“A Ntẹ̀le Jésù Krístì nípa Dídarapọ̀ mọ́ Ọ nínú Iṣẹ́ Rẹ̀,” Làìhónà, Oṣù Kẹfà 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣoòṣù Làìhónà , Oṣù Kẹfà 2025
À Ntẹ̀lé Jésù Krístì nípa Dídarapọ̀ mọ́ Ọ nínú Iṣẹ́ Rẹ
A nkópa nínú iṣẹ́ Olùgbàlà bí a ṣe nfojúsùn sórí àwọn èrèdí Rẹ̀, pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tí a sì ní ìfẹ̀ àra wa.
Àlàyè láti inú Krístì àti Alakoso Ọ̀dọ́ Ọlọ́rọ̀, láti ọwọ Heinrich Hofmann
Nígbàtí a bá ti ṣe ìrìbọmi, a bẹ̀rẹ̀ ìlànà ti gbígbé orúkọ Jésù Krístì lé orí ara wa. Apákan lára ìlànà yi ntọ́ka si pé a ndarapọ̀ mọ́ Olùgbàlà nínú iṣẹ́ Rẹ̀. Ààrẹ Dallin H. Oaks, Olùdámọ̀ràn Ìkínní nínú Ààrẹ Ìkínní, kọ̀wé pé, “Ọ̀kan nínú àwọn ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì jùlọ ti gbígbé orúkọ Krístì lé orí wa [jẹ́] yíyọ̀ọ̀da àti fífaramọ́ láti gbé iṣẹ́ Olùgbàlà àti ìjọba Rẹ̀ lé orí wa.”
Iṣẹ́ Olùgbàlà ni “láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ti ènìyàn wá sí ìmúṣẹ” (Mósè 1:39). Àìkú jẹ ẹ̀bùn àìdíyelé tí Jésù Krístì ti fúnni ní ìdánilójú rẹ̀ nípasẹ̀ àjíǹde Rẹ̀. Ìyè ayérayé, bí ó ti wù kí ó rí, kìí ṣe ọ̀kannáà bí àìkú. Ìyè ayérayé ni ẹ̀bùn títóbi jùlọ tí Ọlọ́run lè fún aráyé (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 14:7). Ó jẹ́ láti wà láàyè títíláé bíi àwọn ẹbí níwájú Rẹ̀. Kí a tó lè gba ìyè ayérayé, a gbọ́dọ̀ di ọmọlẹ́hìn Jésù Kristi tòótọ́. Èyí túmọ̀ sí pé a gba ìhìnrere tí a múpadàbọ̀sípò nípa níní ìgbàgbọ́ nínú Olùgbàlà àti Ètùtù Rẹ̀, ríronúpíwàdà, ṣíṣe ìrìbọmi, gbígba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, dídá àti ṣíṣe ìpamọ́ àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì mọ́, àti fíforítì títi dé òpin. Fíforítì títí dé òpin jẹ́ ara dídarapọ̀ mọ́ Olùgbàlà nínú iṣẹ́ Rẹ̀.
Kíkópa pẹ̀lú ìtara
A nkópa nínú iṣẹ́ Olùgbàlà bí a ṣe nran àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ́wọ́ láti di ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì nítòótọ́ bákannáà. Nínú èyí ni pípín ìhìnrere Rẹ̀ wà, nípa bẹ́ẹ̀ kí a kó àwọn Ísráẹ́lì fífọ́nká jọ, nípa mímú àwọn ojúṣe ṣẹ nínú Ìjọ Olùgbàlà àti nípa títiraka láti dàbí Rẹ̀. Àṣeyọrí “wa [nínú iṣẹ́ Rẹ̀] kò dá lórí bí àwọn ẹlòmíràn ṣe yàn láti fèsì sí [wa], sí àwọn ìfipè [wa], tàbí sí àwọn ìṣe inúrere àtọkànwá [wa].” Ààrẹ Russell M. Nelson fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, “Nígbàkúgbà tí ẹ bá ṣe ohunkóhun tí ó nṣèrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni—ní ẹ̀gbẹ́ eyikeyi ti ìkelè—láti gbé ìgbésẹ̀ kan síwájú ní dídá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run àti gbígba àwọn ìlànà pàtàkì wọn ti ìrìbọmi ati ti tẹ́mpìlì, ẹ nṣe ìrànlọ́wọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ.”
Láti jẹ́ kí iṣẹ́ Olùgbàlà jẹ́ iṣẹ́ wa, a nfojúsùn sórí àwọn èrèdí Rẹ̀, npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, a sì nfẹ́ràn ara wa. Nígbàtí a bá ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ lọ́nà Rẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 51:2), àwọn ohun kan njẹ́ fífi sílẹ̀ láti fi òye gbé fúnra ara wa. Olùgbàlà sọ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n péjọ ní Agbègbè, Jackson Missouri pé:
“Nítorí ẹ kíyèsíi, kò tọ́ pé kí èmi ó pàṣẹ nínú ohun gbogbo; nítorí ẹni tí a bá mú ní dandan nínú ohun gbogbo, òun kannáà jẹ́ ọ̀lẹ àti pé kì í ṣe ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀; nitorina òun kò gba ere kankan.
“Lòotọ́ ni mo wí, ènìyàn níláti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rere pẹ̀lú ìtara, àtí kí wọn ó ṣe ohun púpọ làti inú ìfẹ́ ọkàn wọn, kí wọn ó sí mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òdodo ṣẹ;
“Nitori agbara náà wà nínú wọn, nípa èyí tí wọn jẹ́ aṣojú fún ara wọn. Àti pé níwọ̀n bí àwọn ènìyàn bá ṣe rere wọn kì yíò pàdánù èrè wọn” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 58:26–28).
Bí a ṣe ntẹ̀lé Olùgbàlà, tí a ndarapọ̀ mọ́ Ọ nínú iṣẹ́ rẹ̀, tí a sì nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti di ọmọẹ̀hìn rẹ̀ tòótọ́, a nkọ́ni ní ohun tí Òun yíò kọ́ni. Nítorí a kò fún wa ní àṣẹ láti kọ́ ohunkohun míran (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 52:9, 36), a fojúsùn láìyẹsẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ Rẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 68:25). Ní àfikún, ní pàtàkì a nfi ojú sí àwọn wọ̀nnì tí wọ́n jẹ́ òtòṣì, nínú àìní, tí wọ́n sì jẹ́ aláìlágbára (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 52:40). Àwọn àtẹnumọ́ wọ̀nyí jẹ́ mímu ṣe kedere nígbàtí Olùgbàlà ṣe àyọsọ ọ̀rọ̀ láti inú Ìsàíàh nínú sínágọ́gù kan ní Násárétì:
“Ẹ̀mí Olúwa nbẹ lára mi, nítorítí ó fi àmì òróró yàn mi láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòṣì, ó ti rán mi láti ṣe ìwòsàn àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn, láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìríran fún àwọn afọ́jú, láti jọ̀wọ́ òmìnira fún àwọn tí a pa lára,
“Láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Olúwa ” (Luku 4:18–19; bákannáà wo Ìsáíàh 61:1–2).
Ọdún ìtẹ́wọ́gbà ti Olúwa tọ́ka sí àkókò náà nígbàtí gbogbo àwọn ìbùkún Olúwa yíò di kíkójọ sórí àwọn ènìyàn Rẹ̀. A ntẹ̀lé Jésù Krístì nípa pípe àwọn ẹlòmíràn láti gba àwọn ìbùkún ti ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run àti nípa títọ́jú àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ òtòṣì tàbí tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́nà mìràn.
Dídarapọ̀ mọ́ Jésù Krístì nínú iṣẹ́ Rẹ̀ jẹ́ ìgbádùn nlá nítorípé àwọn iṣẹ́ Rẹ̀, àwọn ìdásílẹ̀, àti àwọn èrèdí ni “kò lè ṣeé bàjẹ́, bẹ́ẹ̀ni wọn kò lè di asán” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 3:1). Fún àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìjákulẹ̀, Olúwa gbani nímọ̀ràn pé: “Nítorínáà, ẹ máṣe jẹ́ kí agara dáa yín ní ṣíṣe-rere, nítorí ẹ̀yin nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá kan lélẹ̀. Àti pé nínú àwọn ohun kékeré ni èyíinì tí ó tóbi yíò ti jáde wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 64:33 A njẹ́ kí Olúwa ṣe àníyàn nípa ìkórè, àti pé àwa kàn nṣe ipa tiwa.
Ọkàn àti Àyà Tí Ó Ṣetán
Ṣíṣe ipa tiwa rọrùn ju bí a ṣe lè rò lọ nítorípé a kò nílò láti mú àwọn ẹ̀bùn tàbí agbára àràọ̀tọ̀ wá sínú iṣẹ́ Olúwa. Ìbèèrè Rẹ̀ kàn jẹ́ ìfarajì àti ṣíṣetán. Olúwa sọ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Kirtland, Ohio, pé “Kíyèsíì, Olúwa nbéèrè ọkàn àti àyà tí ó ṣetán” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 64:34). Olúwa lè jẹ́ kí ẹnití ó ṣetán ní agbára, ṣùgbọ́n Òun kò lè tàbí kò ní mú alágbára ṣetán. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, bí a bá farajì tí a sì ṣetán, Ó le lò wá. Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí a ní ẹ̀bùn tó, Òun kì yíò lò wá bíkòṣepé a ní ìfarajì sí iṣẹ́ Rẹ̀ tí a sì ṣetán láti ràn Án lọ́wọ́.
Samuel àti Anna-Maria Koivisto ṣàfihàn ìfarajì àti ìfẹ́. Láìpẹ́ lẹ́hìn ìgbéyàwó wọn, àwọn Koivistos ṣí kúrò ní Jyväskylä, Finland, sí Göteborg, Sweden, láti lépa àwọn àǹfààní iṣẹ́. Lẹ́hìn tí wọ́n dé, wọ́n pe Arákùnrin Koivisto láti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú Ààrẹ Leif G. Mattsson, olùdámọ̀ràn nínú Ààrẹ Èèkàn Göteborg Sweden. Nítorípé Samuel kìí sọ èdè Swedish, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà.
Lẹ́hìn ìbẹ̀wò ráńpẹ́ kan, Ààrẹ Mattsson ní kí Samueli sìn bíi olùdarí míṣọ́n ní Wọ́ọ̀dù Utby. Sámúẹ́lì tọ́ka sí ohun tí ó hàn gbangba: “Ṣùgbọ́n èmi kìí sọ Swedish.”
Ààrẹ Mattsson nà sí orí tábìlì rẹ̀ ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ tààrà pé, “Njẹ́ mo béèrè bóyá o lè sọ èdè Swedish, tàbí ṣe o ṣetán láti sin Olúwa?”
Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Ìwọ bèèrè bí mo bá ṣetán láti sin Olúwa. Àti pé mo ṣetán.”
Sámúẹ́lì tẹ́wọ́gba ìpè náà. Anna-Maria pẹ̀lú tẹ́wọ́gba àwọn ìpè. Àwọn méjèèjì sìn pẹ̀lú ìṣòtítọ́ wọ́n sì kọ́ láti sọ èdè Swedish rírẹwà bí wọ́n ti nsìn.
Ìfarajì àti ṣíṣetán láti sin Olúwa ti jẹ́ ìhùwàsí ìgbésí-ayé Sámúẹ́lì àti Anna-Maria. Wọ́n jẹ́ akọni lásán nínú ìjọ. Wọ́n ti sìn pẹ̀lu òtítọ́ ní gbogbo ìgbà tí a ti bèèrè lọ́wọ́ wọn. Wọ́n ti kọ́ mi pé nígbà tí a bá nsìn, à nlo àwọn ẹ̀bùn tí a ní (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 60:13), Olúwa sì nràn wá lọ́wọ́ láti mú àwọn èrèdí Rẹ̀ ṣẹ.
Nígbàtí a bá ṣetán láti sìn, a ntiraka láti máṣe ráhùn tàbí kùn, nítorípé a kò fẹ́ ba iṣẹ́ ìsìn wa jẹ́ lọ́nà kọnà. Ìráhùn le jẹ́ àmì ìfarajì tó nmì, tàbí pé ìfẹ́ wa sí Olùgbàlà kìí ṣe bí ó ti yẹ kí ó jẹ́. Bí a bá fisílẹ̀ láìṣàyẹ̀wò, kikùn le tẹ̀síwájú bí ìṣọ̀tẹ̀ tààrà sí Olúwa. Ìlọsíwájú yi ni a rí nínú ìgbésí-ayé Ezra Booth, olùyípadà-ọkan ní kùtùkùtù sí ìjọ ní Ohio ẹnití a pè bí ìránṣẹ́ ìhìnrere sí Missouri.
Bí Ezra ṣe kúrò ní ìpínlẹ̀ Ohio ní Oṣù Kẹfà 1831, inú bí Ezra pé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere kan fi kẹ̀kẹ́-ẹrù rìn ìrìnàjò nígbàtí òun ní láti rìn nínú ooru ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, ní wíwàásù bí ó ti nlọ lọ́nà. Ó kùn. Nígbàtí ó dé Missouri, ó ní ìmọ̀lára àìní okun. Missouri kìí ṣe ohun tí ó nírètí. Dípò bẹ́ẹ̀, ó wo àyíká ó sì kíyèsí i pé “ìfojúsọ́nà náà dà bí ìdààmú díẹ̀.”
Ezra wá túbọ̀ nṣàríwí, pẹ̀gàn, àti ọ̀fíntótó púpọ̀ síi. Nígbà tí ó kúrò ní Missouri, dípò wíwàásù bí ó ti nlọ, bí a ti ní kí ó ṣe, ó padà sí Ohio ní kíákíá bí ó ti lè ṣe. Kíkùn rẹ̀ àkọ́kọ́ yọrí sí ṣíṣe iyèméjì àti níkẹhìn sí sísọ ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìrírí ti ẹ̀mí tí ó ti ni tẹ́lẹ̀ nù. Láìpẹ́ Ezra fi Ìjọ sílẹ̀ “ní òpin ó ‘fi ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ ó sì di aláìmọ́.’”
Irú èyí kannáà le ṣẹlẹ̀ sí wa bí a kò bá kíyèsára. Bí a kò bá mú ojú ìwòye ayérayé dúró, kí a sì rán ara wa létí iṣẹ́ ẹnití èyí íṣe gan, a lè ráhùn, ṣiyèméjì, kí a sì sọ ìgbàgbọ́ tí a ní nù níkẹhìn.
Mo gbàdúrà pé kí a lè yàn láti tẹ̀le Jésù Krístì nípa dídarapọ̀ mọ́ Ọ nínú Iṣẹ́ Rẹ̀. Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, a ó fún wa ní “àwọn ìlérí títóbi àti tó ṣe iyebíye gidigidi” (2Peter 1:4). Àwọn ìbùkún wọ̀nyi pẹ̀lú ìdáríjí ẹ̀ṣẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ ati Àwọn Májẹ̀mú 60:7; 61:2, 34; 62:3; 64:3), ìgbàlà (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 6:13; 56:2), àti ìgbéga (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 58:3–11; 59:23). Nítòótọ́, a ṣèlérí ẹ̀bùn títóbi jù lọ tí Ọlọ́run lè fi fúnni fúnwa—ìyè ayéráyé.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹfà 2025. Yoruba. 19610 779