2025
Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé mo ti ronúpíwàdà nítòótọ́ àti pé a ti dáríjì mí?
Oṣù Kẹfà 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2025

Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé mo ti ronúpíwàdà nítòótọ́ àti pé a ti dáríjì mí?

ọ̀dọ́mọbìnrin ńgbàdúrà

Wíwà ní Àyíká Kíkún, láti ọwọ́ Jenedy Page

Olúwa ti wí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, òun náà ni a ti dáríjì, àti pé èmi, Olúwa, kò rántí wọn mọ́.

“Nípa èyí ni ẹ̀yin lè mọ̀ bí ẹnìkan bá ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ẹ kíyèsíi, òun yíò jẹ́wọ́ wọn yíò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 58:42–43).

Nípa ìrònúpìwàdà àtọkànwá, a lè gba ìdáríjì. “Nígbàtí o bá ní ìmọ̀lára ìtùnú láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí, o lè mọ̀ pé agbára ètùtù ti Olùgbàlà nṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé rẹ.” Àti pé tí a bá tún yọ̀ kúrò, a tún lè ronúpìwàdà, gba ìdáríjì, kí a sì máa gbìyànjú síwájú síi.

Ní àfikún, Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá ti kọ́ni pé: “Sátánì yíò máa gbìyànjú láti mú wa gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kò ní ìdáríjì nítorí àwa lè rántí wọn. Òpùrọ́ ni Sàtánì. … Ọlọ́run kò ṣèlérí pé a kò ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Rírántí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àwọn àṣìṣe kannáà lẹ́ẹ̀kan síi. Ṣùgbọ́n tí a bá dúró ní òtítọ́ àti lódodo, ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa yíò rọlẹ̀ ní ákókò.”

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́: Atọ́nà fún Ṣíṣe àwọn Yíyàn (2022), 8.

  2. Wo Mòsíàh 26:30.

  3. Dieter F. Uchtdorf, ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2007 (Ẹ́nsígn tàbí Làìhónà, Oṣù Karun 2007, 101).