2025
Lẹ́hìn Ayé Yìí: Àwọn Ìdáhùn sí Àwọn Ìbèèrè Kan
Oṣù Keje 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Keje 2025

Lẹ́hìn Ayé Yìí

Lẹ́hìn Ayé Yìí: Àwọn Ìdáhùn sí Àwọn Ìbèèrè Kan

Ètò Baba Ọ̀run lè fún wa ní ìwòye àti àláfíà nípa ìgbé ayé lẹ́hìn ikú.

àkàbà kan nínú àwọsánmà

ìjúwe láti ọwọ́ Thomas Arnaud

Kíni ó nṣẹlẹ̀ lẹ́hìn tí a bá kú?

Bóyá èyí jẹ́ ìbèèrè náà nínú gbogbo ẹ̀sìn. Àwọn ìdáhùn tí a ní nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀ jẹ́ alágbára. Ayé yí kìí ṣe òpin. Nítorí pé Jésù Krístì jíìnde, ẹ̀mí wa yíò tún padà dàpọ̀ mọ́ ara wa, gbogbo wa yíò sì jíìnde ní ọjọ́ kan.

Dájúdájú, àwọn àlàyé míràn tún wà nípa ìgbé ayé lẹ́hìn ikú tí ó ti dé bá wa nípasẹ̀ ìfihàn òde òní tí ó lè dáhùn àwọn ìbéèrè míràn tí a lè ní. Ní ìhín ni díẹ̀ irú àwọn ìbèèrè díẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìdáhùn kúkurú kan.

Báwo ni àwọn ara ẹ̀mí ṣe rí?

Ẹ̀mí jẹ́ irú ọ̀ràn kan, nìkan “dídára jù tàbí mímọ́” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 131:7). Àwọn ara ẹ̀mí dàbí ara àgbàlàgbà ẹlẹ́ran ara.

Níbo ni ayé ẹ̀mí wà?

Ní ìhín, ní àyíká wa.

Kíni ó nṣẹlẹ̀ nínú ayé ẹ̀mí?

Lára àwọn nkan míràn, àwọn ẹ̀mí tó ti tẹ́wọ́gba ìhìnrere náà ni a ṣètò láti wàásù ìhìnrere fún àwọn ẹ̀mí tí kò tẹ́wọ́gba ìhìnrere. Àwọn ẹ̀mí náà lè yàn láti gbà tàbí kọ̀ ọ́.

Báwo ni awọn ara ti o jíìnde ṣe rí?

Àwọn ara tí ó jíìnde kò lè kú, wọ́n jẹ́ ẹran ara àti egungun, ó sì jẹ́ pípé. Wọ́n jẹ́ ológo àti ẹlẹ́wà. “Kò sí ohun tí ó lẹ́wà láti wò jù ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jíìnde.”

Kíni ó nṣẹlẹ̀ nínú ìjọba sẹ̀lẹ́stíà?

Àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ipò gíga jùlọ ti ìjọba ọ̀run dàbí Baba wa Ọ̀run wọ́n sì ní ìrírí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀. Wọ́n gba ohun gbogbo tí Baba ní. Wọ́n kópa nínú iṣẹ́ àti ògo Rẹ̀. A ti fi èdidì dì wọ́n nínú ìgbeyàwó fún ayérayé àti ní báyìí wọ́n ngbé nínú àwọn ẹbí ayérayé, ní níní àwọn ọmọ ẹ̀mí ayérayé ti ara wọn.

Báwo niti àwọn ènìyàn tí kò ṣègbéyàwó rí nínú ayé ṣe rí?

Baba Ọ̀run jẹ alaanu àti olododo pípé. “Olúwa ti ṣèlérí pé ní ayé àìlópin a kò ní sẹ́ ìbùkún kankan fún àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìrin rẹ̀ tí wọ́n pa àwọn òfin mọ, tí wọ́n jẹ́ olootọ sí àwọn májẹ̀mú wọn, tí wọ́n sì nfẹ́ ohun tí ó tọ́.”

A fi èdidì di àwọn òbí mi nínú tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n ní báyìí wọ́n ti kọ ara wọn sílẹ̀. Tani a fi èdidì dì mí pẹ̀lú?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “a ti bí ọ nínú májẹ̀mú” (ìyẹn, lẹ́hìn tí wọ́n ti fi èdidì di àwọn òbí rẹ nínú tẹ́mpìlì), tàbí kí wọ́n ti fi èdidì dì ọ mọ́ àwọn òbí rẹ nínú tẹ́mpìlì lẹ́hìn tí wọ́n ti fi èdidì dì ara wọn. Ní èyíkèyí ọ̀nà, àwọn ìbùkún rẹ wà láìyẹsẹ̀ pàápàá tí àwọn òbí rẹ ba pinnu láti kọ ara wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì fagilé èdidì wọn.

Àwọn yíyàn àwọn òbí rẹ kò ní ipa lórí àwọn ìbùkún rẹ. Ohun pàtàkì fún ọ ni láti jẹ́ olootọ kí o sì wá àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì fún ararẹ. Nípa ìbáṣepọ̀ ẹbí rẹ, o gbọ́dọ̀ “gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì wá ìtùnú Rẹ̀,” ní mímọ̀ pé “Baba Ọ̀run yíò rí i dájú pé ẹnìkọ̀ọ̀kan gba gbogbo ìbùkún tí ó fẹ́ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin tí àwọn yíyàn sì fi ààyè gbà.”

Kíni yíò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n kú nípa ìgbẹ̀mí araẹni?

A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n kú nípa ìgbẹ̀mí araẹni, àti pé a kò lè ṣe ìdájọ́ wọn (gẹ́gẹ́bí bíi ti gbogbo ènìyàn, nígbẹhìn). “Pẹ̀lú àwọn ìgbìyànjú tí ó dára jùlọ ti àwọn olólùfẹ́, àwọn olùdarí, àti àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, ìgbẹ̀mí araẹni kìí ṣe ohun tí a lè dílọ́wọ́ nígbàgbogbo. …

“Kò tọ́ kí ènìyàn gba ẹ̀mí ara rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run nìkan ni ó lè ṣe ìdájọ́ àwọn èrò, ìṣe, àti ipele ìjíhìn (wo 1 Sámúẹ́lì 16:7; Ẹkọ ati àwọn majẹmu 137:9). …

“Àwọn tí wọ́n pàdánù olólùfẹ́ wọn sí ìgbẹ̀mí araẹni lè rí ìrètí àti ìwòsàn nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.”

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Étérì 3:16; Ìkọ́ni Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph F. Smith (1998), 131–32.

  2. Wo Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Brigham Young (1997), 279.

  3. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 138.

  4. Wo Álmà 11:45.

  5. Wo Lúkù 24:39.

  6. Wo Álmà 11:43.

  7. Lorenzo Snow, Àwọn Ìkọ́ni Lorenzo Snow, ed. Clyde J. Williams (1996), 99.

  8. Wo Mósè 1:39.

  9. Wo Orin Dáfídì 16:11; 3 Néfì 28:10; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 76:59, 62; 130:2; 132:19–23.

  10. Dallin H. Oaks, ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 1993 (Ẹ́nsáìnì, Oṣù Kọkànlá 1993, 75).

  11. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbo: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 38.4.2.8 , Ibi Ìkàwé Ìhìnrere

  12. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 38.4.2, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.

  13. Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 38.6.20, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.