“Ìṣẹ́gun ti Àyànfẹ́ Olùgbàlà Wa,” Lìàhónà, Oṣù Kẹ́rin. 2026.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Lìàhónà, Oṣù Kẹ́rin 2026
Ìṣẹ́gun ti Àyànfẹ́ Olùgbàlà Wa
Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ láti ṣe àpèjúwe títóbi ẹ̀bùn iyebíye ti Jésù Krístì. A kì yíò bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ẹlòmíràn láé. Ó jìyà “lẹ́ẹ̀kansi fún gbogbo ènìyàn.”
Bí àwọn ọdún ṣe nkọjá lọ, mo ti di onírẹ̀lẹ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ bí mo ti se ronú nípa, ṣe àṣàrò, àti rí ìtùnú nlá nínú ẹ̀bùn àìní-ìwọ̀n ti Olùgbàlà wa, Ètùtù Jésù Krístì. Iyè-inú ẹlẹ́ran ara lè bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ láti ní òye bí ìpín àyànmọ́ ènìyàn ṣe nyípadà nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Gẹ́tsémánè, lórí àgbélèbú, àti ní ibojì.
Gbogbo Wa Nṣe Àbápàdé Ìrora-ọkàn àti Ìjìyà
Nínú ìpè mi bí Àpóstélì, mo ti rin ìrinàjò gidigidi tí mo sì ní ànfàní pípàdé àwọn ọ̀dọ́mọdé, ọ̀dọ́, àti àgbàlagbà káàkiri púpọ̀ àgbáyé. Àwọn àkokò ti ayọ̀ àkokò nlá wà nínú ayé, ṣùgbọ́n ohun kan tí mo ti rí pẹ̀lú ojú ara mi tí mo sì ní ìmọ̀lára nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi ni pé ní àfikún sí ìdùnnú àti ayọ̀, ìgbé ayé ndi àwọn àkokò ìrora-ọkàn àti ìjìyà mú.
Èmi kò ní gbàgbé jíjóòkó pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́mọdé mẹ́rin tí a fòpin sí ìgbé ayé àwọn òbí wọn láburú láti ọwọ́ afínràn kan nínú ilé ara wọn nígbàtí àwọn ọmọdé náà sùn, tàbí pípàdé pẹ̀lú obìnrin kan tí a lò nílòkulò bí ọmọdébìnrin láti ọwọ́ ìbátan tó gbẹ́kẹ̀lé tàbí jíjóòkó lẹ́ẹ̀gbẹ́ ibùsùn ọmọdébìnrin kan tí ó ní ìpalára ọpọlọ lẹ́hìn ṣíṣubú láti orí kẹkẹ tí yíò kú láìpẹ́, tàbí fífetísílẹ̀ sí sísọkún obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ ti dalẹ̀ rẹ̀ àti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì ní ọ̀nà ìjádelọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Mo ti ní ìmọ̀lára ìrora ti lọ́kọláya tí ọmọ wọn àgbà kò gbàgbọ́ mọ́ nínú àwọn òtítọ́ ìhìnrere ó sì wá ọ̀nà láti rẹ̀wẹ̀sì nígbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn nínú ẹbí. Mo ti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú àwọn òbí àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n dàmú nípa ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó kún fún ìlérí tí ó gba ẹ̀mí ara rẹ̀. Mo ti ní ìmọ̀lára ìkorò tọ̀run nípa àwọn wọnnì tí wọ́n ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n sì fẹ́ láti ronúpìwàdà àti ìbàjẹ́ ti àwọn wọnnì tí a palára nípa ẹ̀ṣẹ̀.
Mo ti rí ìrora-ọkàn ti àìsàn ọpọlọ méjèèjì fún ọ̀kan tí ó njìyà àti fún àwọn wọnnì tí wọ́n njìyà jẹ́jẹ́ bí wọ́n ṣe nwò pẹ̀lú okun díẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Mo ti rí òfò araẹni púpọ̀ nípa àjálù, àgbàrá, ìjì, iná, àti ìsẹ́lẹ̀ àdánidá. Mo ti jẹ́ ẹlẹ́rìí ìrúkèrúdò ní àwọn orílẹ̀-èdè látinú àwọn ìjì, ogun, àti ìparun òṣèlú, àti ìrora tí ó nwá nígbàtí a bá fi àìròtẹ́lẹ̀ sórí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan tí wọ́n sì nwá láti ṣe ohun tí ó tọ́.
Àwọn Ọwọ́ Ìwòsàn, láti ọwọ́ Kolby Larsen, tí a kò lè ṣe ẹ̀dà
Olùgbàlà Ntù Wá Nínú
Ní sísọ̀rọ̀ nípa Ètùtù Jésù Krístì, Ààrẹ James E. Faust (1920–2007), Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní, wípé: “Olùpalára náà níláti ṣe ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣiṣẹ́ nínú àwọn àdánwò wọn, àti pé Olùgbàlà yíò ‘tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú gẹ́gẹ́bí àwọn àìlera wọn’ [Álmà 7:12]. Òun yíò ràn wá lọ́wọ́ láti gbé àwọn ẹrù wa. Àwọn egbò kan npanilára gan ó sì jinlẹ̀ tí wọn kò lè ṣeé wòsàn láìsí ìrànlọ́wọ́ látinú agbára gíga àti ìrètí fún ìdáláre pípé àti ìsànpadà ní ayé tó nbọ̀. … Ó ní ìmọ̀ ìrora wa òun yío sì rìn pẹ̀lú wa pàápà nínú àwọn wákàtí ṣíṣókùnkùn wa.”
Mo ní ìmm̀lára púpọ̀ sísún mọ́ ìfẹ́ Olùgbàlà àti àwọn ìbùkún àìlópin tí a ṣe ìlérí fún wa nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì. Òun kò dá ààbò bò wá kúrò nínú àwọn ìrírí líle ìgbé ayé tí ó nmú ìrora àìní-ìwọ̀n, ṣùgbọ́n Ó dá ààbò bò wá kúrò nínú ìjìyà ayérayé àti yíyàkúrò ní ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run tí ó sì fi àyè gbà wá, nípasẹ̀ gbogbo ìjìyà Rẹ̀, láti ni àyè ti ayọ̀ pípé àti ayọ̀ ayérayé níwájú Ọlọ́run.
Ààrẹ Dallin H. Oaks rán wa létí: “Ní gígùn, ìrànlọ́wọ́ alágbára jùlọ ayé ikú ti Ọlọ́run ni ìpèsè Rẹ̀ nípa Olùgbàlà, Jésù Krístì, ẹnití ó jìyà láti san oye tí ó sì pèsè ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ronúpìwàdà. Ètùtù aláàánú àti ológo náà ṣe àlàyé ìdí tí ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì fi jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìkínní ti ìhìnrere. Ètùtù Rẹ̀ ‘Mú àjínde òkú wá sí ìmúṣẹ’ (Álmà 42:23), ó si [ti] ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé’ (Álmà 34:8), ní pípa gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ronúpìwàdà rẹ́ àti fífún Olùgbàlà wa ní agbára láti tù wá nínú àwọn àìlera ayé ikú wa.”
Àlàyè kíníkíní látinú Àdúrà ní Gẹ́tsémánì, láti ọwọ́ Del Parson, a lè ṣe ẹ̀dà fún lílò Ìjọ nìkan
Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Àìlópin
Nígbàtí mo ronú nípa ìjìyà tí mo ti rí níti ara mi, èyítí ó fi àìlópin kéré ní àfiwé sí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ti tàbí tí wọn yíò rìn ní ilẹ̀ ayé rí, èmi kò lè, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ eyikeyi tí mo mọ̀, ṣe àpèjúwe àwxn ìmọ̀lára ọkàn mi fún ohun tí ó ti gbọ́dọ̀ ti ṣẹlẹ̀ nínú ọkàn àti iyè-inú àti ara àti ẹ̀mí Olùgbàlà ní àwọn àkokò mímọ́ Rẹ̀ nípa gbogbo-àpapọ̀ ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrora gbogbo ènìyàn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì ti gbogbo àìlópin bẹ̀rẹ̀ bí Jésù ṣe lọ “si´ ibì kan tí a pè ni] Gẹ́tsémánì” (Máttéù 26:36) ní Òkè Ólífì ní ìta odi Jérúsálẹ́mù. Ó wí fún àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ pé, “Ọkàn mi bàjẹ́ gidigidi, títí dé ikú” (Máttéù 26:38).
Ó ngbàdúrà, wípé, “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, jẹ́kí ago yí kí ó kọjá kúro lórí mi: ṣùgbọ́n kìí ṣe bí èmi ti nfẹ́, ṣùgbọ́n bí ìwọ ti fẹ́” (Máttéù 26:39). Ó padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀, ó ri tí wọ́n nsùn, Ó lọ lẹ́ẹ̀kansi, Ó sì gbàdúrà ní ẹ̀ẹ̀kejì. “Baba mi, bí ago yí kò bá lè ré mi kọjá, bíkòṣepé mo mu ú, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe. … [Ó] sì gbàdúrà ní ẹ̀ẹ̀kẹ́ta, ó nsọ ọ̀rọ̀ kannáà” (Máttéù 26:42, 44).
Jésù mu ago kíkorò Ó sì jìyà kọjá òye ayé ikú wa méjèèjì ní ọgbà àti lórí àgbélèbú. Láì dẹ́ṣẹ̀, Ó gbé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa lé orí Ararẹ̀, pé bí a ti nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí a sì nronúpìwàdà, a ó gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀rù kúrò lórí wa (wo 2 Kọ́ríntì 5:21).
Ìjìyà, ikú, àti ìrúbọ ètùtù Jésù ni a ti nretí tipẹ́tipẹ́. Sísọ̀rọ̀ ọgọ́rún méje ọdún ṣáajú ìbí Jésù, Ísáíàh sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “Olúwa ti mú àìṣedéédé wa gbogbo pàdé lára rẹ̀” (Ísáíàh 53:6). Jésù sọ̀rọ̀ nípa fífi ayé Rẹ̀ fúnni bí “ìràpadà kan” (Máttéù 20:28; bákannáà wo 1 Tímótìéù 2:6) “fún ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀” (Máttéù 26:28) fún gbogbo ẹnití yíò gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tí yíò sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Pétérù ṣe àpèjúwe bí Ó ṣe “jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [wa] ” (1 Pétérù 3:18), pé nípasẹ̀ ìnà Rẹ̀ ni a mú wa láradá (wo 1 Pétérù 2:24). Ó ṣe ohun tí ẹlòmíràn kò lè ṣe láti fi ààyè gbà wá láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa. A “pa á lára nítorí àìṣedéédé wa” (Ísáíàh 53:5).
Títẹ̀lé ìjìyà ní Gẹ́tsémánì, ìrora Rẹ̀ tẹ̀síwájú—dídalẹ̀ nípasẹ̀ ẹnìkan tí ó rìn pẹ̀lú Rẹ̀, ní ṣíṣẹ̀sín níwájú àwọn aláàkóso àìṣòótọ́, ìrora ti ara rẹ̀ tí ó jẹ́ nínà, adé ẹ̀gún tí a tẹ̀ mọ lórí nípasẹ̀ àwọn ọmọ-ogun ìkà àti aláìní àánú (wo Jòhánnù 18:2–3, 12–14; Márkù 15:15–20), àti ìgì tí a fi gún ẹran ara yíya ti ẹ̀hìn Rẹ̀ bí Ó ti nrìn lọ síwájú Gọ́lgótà (wo Jòhánnù 19:16–17).
Ní orí àgbélèbú, ìrora kíkọjá-àlà tí ó ní ìmọ̀lára ní Gẹ́tsémánì padà pẹ̀lú ìjáfáfá tí kò sí ẹnití ó lè faradà. Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, dánìkan jẹ́ iṣẹ́ àtọ̀runwá nípasẹ̀ Baba Rẹ̀ láti gbé ayé sílẹ̀. Àwọn ọmọ-ogun àti alákóso kò le gbà á lọ́wọ́ Rẹ̀ (wo Jòhánnù 10:18). Nínú ọ̀wọ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀, Jésù tẹ orí Rẹ̀ ba ó sì wípé, “Ó ti parí” (Jòhánnù 19:30).
Àkokò ìkẹhìn ti ayé ikú Rẹ̀ ti parí. Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ láti ṣe àpèjúwe títóbi ẹ̀bùn iyebíye Rẹ̀. A kì yíò bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ ẹlòmíràn láé. Jésù Krístì jìyà “lẹ́ẹ̀kan fún gbogbo ènǹyàn” (Hébérù 10:10).
Ó ti jínde!
Pẹ̀lú ṣíṣe àṣeyọrí iṣẹ́ ìránṣẹ́ àtọ̀runwá Rẹ̀, Òun ni yíò jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn gbogbo ènìyàn láti dìde kúrò nínú isà-òkú sínú àìkú (wo 1 Kọ́ríntì 15:21–23).
Sí àwọn obìnrin níbi ibojì, àwọn ángẹ́lì wípé:
“Èéṣe tí ẹ̀yin fi nwá alààyè ní àárín òkú?
“Kò si ní ìhín yí, ṣùgbọ́n ó ti jínde” (Lúkù 24:5–6).i
Sí àwọn Àpóstélì Rẹ̀, Ó wípé, “Kíyèsí ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni” (Lúkù 24:39). Lẹ́hìnnáà, “a rí i [nípasẹ̀ púpọ̀ ju] ọgọ́ọrún márún … lẹ̀ẹ̀kan” (1 Kọ́ríntì 15:6). Àwọn ẹlẹ́rìí-ojúkojú rí Olùgbàlà olùjínde. Òun kò kú. Ó wà láàyè
Jésù Krístì já àwọn ẹ̀wọ̀n àti ìdè ti ìgbèkùn àìlópin ikú fún gbogbo ẹnití ó ti gbé rí tàbí yíò gbé ní orí ilẹ̀ ayé (wo 1 Kọ́ríntì 15:22). Ó ṣẹ́gun gbogbo-àpapọ̀ ọ̀tá wa; ọ̀tá ikú ni a lé lọ títíláé.
Ààrẹ Russell M. Nelson (1924–2025) wípé: “Jésù Krístì gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, àwọn ìrora yín, àwọn ìrora-ọkàn yín, àti àwọn àìlera yín. Ẹ kò ní láti dánìkan gbé wọn! Òun yíò dáríjì yín bí ẹ ṣe nronúpìwàdà. Òun yíò bùkún yín pẹ̀lú ohun tí ẹ nílò. Òun yíò wo ẹ̀mí ọgbẹ́ yín sàn. Bí ẹ ṣe nfi àjàgà yín pẹ̀lú Rẹ̀, àwọn ẹrù yín yíò di fífúyẹ́. Bí ẹ yíò bá dá kí ẹ sì pa àwọn májẹ̀mú láti tẹ̀lé Jésù Krístì mọ́, ẹ̀yin yíò ri pé àwọn àkokò ìrora ti ayé yín jẹ́ ránpẹ́. Àwọn ìpọ́njú yín ni a ó ‘ gbé mì nínú ayọ̀ Krístì’ [Álmà 31:38]”
Gẹ́gẹ́bí ọ̀kan lára àwọn Àpóstélì Rẹ̀ tí a yàn, mo ní ìrírí àwọn àkokò ẹ̀mí ti araẹni tí ó ti mú ẹ̀rí pàtó àti dídájú kan pé Ó wà láàyè. Ní àkokò Ọdún Àjínde yí, njẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ wọ̀nyí gbé ní inú àti ọkàn wa: “Ẹ má jẹ́ kí ngbàgbé, Áà Olùgbàlà, Ẹ ti ṣẹ̀jẹ̀ ẹ sì kú fún mi,” bí a ṣe nyọ̀ nínú kíkọrin:
© 2026 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọrọ Oṣoòṣù Lìàhónà, Oṣù kẹrin 2026. Yoruba. 20038 779