2025
Òtítọ́ ti Ìgbésí Ayé Wa
Oṣù Kẹjọ 2025


“Òtítọ́ ti Ìgbésí Ayé Wa,” Lìàhónà, Oṣù Kẹjọ. 2025.

Ọ̀rọ̀ osooṣù Lìàhónà , Oṣù Kẹjọ 2025

Òtítọ́ ti Ìgbésí Ayé Wa

Olùfẹ́ni Baba wa Ọ̀run ti ṣe àfihàn àwọn òtítọ́ ti ìgbà wa tí ó ti kọjá, ti ìsisìnyí, àti ti ọjọ́ iwájú, pẹ̀lú bí a ṣe lè gba èyí tó tóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn.

Ilé ìtajà N.K. Whitney & Co.

Lórí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì nínú yàrá kékeré kan, tó kún fọ́fọ́ lókè ilé ìtajà Newel K. Whitney ní Kirtland, Ohio, ní Ọjọ́ Kejìlélógún Oṣù Kínní, Ọdún 1833, àwọn alàgbà ìjọ péjọ pẹ̀lú Wòlíì Joseph Smith. Ní Oṣù Kejìlá ọdún to ṣaájú, Joseph ti gba ìfihàn kan tó ndarí rẹ̀ làti gbé ilé-ìwé kan kalẹ̀ nípàtàkì láti pèsè àwọn arákùnrin sílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́́ ìránṣẹ́ ìhinrere.

“Mo fún yín ní àṣẹ kan,” ni Olúwa ti kéde, “pé ẹ̀yin ó máa kọ́ ara yín ní ẹ̀kọ́ ti ìjọba náà.

“Ẹ kọ́ni láìsimi oore ọ̀fẹ́ mi yíò sì wà pẹ̀lú yín, kí a lè kọ́ yín ní pípé síi nínú àlàyé ìmọ̀, nínú ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, nínú ẹ̀kọ́, nínú òfin ìhìnrere, nínú ohun gbogbo tí ó ní í ṣe sí ìjọba Ọlọ́run, tí ó yẹ fún yín láti mọ̀; …

“KÍ ẹ̀yin ó lè wà ní ìmúrasílẹ̀ nínú ohun gbogbo nígbàtí èmi yíò tún rán yín lẹ́ẹ̀kansíi láti gbé ìpè náà ga èyítí èmi ti pè yín sí, àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú èyítí mo ti fi àṣẹ fún yín” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:77–78, 80).

“Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Wòlíì” yìí bí a ti pè é, pèsè ìtújáde àgbàyanu nípa tẹ̀mí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí Ìjọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ni a kọ́ níbẹ̀. Lóni àgbáyé jẹ́ ibi tí ó yàtọ̀ pátápátá, ṣùgbọ́n ìtọ́sọ́nà tí Olúwa fúnni nígbànáà sì tún wúlò púpọ̀. Àwa, pẹ̀lú, gbọ́dọ̀ wá ìmọ̀ àti òtítọ́ “àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà, àti bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀ rí, àti bí wọ́n yíò ṣe wá” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:24).

obìnrin nronú jinlẹ̀ ìwé tí ó nkà

Ìwádìí Wa fún Òtítọ́

Ní àkókò tí à ngbé nínú rẹ̀ yìí, ìmọ̀ díẹ̀ wà fún wa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ní ìgbà tó kọjá, bí ó bá fẹ́ mọ nkan kan, o ní láti lọ sí ilé ìkàwé kí o sì wò ó. Lóni ẹ̀rọ ayélujára àti àwọn ẹ̀rọ àgbéléwọ́ pèsè wíwọlé sí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ àìlópin ìwífúnni tí a lè rí ní ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Inú Olúwa ndùn nígbà tí a bá fi ọgbọ́n lo àwọn ohun èlò tí ó wà ní àrọ́wọ́tó sí wa, ṣùgbọ́n Ó ti pèsè ìmọ̀ràn àìlákoko yìí pé: “Ẹ wá kiri pẹ̀lú aápọn kí ẹ sì kọ́ ara yín ní àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n; bẹ́ẹ̀ni, ẹ wá àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n nínú àwọn ìwé tí ó dára jùlọ; ẹ wá ẹ̀kọ́ kíkọ́, àní nípa ṣíṣe àṣàrò àti bákannáà nípa ìgbàgbọ́” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:118). Ó gbà wá níyànjú làti kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ayé tó wà ní àyíká wa (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:79; 93:53), ṣùgbọ́n nínú wíwákiri wa fún òtítọ́, a gbọ́dọ̀ máa wo Ọlọ́run, ẹnití ó “ní òye ohun gbogbo, ohun gbogbo sì wà níwájú rẹ̀, … ó sì ga ju ohun gbogbo lọ, … ohun gbogbo sì jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀, áti nipa” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:41).

Lára àwọn òtítọ́ tí Ọlọ́run ti fi fún wa, ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jẹ́ ìpìlẹ̀ jùlọ fún ìgbésí ayé wa lórí ilẹ̀ ayé ni pé Òun ni Baba wa Ọ̀run. Àwa ni ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí Rẹ̀. Ó mọ̀ ó sì fẹ́ràn wa ní pípé. Àti pé bíi ọmọ ẹ̀mí rẹ̀, a ní ìṣẹ̀dá àtọ̀runwá àti kádàrá. Lílóye àti títẹ́wọ́gba àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí nfún wa ní ìdánimọ̀, iyì, àti èrò tí ó bùkún tí ó sì ndarí wa nínú ìgbésí ayé wa ṣáájú ilẹ̀-ayé, yíò sì máa tẹ̀síwájú láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ nísisìnyí àti títí láé.

Àwọn ènìyàn tó nla ààrin ìkelè kọjá

A wà pẹ̀lú Baba ní Àtètèkọ́ṣe

Bí a ṣe nwá òtítọ́ àwọn nkan “bí wọ́n ṣe wà rí,” a ṣàwárí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa, Jésù Krístì: “Àti nísisìnyí, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi wà ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú Baba, èmi sì ni Àkọ́bí,” “ẹ̀yin pẹ̀lú sì wà ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú Baba” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:21, 23).

Ṣáájú ìgbé ayé wa lórí ilẹ̀ ayé, a wà ní ìgbìmọ̀ kan ní ọ̀run níbi tí Bàbá wa Ọ̀run ti fi ètò ayọ̀ ńláǹlà Rẹ̀ hàn. Wòlíì Joseph Smith kọ́ni pé ìwúnilórí Ọlọ́run fún ètò Rẹ̀ ni láti fún wa ní “àǹfààní láti tẹ̀síwájú bíi tirẹ̀ [àti] … kí a sì di gbígbéga pẹ̀lú òun fúnrarẹ̀.” Iṣẹ́ àti ògo rẹ̀ ni “láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ” (Mósè 1:39).

A lo agbára wa láti yàn a sì yàn láti tẹ̀lé èto Baba Ọ̀run. A ti ní ìbùkún láti jẹ́ bíbí sínú ayé yi, níbití a ti tẹ̀síwájú láti ní agbára láti yàn tí a sì lè ní ìrírí ikú, kọ́ ẹ̀kọ́, àti tẹ̀síwájú sí ọ̀nà ìyè ayérayé.

Lákoko ìrìn àjò ikú wa, àwa yíò ní ìrírí ìpènijà àti ìfàsẹhìn. Ṣùgbọ́n a kò nílò láti dá nìkan kojú àwọn ìpọ́njú ìgbésí-ayé. Joseph Smith kọ́ni pé Bàbá Ọ̀run, “Obi Ńlá ti àgbáyé[,] nbojúwo gbogbo ẹbí ènìyàn pẹ̀lú àbójútó ti baba àti ọ̀wọ̀ ti baba.”

Bàbá wa Ọ̀run, “Baba àwọn àánú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” yíò bùkún wa, yíò gbé wa ró, yíò sì tù wá nínú “nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìdààmú èyíkéyìí nínú, nípa ìtùnú tí àwa fúnra wa fi wá ní ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” (2 Kọ́ríńtì 1:3–4). Bí apákan pàtàkì nínú ètò Rẹ̀, Baba Ọ̀run ti pèsè ọ̀nà fún wa láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Ọgbà Gẹ́tsémánè, Ísráẹ́lì

Ọ́nà sí Baba Wa

Òtítọ́ “àwọn ǹkan bí wọ́n ti wà gan-an” (Jákọ́bù 4:13) ṣe kedere: a kò lè dá nìkan dé ibi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára wa bí ọmọ Baba wa Ọ̀run. Jésù Krístì, Àkọ́bí Ọmọ ti Baba nínu ẹ̀mí, dá májẹ̀mú láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa.

Jésù Krístì, “Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba, tó kún fún oore ọ̀fẹ́ ati òtítọ́, àní Ẹ̀mí òtítọ́, … wá ó sì gbé nínú ẹran ara, ó sì gbé ààrin wa” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:11). Ó wá láti fi ọ̀nà hàn wá láti wá ìdùnnú, ìtumọ̀, àti ayọ̀ ní ayé yi àti ni ayérayé.

“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má bà ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.

“Nítorí Ọlọ́run kò rán Ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí á lè ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là” (Jòhánnù 3:16–17).

Ìrírí Olùgbàlà lórí ilẹ̀ ayé ṣe pàtàkì. Òun “kò gba nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n ó gba oore ọ̀fẹ́ fún oore ọ̀fẹ́” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:12). Ó dàgbà títí “tí ó fi gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ògo ti Baba” àti “gbogbo agbára, ní ọ̀run àti ní ayé, ògo ti Baba sì wà pẹ̀lú rẹ̀, nítorí ó ngbé nínú rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:16–17). Olùgbàlà kọ́ni pé:

“Mo fi àwọn ohun sísọ wọ̀nyí fún yín kí ẹ̀yin ó lè lóye kí ẹ sì mọ bí a ti njọ́sìn, kí ẹ sì mọ ohun tí ẹ̀ nsìn, kí ẹ̀yin lè wá sọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, àti nígbà tí àkókò bá tó kí ẹ lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀.

“Nítorí bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ ẹ̀yin yíò gba nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀, ẹ ó sì di ṣíṣe lógo nínú mi bí ti èmi nínú Baba; nítorínáà, mo wí fún yín, ẹ̀yin yíò gba oore ọ̀fẹ́ fún oore ọ̀fẹ́” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:19–20).

Nínú Ọgbà Gethsemane àti lórí àgbélébú, Jésù Krístì gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lé orí Ara rẹ̀ Ó sì jìyà gbogbo àwọn ìkorò àti “ìrora àti àwọn ìpọ́njú àti àdánwò onírúurú gbogbo” (Álmà 7:11). Èyí “mú kí [Òun], … tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, kí ó gbọ̀nrìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ ní gbogbo ihò ara” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:18). Nípasẹ̀ Jésù Krístì nìkan àti Ètùtù àti Àjínde Rẹ ni ìgbàlà àti ìgbèga ṣeéṣe.

Nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́ Olùgbàlà àti ẹbọ ètùtù, a lè dàgbà títí tí a ó fi gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti ni ọjọ́ kan tí a ó lè mú wa wá sí jíjẹ́ pipé. Bí a bá tẹ̀lé àpẹẹrẹ Olùgbàlà tí a sì gbọ́ràn sí àwọn òfin Rẹ̀, Òun yíò tọ́ wa sọ́nà yíò sì darí wa ní ọ̀nà wa padà sí ibi ológo ti Baba wa ní Ọ̀run.

àwòrán Krístì tí ó nrìn ní ojú ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù

Krístì ní Ojú Ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù, láti ọwọ́ Michael Coleman, lè má jẹ ṣíṣe ẹ̀dà

Njẹ́ Ìwọ Yíò Gba Ẹ̀bùn Rẹ̀ Bí?

Lára àwọn òtítọ́ “ti àwọn nkan bí wọn yíò ṣe rí gan-an ” (Jákọ́bù 4:13), a kẹ́kọ̀ọ́ pé ìrírí wa ní ayérayé yíò jẹ́ pípinnu nípa yíyàn wa láti tẹ̀lé Jésù Kristi kí á sì gba àwọn ẹ̀bùn tí Ó nfúnni. Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni pé a ó “gbádùn ohun náà tí [a] ṣetán láti gbà.” Pẹ̀lú ìbànújẹ́, àwọn kan kì yíò “ṣetán láti gbádùn ohun tí nwọn le ti gbà” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:32).

Ààrẹ míṣọ́n mi, Alàgbà Marion D. Hanks (1921–2011), ẹnití ó sìn bíi Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin, kọ́ àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere rẹ̀ pé bíbéèrè fún ohun tí a ṣetán láti gba kí a sì gbádùn jẹ́ ọ̀nà kan tí a lè gbà ṣèdájọ́ ibití a wà nínú ìrìnàjò ẹ̀mí wa. “Nítorí èrè kíni ó jẹ́ fún ènìyàn tí a bá fi ẹ̀bùn kan fún un, tí òun kò sì gba ẹ̀bùn náà?” Bí a ṣe ngba àwọn ẹ̀bùn Olùgbàlà nípa wíwá àti títẹ̀lé E pẹ̀lú ìtara, a ó yọ̀ nínú ìrètí ìyè ayérayé àti “nínú ẹni náà tí ó jẹ́ olùfúnni ní ẹ̀bùn [náà]” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:33). Ẹ̀bùn yi tí a fúnni pẹ̀lú ìfẹ́ni tó bẹ́ẹ̀ “jẹ́ títóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 14:7).

Ọlọ́run ni Bàbá wa Ọ̀run. Ó mọ̀ Ó sì fẹ́ràn wa. Bi a ṣe yípadà sí I nínú wìwákiri wa fún òtítọ́, a lè faramọ́ òye, gba ọgbọ́n, tẹ́wọ́gba òtítọ́, fẹ́ràn ìwà rere, kí a sì faramọ́ ìmọ́lẹ̀ tí ó nwá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:40). Lẹ́hìnnáà a ntẹ̀síwájú ní gbogbo ìgbésí ayé wa títí “tí ọjọ́ náà yíò dé nígbàtí [àwa] yíò ní òye Ọlọ́run pàápàá, ní dídi ààyè nínú rẹ̀ àti nípasẹ̀ rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 88:49).

Èyí yíò jẹ́ ọjọ́ ológo àti aláyọ̀ nlá jùlọ.

Àwọn Àkọsílẹ̀

  1. Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Jósẹ́fù Smith (2011), 210, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  2. Àwọn Ìkọ́ni: Jósẹ́fù Smith, 39.