“Èmi Ó Wò Wọ́n Sàn,” Làìhónà, Oṣù Kejì, 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kejì 2025
“Èmi Ó Wò Wọ́n Sàn”
Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìwòsàn Olùgbàlà jẹ́ ìṣíwájú àtọ̀runwá àti ìlérí kan nípa ìwòsàn pípẹ́ ti ara àti ti ẹ̀dùn ọkàn tí yíò wá sọ́dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nínú Àjínde.
Èmi ṣì rántí àwọn fífò pípẹ́ tí mo ṣe gidigidi nígbà ìgbésí ayé akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ mi bí ọ̀gágun iṣẹ́-ọkọ̀-òfúrufú kan.
Nínú ọ̀kan lára wọn, mo gbéra ní Germany ní aago mọ́kànlá òwúrọ̀ mo sì sọ̀kalẹ̀ ní California ní aago kan ọ̀sán ní ọjọ́ kannáà. Ní fífiwé àwọn àkokò ìbílẹ̀ lílọ àti dídé, ó lè farahàn bí ẹnipé fífò kan sọdá Òkun Atlantic àti Àríwá agbègbè ti Amẹ́ríkà gba wàkàtí méjì péré. Ọkọ̀ Boeing 747 náà yára, ṣùgbọ́n kìí ṣe pé ó kúkú yára bẹ́ẹ̀! Ní òdodo, ó gbà wá bíi wákàtí mọ́kànlá, ní dídá lórí ìjì, láti rin ìrìnàjò àwọn ẹgbẹ̀rún marun ó lé igba mẹ́ta máìlì (ẹgbẹ̀rún mẹsan kilómítà).
Nítorí a nfò sí ìwọ̀-òòrùn, òòrùn náà kò wọ̀ rárá nígbà fífò wa. A gbádùn ojú-ọjọ́ gbígbòòrò ní gbogbo ọ̀nà láti Germany sí California.
Pípadà sí Germany, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ ìtàn kan tó yàtọ̀ pátápátá. Àní nígbàtí a gbéra ní kùtùkùtù ọ̀sán náà, bí a ti fò ní ìlà-òòrùn, wíwọ̀-òòrùn náà wá kíákíá síi ju bí ìbá ti rí lọ, kí a sì tó mọ̀ ọ́, ilẹ̀ ti ṣú lórí wa.
Ní ìgbà àwọn fífò pípẹ́ wọ̀nyí, ọkàn mi nfi ígbà gbogbo kún fún ìyanu bí mo ti nronú jinlẹ̀ ní ti ẹwà ilẹ̀-ayé yí àti ètò ìṣẹ̀dá ti Ọlọ́run. Àní nígbà fífò ní òru, nínú òkùnkùn biribiri, mo mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé òòrùn yíò ràn lẹ́ẹ̀kansi, pé ìmọ́lẹ̀ dídán yíò padà yíò sì mú ìyárí àti ìgbésí ayé wá sí ọjọ́ ọ̀tun ṣíwájú ópin ti ìrìnàjò wa. Àwọn ipò ti fífò mi lè ti jẹ́ kí ó dàbí ẹnipé òòrùn nwọ̀ díẹ̀díẹ̀ síi tàbí kíákíá síi, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé òòrùn ti wà láìyẹsẹ̀, ní dídúró ṣinṣin, àti ní ṣíṣeé gbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọ̀run.
Mo ní ìmọ̀lára irú ọ̀nà kannáà nípa Ọlọ́run. Nítorí mo ní ìdánilójú jíjinlẹ̀ gan nípa ọgbọ́n Ọlọ́run àti èrèdí fún gbogbo ìṣẹ̀dá Rẹ̀, mo lè ní ìmọ̀lára ìrètí aláyọ̀ àti àláfíà pípẹ́ nígbàtí mo bá ronú nípa wíwà nínú ayé-ikú wa. A jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Ó fẹ́ràn wa. Ó mọ àwọn ipò wa. Ó ṣetán láti ṣe ìrànlọ́wọ́. Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí kò yípadà, àní nígbàtí àwọn ohun ní àyíká wa dàbí àìlèdúró àti àìròtẹ́lẹ̀.
Gbogbo wa nní ìrírí àwọn àkokó ìṣókùnkùn, ìbànújẹ́, àti àìní-ìdánilójú tí ó nba àláfíà wa lẹ́rù. Mo ti ní ìmoore tó fún ìgbẹ́kẹ̀lé àti orísun òtítọ́ àti ìmọ́lẹ̀ náà (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:6–11). Jésù Krístì ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé. Nítorí Rẹ̀ àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, a ní ìrètí fún ọjọ́-ọ̀la, àyè sí ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá láti mú àwọn ọjọ́ òkùnkùn di dídán nípa ìrìnàjò wa, àti ìlérí ìṣẹ́gun ìgbẹ̀hìn lórí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
“Ó Fẹ́ràn Aráyé”
Jésù Krístì ni ẹni pípé kanṣoṣo tí ó rìn ní ilẹ̀ ayé rí. Nítorí ìgbésí ayé pípé Rẹ̀, Òun kò jẹ gbèsè kankan sí ìdáláre. Nínú ìfẹ́ fún wa, Ó fi ìgbésí ayé Rẹ̀ fún wa ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run lápapọ̀ láti ṣí ilẹ̀kùn sí àìkú àti ìyè ayérayé.
Pẹ̀lú ohun tí Sátánì fẹ́ kí a gbàgbọ́, kò sí ẹnìkankan lára wa tí ó kọjá okun Olùgbàlà láti gbà wá là. Kò sí ẹnìkankan lára wa tí ó jẹ́ aláìyege kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́ ìdáríjì. Kò sí ẹnìkankan tí ó kọjá jíjẹ́ “yíyíká kiri títí ayérayé nínú apá ìfẹ́ rẹ̀” (2Néfì 1:15).
Èyí tí ó ga ju gbogbo àwọn ẹ̀bùn lọ yí nwá láti inú agbára lílèṣe àti ríràpadà Ètùtù Jésù Krístì. Nítorí ìjìyà Olùgbàlà ní Gẹ́thsémánè àti ní Gọ́lgóthà, Ó mọ bí Òun ó ti gbà wá là kúrò nínú kí ó sì rànwálọ́wọ́ la eyikeyi àti gbogbo àwọn àìlera wa já (wo Álmà 7:12).
“Òun kò ṣe ohunkóhun bíkòṣe fún èrè aráyé; nítorí ó fẹ́ aráyé, àní tí ó fi fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí òun lè fa gbogbo ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀”(2 Néfì 26:24).
Jésù Krístì ni okun wa!
Ó nawọ́ jáde.
Ó nmúpadàbọ̀sípò.
Ó ngbàlà.
“Nígbàtí Olùgbàlà [ṣe ìrúbọ ètùtù Rẹ̀] fún gbogbo aráyé, Ó ṣí ọ̀nà kan tí àwọn tí ó bá tẹ̀lé E fi lè ní àyè sí ìwòsàn, ìfúnlókun, àti agbára ìràpadà Rẹ̀,” ni Ààrẹ Russell M. Nelson sọ.
Agbára náà, bíiti òòrùn, wà níbẹ̀ nígbà gbogbo. Kì í yẹsẹ̀ láé. Àṣàyàn náà láti tẹ̀lé nínú àwọn ìṣísẹ̀ Olùgbàlà ni ó dàbí rírìn jáde nínú àwọn òjìji àti sínú ìmọ́lẹ̀-òòrùn, níbi tí a ti lè gba àwọn ìbùkún ìmọ́lẹ̀, ìyárí, àti ìfẹ́ Ọlọ́run. Mo mọ̀ pé ní ọjọ́ kan, a ó wo ẹ̀hìn a ó sì jẹ́ kíkún fún ìmoore pé a ṣe ìpinnú pàtàkì ti ayérayé láti gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì àti ìfẹ́ àtọ̀runwá Rẹ̀ láti gbé wa ga àti láti fún wa lókun.
“Padà sí ọ̀dọ̀ Mi”
Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ nípa àwọn ẹ̀nìyàn kan tí wọ́n lo ọjọ́ mẹ́ta nínú òkùnkùn jíjinlẹ̀ jùlọ tí ó tẹ̀lé Ìkan-mọ́-àgbélèbú Olùgbàlà. Òkùnkùn ti ara ní àyíká wọn lè jẹ́ àpẹrẹ òkùnkùn ti ẹ̀mí tí gbogbo wa nní ìrírí rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀. Nígbànáà àwọn ènìyàn gbọ́ ohùn Krístì tí ó npè wọ́n jáde láti inú òkùnkún náà àti sí inú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀:
“Ẹ̀yin kì yíò ha padà sí ọ̀dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, kí èmi ó lè wò yin sàn bí?” (3 Néfì 9:13).
“Ẹ rú ẹbọ-ọrẹ ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ sí mi” (3 Néfì 9:20).
“Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ sì padà wá sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú èrèdí kíkún ọkàn” (3 Néfì 10:6).
Olùgbàlà nawọ́ àwọn ìfipè bákannáà sí wa ní òní nígbàtí a bá rí ara wa ní sísọnù sínú òkùnkùn. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kọ̀ọ̀kan títà-òòrùn ṣe nfi àmì sí bíbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ titun kan, àkokò kọ̀ọ̀kan tí a bá ronúpìwàdà, à ngba ìbẹ̀rẹ̀ titun kan, bíbẹ̀rẹ̀ dídán titun kan.
Ìyẹn kò túmọ̀sí pé ó rọrùn. Ìronúpìwàdà túmọ̀sí ìyípadà, àti pé ìyípadà kìí ṣẹlẹ̀ kíákíá. Nígbàtí ó jẹ́, aláyọ̀, ìrònúpìwàdà ní “ìkorò ti-ọ̀run” nínú (2 Kọ́ríntì 7:10). Ó bèèrè fún pé kí a gbà kí a sì jẹ́wọ́ àwọn àṣìṣe wa, bíbèèrè fún ìdáríjì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti láti ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí a lè ti palára. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó bèèrè pé kí a wá “Ẹ̀mí Olúwa Alèwílèṣe,” pé kí a lè ní ìrírí “ìyípadà nlá kan nínú … ọkàn wa, tí a kò ní ní ẹ̀mí àti ṣe búburú mọ́, ṣùgbọ́n láti ṣe rere títí lọ” (Mosiah 5:2).
Irú ìyípadà náà jẹ́ ìrìnàjò pípẹ́ kan, ṣùgbọ́n láìpẹ́ bí ẹ bá ti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́, “ọjọ́ ìgbàlà yín” bẹ̀rẹ̀, àti pé “lójúkannáà ni a ó mú ètò ìràpadà wá fún yín” (Alma 34:31).
Nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà tòótọ́ wa, Ọlọ́run ṣe ìlérí láti daríjì àti láti máṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Nígbàtí a bá ní ìṣòro gbígbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ẹ jẹ́ kí a tiraka láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí Olúwa láti dáríjì kí a sì kọ́ láti dáríji àwọn ẹlòmíràn àti ara wa.
“Àwọn ẹ̀mí wa nbàjẹ́ nígbàtí a bá ṣe àwọn àṣìṣe tí a sì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀,” ni Ààrẹ Boyd K. Packer kọ́ni (1924–2015). “Ṣùgbọ́n ní àìdàbí ọ̀ràn ti ara ikú wa, nígbàtí ètò ìrònúpìwàdà bá parí, kò sí àpá tí ó kù nítorí Ètùtù Jésù Krístì.”
Wíwo Ọkùnrin Afọ́jú Sàn, láti ọwọ́ Carl Heinrich Bloch
“Ẹ Mú Wọn Wá Sìhín”
Olùgbàlà ni Oníwòsàn Nlá. Ọ̀kan lára àwọn ìjúwe dídára jùlọ ti agbára ìwòsàn Rẹ̀ ni a rí nínú Ìwe ti Mọ́mọ́nì, nínú àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ara-ẹni Rẹ̀ ní Amẹ́ríkà àtijọ́:
“Njẹ́ ẹ̀yin ní aláìsàn kankan ní àárín yín bí?” Ó bèèrè. Ẹ mú wọn wá sìhín. Njẹ́ ẹ̀yin ní àwọn amúkun, tàbí afọ́jú, tàbí arọ, tàbí akéwọ́, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí àwọn gbígbẹ, tàbí adití, tàbí tí a pọ́n lójú ní onírurú ọ̀nà? Ẹ mú wọn wá sí ìhín èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín; inú mi kún fun àánú. …
“Ó sì ṣe nígbàtí ó ti sọrọ báyĩ, gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, jùmọ̀ jáde lọ pẹ̀lú àwọn aláìsàn wọn àti àwọn tí a pọ́n lójú, àti àwọn amúkun wọn, àti pẹ̀lú àwọn afọ́jú wọn àti pẹ̀lú àwọn odi wọn, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí a pọn lójú ní onírurú ọ̀nà; ó sì wò olúkúlùkù wọ́n sàn bí wọn ṣe nmú wọn wá sí ọdọ rẹ̀” (3 Néfì 17:7, 9).
Gbogbo ìgbà tí Olùgbàlà bá wo ẹnikẹ́ni “tí a pọ́nlójú ní ọ̀nàkọnà,” ṣaájú àti lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀, ó jẹ́ ẹ̀rí kan sí agbára ìgbẹ̀hìn Rẹ̀ láti wo àwọn ọkàn wa sàn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwòsàn ìyanu jẹ́ ṣùgbọ́n ìṣaájú àti ìlérí kan nípa ìwòsàn pípẹ́ ti ara àti ti ẹ̀dùn ọkàn tí yíò wá sọ́dọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa nínú Àjínde, èyí tí ó “jẹ́ ìṣé ìwòsàn àṣepé Olúwa.”
Ó jẹ́ òtítọ́ pé àwọn àdúrà wa fún ìwòsàn nínú ìgbésí ayé yí ni a kìí gba ìdáhùn sí ní ọ̀nà tí a retí, ṣùgbọ́n tí a kò pa wọ́n tì láé. Àkokò fún ìwòsàn yíò wá, gẹ́gẹ́ bí òkùnkùn òrù tí nfúnni ní àyè nígbàgbogbo—ní àkokò títọ́—sí títàn-òòrùn ológo.
Bí Ààrẹ Nelson ti jẹri: “Ìgbàgbọ́ wa ni a kò ṣaláìmọyì rẹ̀ láé. Mo mọ̀ pé ìwòye Baba Ọ̀run ọlọ́gbọ́n gbogbo ni ó gbòòrò púpọ̀ ju tiwa. Nígbàtí a bá mọ̀ nípa àwọn ìdàmú àti ìrora ayé ikú wa, Òun nmọ̀ nípa ìlọsíwájú àti agbára ayé àìkú wa. Bí a bá gbàdúrà láti mọ ìfẹ́ Rẹ̀ tí a sì juwọ́ ara wa sílẹ̀ sí i pẹ̀lú sùúrù àti ìgboyà, ìwòsàn ọ̀run lè wáyé ní ọ̀nà àti àkokò ti ara Rẹ̀.”
Láìpẹ́ ìyàwó mi, Harriet, àti èmi fi ìrètí pàtàkì kan àti ẹ̀bẹ̀ sínú àwọn àdúrà wa ní ìtìlẹhìn àwọn tí a fẹ́ràn. A gbàdúrà pé kí àwọn ikọ̀ olùtọ́jú wọn ó jẹ́ fífún ní okun pàtàkì láti wo àwọn àìsàn wọn sàn. A ní ìtẹ̀mọ́ra láti fikun pé àní bí ìwòsàn kíákíá tàbí ìdápadà kan bá bá tilẹ̀ ṣe àìṣẹlẹ̀, agbára ìwòsàn Olùgbàlà lè mú ìtùnú àti àláfíà wá fún wọn. Àbájáde ìwòsàn nípa agbára ìràpadà Olùgbàlà lè ní àní ipá títóbijù lórí ìlera ẹ̀dùn ọkàn, ti ẹ̀mí, àní àti ti ara wa ju eyikeyi ìwòsàn ti ayé tí a lè gbà lọ. Jésù Krístì ni Oníwòsàn nínú ayé yí àti ní ayérayé.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, mo jẹ́ ẹ̀rí pé àánú Olùgbàlà ni ó tó láti wo àwọn àpá yín sàn, wẹ ẹ̀ṣẹ̀ yín nù, fi okun fún yín fún àwọn àdánwò tó nbọ̀, kí ó sì bùkún yín pẹ̀lú ìrètí, ọgbọ́n, àti àláfíà Rẹ̀. Agbára Rẹ̀ wà níbẹ̀ nígbàgbogbo—léraléra àti ṣíṣeé ìgbẹ́kẹ̀lé—àní nígbàtí àwa, fún àkokò kan, bá ní ìmọ̀lára jíjìnà kúrò nínú ìfẹ́, ìmọ́lẹ̀, àti ìyárí Rẹ̀.
Mo gbàdúrà pé kí a máṣe pàdánù ọgbọ́n ìyanu wa àti ìmoore jíjinlẹ̀ fún ohun gbogbo tí Jésù Krístì ti ṣe fún wa. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé a ní ìfẹ́ yín ní pípé, kí ẹ sì rántí ohun tí a ti ṣe ìlérí fún yín ní ayérayé.
“Njẹ́ kí Ọlọ́run gbà fún un yín pé kí àwọn ẹrù yín lè di fífúyẹ́, nípasẹ̀ ayọ̀ ti Ọmọ rẹ̀,” Jésù Krístì (Álmà 33:23).
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdé: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdé ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kejì 2025. Yoruba. 19609 779