹran-ara àti egungun, a sì wà ní àwòrán Rẹ̀.

Bí o bá tiraka láti fojúinú wo bí Ọlọ́run ṣe rí, àpẹẹrẹ pípé kan wà: Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Krístì wípé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè: kò sí ẹnití ó le wá sọ́dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ mi. Ìbáṣepé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú” (Jòhánnù 14:6–7). Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, tí a bá fẹ́ mọ bí Bàbá Ọ̀run ṣe rí, a lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù Kristi ṣe rí! Wọ́n fi jíjẹ́-pípé wà ní ìṣọ̀kan nínú èrò.

Ọlọ́run kìí ṣe ẹnìkan tí iṣẹ́ dí lọ́wọ́ púpọ̀jù fún ọ.

Ní tòótọ́, ríràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìyè ayérayé ni iṣẹ́ Rẹ̀ àti ògo Rẹ̀. Ìwọ ni àfojúsùn Rẹ̀ àkọ́kọ́! Òun kò ní ààlà nípasẹ̀ àkókò bí àwa ti wà. Dé ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú àdúrà nígbàkúgbà. Lẹ́hìnnáà tẹ́tísí àwọn ọ̀nà púpọ̀ tí Ó fi ndáhùn.

Ọlọ́run kìí ṣe ẹnìkan tí ó nfi agbára mú ọ láti tẹ̀lé E.

Alàgbà Dale G. Renlund ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá kọ́ni nígbàkan pé, “Àfojúsùn Bàbá wa Ọ̀run nínú ṣíṣe òbí kìí ṣe láti jẹ́kí àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe ohun tí ó tọ́; ó jẹ́ láti jẹ́kí àwọn ọmọ Rẹ̀ yàn láti ṣe ohun tí ó tọ́ kí wọ́n sì dàbí Rẹ̀ níkẹhìn.” Òun yíò pè ọ́, gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn, yíò sì kọ́ ọ ní òtítọ́, ṣùgbọ́n Òun kì yíò mú agbára rẹ láti yàn kúrò nípa fífi ipá mú ọ láti tẹ̀lé E.

Ọlọ́run kìí ṣe ẹnìkan tí ó ngbìyànjú làti mú ọ nínú ṣíṣe nkan tí kò tọ́ kí ó le jẹ ọ́ níyà.

Dípò bẹ́ẹ̀, bí Alàgbà Patrick Kearon ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá ṣe sọ ọ́, “Ọlọ́run nlépa yín láìsinmi,” tí ó túmọ̀ sí pé Òun kò ní jáwọ́ nínú gbígbìyànjú láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti padà sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ó mọ̀ pé gbogbo wa ní àdánidá yíò dojúkọ àwọn ohun líle nígbàtí a bá ṣe àṣìṣe. Nítorí náà Ó pèsè ọ̀nà fún wa láti sọ wá di mímọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kí a sì rí okun nípasẹ̀ Ètùtù Ọmọ Rẹ̀.

Ọlọ́run kìí ṣe ẹnìkan tí ó ndúró dè ọ́ láti “tó tán” tàbí “jẹ́ pé” kí Ó tó lè fẹ́ràn rẹ.

Ìfẹ́ Rẹ̀ sí ọ jẹ́ àílópin. Ó fẹ́ràn rẹ nísinsìnyí gan-an, bíi aláìpé bí ìwọ ṣe jẹ́! Ààrẹ Jeffrey R. Holland, Aṣojú Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, fúnni ní àlàyé tó lágbára kan nípa òtítọ́ yi: “‘Ẹ wá bí ẹ̀yin ti rí,’ olùfẹ́ni Baba kan sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, ṣùgbọ́n Ó fi kún un pé, ‘Ẹ máṣe gbèrò láti dúró bí ẹ ṣe wà.’ A nrẹ́rin músẹ́ a sì nrántí pé Ọlọ́run ti pinnu làti ṣe wá díẹ̀ síi ju bí àwa ti rò pé a lè jẹ́.” Pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìgbaniníyànjú pípé, Baba Ọ̀run ngbìyànjú láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dàbí Rẹ̀ kí o sì gba ohun gbogbo tí Ó ní, ìṣísẹ̀ kan ní àkókò kan.

Ẹnití Ọlọ́run JẸ́

Ọ̀nà tó dára jùlọ láti mọ Baba rẹ Ọ̀run ni láti máa ní àwọn ìrírí pẹ̀lú Rẹ̀ léraléra. Báwo? Kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀ àti Ọmọ Rẹ̀ làti inú àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè. Gbàdúrà sí I. Pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Lo àkókò ìdákẹ́jẹ́, ti araẹni ní jíjọ́sìn sí I ní ilé ìjọsìn, nínú tẹ́mpìlì, àti ní àwọn ibi mímọ́ mìran. Dá àwọn májẹ̀mú kí o sì pa wọ́n mọ́ pẹ̀lú Rẹ̀. Òun yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ẹnití Òun jẹ́ àti bí Òun ti nímọ̀lára nípa rẹ.