2025
Ìrànlọ́wọ́ láti inú Orísun Pípé kan
Oṣù Kejì 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kejì 2025

Ìrànlọ́wọ́ láti inú Orísun Pípé Kan

Èyíówù àwọn ìlàkàkà tí ó lè wà ní ìlòdì sí yín, Jésù Krístì yíò ràn yín lọ́wọ́ bí ẹ ti nyípadà sí I.

Jésù Krístì

Àwòṣe náà, láti ọwọ́ Jeanette Bourup

Ní àkokò kan tàbí òmíràn gbogbo wa nílò ìrànlọ́wọ́ kékeré kan. Nígbàmíràn ọ̀pọ̀ ìrànlọ́wọ́. Òtítọ́ náà ni, pé ígbésí ayé nlọ púpọ̀ dáadáá si nígbàtí ẹ kò bá gbìyànjú láti dá lọ nínú rẹ̀.

Jésù Krístì ni orísun pípé, ìrètí, àti okun ti ìrànlọ́wọ́ yín, Bákannáà Òun lè ṣèrànwọ́ láti yí yín padà fún dídára si—àní bóyá ní àwọn ọ̀nà tí ẹ kò rò pé ó ṣeéṣe.

Ìyípadà Ọkàn Kan

Njẹ́ ẹ̀yin ti gbàdúrà rí pé kí Ọlọ́run rọ ọkàn àwọn ọ̀tá yín? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ wà nínú ọ̀gbà rere (wo 3Néfì 12:44; Mórónì 7:48). Àní bí ẹ̀yin kò bá ní àwọn ọ̀tá ọgbọ́n kannáà nínú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì yí (ẹ mọ̀ pé, àwọn ọ̀tá ní ìhámọ́ra pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ogun tí wọ́n sì ṣetán láti kọlù), bóyá ẹ ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rọ̀ ẹnìkàn lọ́kàn tí kò hùwà sí yín dáadáa.

Sùgbọ́n ṣé ẹ ti ronú rí láti gbàdúrà kí ẹ sì bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti rọ ọkàn yín? Bóyá ẹ nní ìgbà líle kan ní dídáriji ẹnìkan. Tàbí ẹ̀ máa npàdánù ìbínú yín, àní bí ó tilẹ̀jẹ́pé ẹ kò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Tàbí ẹ fẹ́ láti ní ìmọ̀lára inúrere síi sí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yín pẹ̀lú òótọ́ pé wọ́n nmúnú bíi yín nígbàmíràn.

“[Jésù Krístì] yíò yí ọkàn yín àti ìgbésí ayé yín padà. Ní díẹ̀ díẹ̀, ẹ ó dàgbà ẹ ó sì dà bíi Tirẹ̀ si. Ìsopọ̀ májẹ̀mú yín pẹ̀lú Rẹ̀ yíò mú àyè títóbijù sí agbára Rẹ̀ wá fún un yín” (Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́nisọ́nà Kan fún Ṣíṣe Àṣàyàn [2022], 8, àfikún àtẹnumọ́).

Èyí kìí ha ṣe ìlérí nlá kan bí? Ohun èyíówù kí ẹ lè máa tiraka pẹ̀lú, àní ọkàn ti ara yín, Jésù Krístì lè ṣèrànwọ́. Báwo ni ẹ ṣe lè yípadà sí I ní òní?

ọmọdékùnrin