“Rí Ayọ̀ Nínu Ìrìnàjò Ìhìnrere Rẹ,” Làìhónà, Oṣù Keje 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà Oṣù, Keje 2025
Rí Ayọ̀ Nínu Ìrìnàjò Ìhìnrere Rẹ
Àbájáde tí ó ga jùlọ ti fífi ìfẹ́ wa fún Olúwa hàn nípa pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ jẹ́ àwọn ìbùkún tí ó nmú ìdùnnú àti ayọ̀ wa.
Àwòrán àwọn Ọmọ Ìjọ aláyọ̀ ti wọ́n nrìn ní Thailand láti ọwọ́ Cristina Smith
Nígbàtí mo nsìn gẹ́gẹ́bí olórí míṣọ̀n ní Japan ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo lọ sí ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀ kan ní ìlú ìgbèríko kan ní ọ̀kan lára àwọn igun tó jìnnà sí míṣọ̀n wa. Ààrẹ àgbègbè ti ṣètò fún mi láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú ọkùnrin kan tí ó ti darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní ọdún kan sẹ́hìn tí ó sì nwá láti gba ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì. Ó ní ìrètí láti gba ẹ̀bùn àtọ̀runwá tirẹ̀ lákokò tàbí súnmọ́ àjọ̀dún ọdún kan ìrìbọmi rẹ̀.
Nínú ìbarasọ̀rọ̀ wa, ọmọ ìjọ titun yìí ṣe àlàyé bí òun ṣe ní ìmoore jíjinlẹ̀ fún àwọn ìbùkún títóbi tí ó ti rí gbà lọ́dún náà láti ìgbà tí ó ti ṣe ìrìbọmi. Ó gbádùn lílọ si ìpàdé oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti àwọn ìpàdé míràn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí àwọn ìṣe ṣíṣe ẹ̀ka rẹ̀. Sí mi, ó gbé ìgbẹ́kẹ̀lé májẹ̀mú kan jáde láti inú òye èrèdí ìhìnrere rẹ̀, èyí tí ó jẹ́ arakan pàtàkì nínú rẹ̀ nísisìyí. Òun jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Krístì tí ó yípadà tí ó ti ní ìrírí ìyípadà nla ti ọkàn (wo Mòsíàh 5:2).
Ìyókù ìbárasọ̀rọ̀ wa tẹ̀lé àwòṣe ti ìrètí kan. A sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tí yíò jẹ́ arakan ti ìrírí tẹ́mpìlì rẹ. Ó dáhùn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbèèrè òṣùwọn tí ó rọ̀mọ̀ gbígba ìkaniyẹ̀ tẹ́mpìlì kan pẹ̀lú ìdánilójú.
Lẹ́hìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, mo rántí bí mo ṣe nsọ̀rọ̀ sí ààrẹ àgbègbè náà bí mo ṣe fi ìmoore hàn tó láti pàdé irú ọkùnrin olùtayọ bẹ́ẹ̀. Mo wí fun bí ó ti wú mi lórí tó pé àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àti àwọn ọmọ ìjọ náà ti rí, tí a sì fi ẹ̀mí tọ́ dàgbà, ẹnìkan bí irú ìwò àti ìlérí bẹ́ẹ̀.
Ó yà mí lẹ́nu nígbàtí ààrẹ àgbègbè náà sọ pé nígbàtí ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí í gba ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere tí ó sì nlọ sí ilé ìjọsìn ní bí ó lé ní ọdún kan sẹ́hìn, kò nílé ó sì wà ní ìṣòro gan-an—tí ó súnmọ́ àìnírètí—àwọn ipò. Ààrẹ àgbègbè náà ṣe àpèjúwe bí arákùnrin yìí ti ṣe àṣàrò ìhìnrere àti ìyípadà rẹ̀ fún sáà àwọn oṣù mélòó kan tí ó yọrí sí ìyípadà yíyanilẹ́nu rẹ̀, tí ó fi í sí ipa-ọ̀nà ti ẹ̀mí àti ti ìgbẹ́kẹ̀lé araẹni tí ó fun ní èrèdí ọgbọ́n àti ayọ̀ kan.
Ìhìnrere náà fún un ní àwòrán tó ṣe kedere nípa èrèdí ìgbé ayé rẹ̀. Àwọn ìhìnrere òtítọ́ àti iyebíye mú àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbèèrè pàtàkì ti ayé ikú wá, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pé “Ọlọ́run ni Baba wa Ọ̀run, àti pé a jẹ́ ọmọ Rẹ̀. … Ọlọ́run mọ àwa fúnra wa ó sì nífẹ̀ẹ́ wa.” Nínú ètò Rẹ̀, “Baba Ọ̀run ti… pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ìtọ́sọ́nà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti padà sí iwájú Rẹ̀.”
Irú èyí ni ìbùkún fún ọkùnrin yìí, èyítí ó wà ní àrọ́wọ́tó bákannáà fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìhìnrere Jésù Krístì.
Èrèdí Ìgbé Ayé
Nítorí Jésù Krístì mú ìhìnrere Rẹ̀ padàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith, “a ní òye èrèdí ìgbé ayé, nípa ẹni tí a jẹ́,” ni Ààrẹ M. Russell Ballard kede (1928–2023). Nínú ẹ̀rí ìkẹhìn rẹ̀ sí Ìjọ, Ààrẹ Ballard, Aṣojú Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá nígbà náà, wí pé:
“A mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́; a mọ ẹni tí Olùgbàlà jẹ́ nítorípé a ní Jósẹ́fù, ẹnití ó lọ sínú igbó súúrú àwọn igi bíi ọmọdékùnrin kan, ní wíwá ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. ….
“Mo ní ìyanu, ó sì dámi lójú pé ó rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín pẹ̀lú, nípa bí a ti jẹ́ alábùkúnfun tó láti mọ̀ ohun tí a mọ̀ nípa èrèdí wa nínú ayé, ìdí tí a fi wà ní ìhín, ohun tí a nílati máa gbìyànjú láti ṣe àti láti ṣeyọrí ní ìgbé ayé wa ojojúmọ́.”
Fún àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ìmọ̀ náà wà pẹ̀lú òye “ètò pípe” ti ìgbàlà ti Ọlọ́run. Tí a tún mọ̀ sí “ètò ìdùnnú ńlá,” “ètò ìràpadà,” àti “ètò àánú” (Álmà 42:8, 11, 15), ó “mú ohun ìjìnlẹ̀ náà kúrò nínú ìgbé ayé àti àìdánilójú kúrò ní ọjọ́ iwájú wa.” Pàtàkì sí ètò náà ni “ẹ̀kọ́ Kristi,” èyí tí ó jẹ́ àárín-gbùngbùn èrèdí ìgbésí ayé.
Nítorí pé a ní ìhìnrere, a mọ̀ pé a jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, tí a rán wá sí ayé láti dán wò, túnṣe, tí a sì múrasílẹ̀ láti “mú jáde wá nípasẹ̀ àjíìnde àwọn òkú, nípasẹ̀ ìṣẹ́gun àti ògo Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 76:39). A mọ àwọn òfin a sì kọ́ wa ní “ànító pé [a] mọ ohun rere kúrò nínú ibi” (2 Néfì 2:5). A mọ̀ pé a wa lórí ilẹ̀ ayé láti ní ìfẹ́ àti láti sìn. A sì mọ̀ pé Olùgbàlà ti pè wá láti ṣẹ́gun ayé àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà (wo Jòhánnà 16:33; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:2) ní ìmúrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì.
Bí a ṣe ndojúkọ Ọ́, ohun tí Joseph Smith pè ní “ohùn ìdùnnú ti Ìhìnrere ti Olúwa wa Jésù Krístì” yíò fún wa lókun ní àwọn ọjọ́ ìnira yíò sì mú ìtumọ̀ àti èrèdí wá sínú ayé wa àti sí ìgbé ayé àwọn ẹlòmíràn.
Eékún yíò wólẹ̀, nípasẹ̀ Dan Wilson, a kò le ṣe ẹ̀dà
Ìgboràn, Àwọn Ìbùkún, Ayọ̀
Ọlọ́run ti fún wa ní ẹ̀rí ìwà agbára òmìnira kí a lè jíhìn fún àwọn yíyàn wa (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101:78; 2 Néfì 2:16). Gẹ́gẹ́bí ara ti “àtakò nínú ohun gbogbo” (2 Néfì 2:11), A gba Sátánì láàyè láti dán wa wò láti ṣi agbára òmìnira wa lò.
Ṣùgbọ́n Olúwa Jésù Krístì, “ní mímọ̀ àjálù tí yíò wá sórí àwọn olùgbé ayé” ní ọjọ́ tiwa, pe Wòlíì Joseph Smith, “ó bá a sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, ó sì fún un ní àwọn òfin” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:17). Àwòṣe náà nípa èyítí Olúwa fi nfi àwọn òfin àti ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí àwọn wòlíì Rẹ̀ ntẹ̀síwájú ní ọjọ́ tiwa pẹ̀lú Ààrẹ Russell M. Nelson—àti fún ìdí kan náà. Ọlọ́run nfẹ́ láti darí wa sí ìdùnnú ní ayé yí àti sí ògo sẹ̀lẹ́stíà ní ayé èyí tí ó nbọ̀.
Ìgbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wá láti inú ìfọkànsìn wa àti ìfẹ́ fún Un. Olúwa Jésù Krístì Fúnrarẹ̀ kéde pé láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run “ni ìkínní àti òfin nlá” (wo Máttéù 22:37–38). Ó fúnni ní ìwòye síwájú síi nígbà tí Ó kéde pé, “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́” (Jòhánnù 14:15).
Èrè wà fún níní ìfẹ́ Olúwa àti pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Ní àkokò ìríjú yí Ó ṣe àpèjúwe “òfin kan wà, tí a ti pàṣẹ láìlèyípadà ní ọ̀run … , ní orí èyítí gbogbo àwọn ìbùkún dá lé—
“Nígbàtí a bá gba ìbùkún èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó jẹ́ nípa ìgbọ́ran sí òfin náà lórí èyí tí ó dálé” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 130:20–21).
Nípa bẹ́ẹ̀, àbájáde gíga jùlọ ti fífi ìfẹ́ wa hàn fún Olúwa nípa pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ ni àwọn ìbùkún tí ó nmú ìdùnnú àti ayọ̀ wá.
Wíwo ayé nipasẹ̀ àwọn ojú ti ìhìnrere ti a múpadàbọ̀sípò àti ìfihàn òde òní nfún wa ní híhàn kedere. Pẹ̀lú ojú ìwòye tí ó ṣe kedere nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti àyànmọ́ àtọ̀runwá, a mọ̀ pé “àwọn ohun gan-an tí yíò jẹ́ kí ayé ikú [wa] dára julọ bí ó ti lè jẹ́ gan-an ni àwọn ohun kan náà gan-an tí yíò mú kí ìgbésí ayé [wa] ní gbogbo ayérayé dára jù lọ bí ó ti lè ṣeéṣe!”
Íparí
Mo parí níbi tí mo ti bẹ̀rẹ̀, ní ìrántí ìrírí mi ní àwọn ọdún sẹ́hìn pẹ̀lú ìyípadà àìpẹ́ kan ní Japan. Nípasẹ̀ àápọn rẹ̀ àti àápọn àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àti àwọn ọmọ ìjọ, ó rí ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò. Ní rírí ìhìnrere, ó tún ṣe àwárí èrèdí rẹ̀, èyítí ó mú ìran rẹ̀ gbòòrò. Ó tún rí ètò ìdùnnú nlá náà. Ìgbọràn sí àwọn ètò májẹ̀mú ìhìnrere mú ìbùkún àti ayọ̀ wá, ní gbígbéga ní ti ara àti ti ẹ̀mí.
Ìrìn-àjò rẹ̀ tí ó darí sí dídà ọmọ Ìjọ Jésù Krístì gbà á láàyè láti di ẹlẹri Jésù Krístì. Alàgbà Patrick Kearon ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ti ṣe àpèjúwe ayọ̀ tí ó tẹ̀lé e:
“Nítorí ètò olùfẹ́ni ti Baba wa Ọ̀run fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Rẹ̀, àti nítorí ìràpadà ayé àti iṣẹ́ ti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, a lè—a sì níláti—jẹ́ ènìyàn aláyọ̀ jùlọ ní orí ilẹ̀ ayé! Àní bí awọn ìjì ayé ninu ayé tí ó nfi ìgbàkúgbà dààmú àgbáyé ṣe nlù wa lára, a lè tọ́ ọgbọ́n dídàgbà àti ìbánigbé ti ayọ̀ ati àláfíà àtinúwá nítorí ti ìrètí wa ninu Krístì ati òye wa ní ti ààyè ti arawa ninu ètò ìdùnnú rírẹwà náà.
Mo fi ìmoore mi hàn fún, àti ẹ̀rí nípa, ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadàbọ̀sípò, pẹ̀lú ètò ìdùnnú nlá tí a fi sínú rẹ̀ jíjinlẹ̀ gidi. Mo pè yín láti ṣe àbápín àwọn èso ìhìnrere kí ẹ sì ní ìmọ̀lára ayọ̀ síi ní ayé yí ní ìrìnàjò yín síwájú ìyè ayérayé.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀pada èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Keje 2025. Yoruba. 19601 779