“Àwọn Májẹ̀mú, Agbára, àti Ìlérí,” Làìhónà, Oṣù Kẹwa. 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹwa 2025
Àwọn Májẹ̀mú, Agbára, àti Ìlérí
Tẹ́mpìlì ni àárín-gbungbun ìlérí agbára ati ààbò sí àwọn olóòọ́tọ́ ṣíwájú Ìpadàbọ̀ Ẹẹ̀kejì ti Olúwa Jésù Krístì.
Ìjúwe Joseph Smith láti ọwọ́ Dan Burr
Ní Oṣù Karun 1833 baba-àgbà baba mi kẹrin Asahel Perry àti àwọn ọ̀rẹ́ kan rin ìrìnàjò láti apá àríwá New York lọ sí Kirtland, Ohio. Wọn kìí ṣe ọmọ ìjọ ti Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò titun, ṣùgbọ́n wọ́n nfẹ́ láti pàdé Wòlíì Joseph Smith. Wọ́n dé ní àkokò gan láti lọ sí ìgbìmọ̀ àkọ́kọ́ tí a ṣe láti sọ̀rọ̀ kíkọ́ Tẹ́mpìlì Kirtland.
Lẹ́hìn bíbẹ̀rẹ̀ ìgbìmọ̀ náà, Wòlíì ṣe ìgbékalẹ̀ iṣẹ́ ti kíkọ́ tẹ́mpìlì náà. Lẹ́hìnnáà ó ké pè àwọn tí ó wà níkàlẹ̀ láti fi ìmọ̀lára wọn hàn ní ìbámu sí irú àdáwọ́lé títóbi bẹ́ẹ̀. Púpọ̀jùlọ fèsì pé Ìjọ jẹ́ òtòṣì púpọ̀jù láti kojú irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Wọ́n dá àbá kíkọ́ ti ilé kékeré, tí kò wọ́n púpọ̀.
Ní ìgbà ìsọ̀rọ̀ tí ó ntẹ̀síwájú, Baba-àgbà Perry àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ rúnra, kó owó wọn jáde, wọ́n sì fi kún un. Njẹ́ wọ́n ní oye tó tó fún ìrìnàjo wọn láti padà àti láti dáwó sí kíkọ́ ti tẹ́mpìlì? Ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́hìnnáà, baba-àgbà mi dé ọ̀dọ̀ Joseph Smith, ó mú dọ́là marun ẹyọ-owó jáde, ó sì fi í fún Wòlíì. (Irú ẹyọ-owó kan ní ònì tí yíò jẹ́ bíi ọgọọgọ́ọ̀rún dọ́là!)
Joseph dúró níwájú ìgbìmọ̀ náà ó sì di ẹyọ-owó náà mú sókè. Nígbànáà, ó nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára ó wípé “iṣẹ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ àti pé Ilé [Olúwa] yíò di kíkọ́ gẹ́gẹ́bí a ti gbekalẹ̀” láti ọwọ́ Olúwa Jésù Krístì.
Ẹbí Perry láìpẹ́ darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní Kirtland, wọ́n gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wọn ní ọdún díẹ̀ lẹ́hìnnáà ní Tẹ́mpìlì Nauvoo, wọ́n sì sọdá àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ sí Utah.
Ní ìgbà tí a fi máa ya Tẹ́mpìlì Kirtland sí mímọ́ ní 1836, ó ti kéré jù láti gba gbogbo àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn tí wọ́n fẹ́ láti lọ fún ìyàsímímọ́ rẹ̀. Bí Ìjọ ṣe ndàgbà, bẹ́ẹ̀náà ni oye àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí wọ́n ní láti lọ sí àwọn ìpàdé òde. Ààrẹ James E. Faust (1920–2007), ẹni tí ó nsìn bí ààrẹ èèkàn mi nígbàtí mò wà ní ọ̀dọ́mọkùnrin àti bí olùtọ́ nígbàtí a pè mi bí Aláṣẹ Gbogbogbò ní 2007, ṣe àkíyèsí yí nípa tẹ́mpìlì kejì Ìjọ:
“Ṣíwájú kí a tó parí Tẹ́mpìlì Nauvoo ní 1846 àwọn Ènìyàn Mímọ́ npàdé ní òde, léraléra nítòsí tẹ́mpìlì, láti gbọ́ Joseph àti àwọn aṣaájú Ìjọ míràn tí wọ́n nsọ̀rọ̀. Nígbàmíràn àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún nlọ sí àwọn ìpàdé wọnnì”—nígbàmíràn àní nínú ojú-ọjọ́ líle.
“Bí [Alàgbà] George A. Smith ti ṣe àkíyèsí ní gbígba àlàmọ̀, ‘Ní àwọn ọjọ́ ti Wòlíì Joseph … [Ìjọ] ti gbilẹ̀ dídára jùlọ ní òde.’”
A fi ìmoore hàn pé ní ọjọ́ wa, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ngbilẹ̀ ní òde, ní ilé, àti káàkiri gbogbo ayé. Gbígbilẹ̀ náà pẹ̀lú kíkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ní ààyè àìlónkà “gẹ́gẹ́bí àwòṣe tí a gbékalẹ̀”—àwòṣe kan tí ó ti máa npẹ̀lú àwọn ìbùkún, ìyàsọ́tọ̀, ìgbàgbọ́, àti ìrúbọ.
Tẹ́mpìlì Kirtland—Ìmọ́lẹ̀ Ológo, láti ọwọ́ Glen S. Hopkinson, ni a kò lè dàkọ
Kínìdí Àwọn Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Tẹ́mpìlì?
“Awọn aṣíwájú wa ti sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn tẹ́mpìlì yíò kún ilẹ̀ Àríwá àti Gúsù Amẹrika, erékùṣù ti Pacific, Europe, àti ibomíràn,” Ààrẹ Eza Taft Benson (1899–1994) sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ díkédì sẹ́hìn. “Bí a ó bá ṣe iṣẹ́ ìràpadà yí lórí ìwọ̀n tí ó gbọ́dọ̀ jẹ́, ọgọọgọrun àwọn tẹ́mpìlì ní a ó nílò.”
Ààrẹ Russell M. Nelson wípé à nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì ni ààyè àìlónka ní òní “nítorí Olúwa ti kọ́ wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì nṣèrànwọ́ láti kó Ísráẹ́lì jọ ní ẹ̀gbẹ́ méjèjì ìkelè. Àwọn ìbùkún wọ̀nyí bákannáà nṣèrànwọ́ láti múra àwọn ènìyàn tí yíò múra ayé sílẹ̀ fún Bíbọ́ Ẹ̀ẹ̀kejì Olúwa!”
Nínú àdúrà ìyàsímímọ́ rẹ̀ ti Tẹ́mpìlì Kirtland, Joseph Smith gbàdúrà “pé gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn yíò wọ inú àlà ilé Olúwa lè ní ìmọ̀ agbára rẹ. …
“Àwọ sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ, Baba Mímọ́, pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ lè jáde lọ láti ilé yìí pẹ̀lú ìhámọ́ra agbára rẹ, àti pé kí orúkọ rẹ ó lè wà ní orí wọn, àti ògo rẹ yí wọn kákiri,àti kí àwọn ángẹ́lì rẹ ó máa ṣe ìtọ́jú wọn” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 109:13, 22; àtẹnumọ́ àfikún, bákannáà wo ẹsẹ 23).
Nígbàtí mo ka àwọn ẹsẹ wọnnì, mo ronú nípa ìran Néfì ti àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Ẹ kíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ irùkannáà: “Ó sì ṣe tí èmi, Néfì, kíyèsí agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn mímọ́ ti ìjọ onígbàgbọ́ ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, àti sórí àwọn ènìyàn májẹ̀mú ti Olúwa, àwọn tí a túká sórí gbogbo ojú àgbáyé; wọ́n sì gbáradì pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá” (1 Néfì 14:14; àfikún àtẹnumọ́).
Mo gbàgbọ́ pé àwọn tẹ́mpìlì ọjọ́ ìkẹhìn nṣe ojúṣe pàtàkì ní mímúṣẹ ti àsọtẹ́lẹ̀ Néfì ó si jẹ́ àárín-gbùngbun sí ààbò àti agbára ìlérí sí àwọn olóòótọ́ ṣíwájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́hìn, nígbàtí mo nsìn bí bísọ́ọ̀pù ní wọ́ọ̀dù Unifásítì, mo ní ìwọ̀lọ́kàn nípàtàkì nípa ọ̀dọ́mọbìnrin kan nínú wọ́ọ̀dù mi. Ó ṣì nmú mi ní ìwọ̀lọ́kàn. Ẹ mọ̀ ọ́ bí Ààrẹ Emily Belle Freeman, Ààrẹ Gbogbogbo àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin. Nínú ọ̀rọ̀ àìpẹ́ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, ó kọ́ni pé nípa tẹ́mpìlì, Jésù Krístì ngbé wa sókè sí ibi gígajù ti ẹ̀mí.
“Ní àkókò kọ̀ọ̀kan tí mo bá kọjá ní ẹnu ọ̀nà ilé Rẹ̀, mo nní ìrírí ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú jíjinlẹ̀ síi pẹ̀lú Rẹ̀,” ni Ààrẹ Freeman sọ. “Mo di yíyàsímímọ́ pẹ̀lú Ẹmí Rẹ̀, ríró pẹ̀lú agbára Rẹ̀, àti yíyà sọ́tọ̀ láti gbé ìjọba Rẹ̀ ga.”
Agbára Ìlérí
Ààrẹ Nelson ti sọ̀rọ̀ léraléra nípa agbára ti Jésù Krístì tí ó wà ní àrọ́wọ́tó nípa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì. “Síso ara yín pẹ̀lú Olùgbàlà túmọ̀ sí pé ẹ ní ààyè sí okun Rẹ̀ àti agbára ìràpadà.” ni ó sọ. Ààrẹ Nelson ti kọ́ni bákannáà:
“Bí a ti npa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa mọ́, à njèrè ààyè títóbijù sí agbára ìfúnnilókun ti Olúwa. Nínú Tẹ́mpìlì, a ngba ààbò látinú àwọn ìjìyà ti ayé.
“Àwọn ìlànà pàtàkì ti [Olùgbàlà] nso wá mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ oye-àlùfáà. Nígbànáà, bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Ó nró wa pẹ̀lú agbára ìwòsàn, ìfúnnilókun Rẹ̀ . Àti pé áh, bí a ó ṣe nílò agbára Rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ iwájú.”
“Agbára ìwà àti ti ẹ̀mí tí àwọn ènìyàn nílò lọ́wọ́lọ́wọ́ àti fún àwọn ọjọ́ ìwájú ni agbára Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. À njèrè ààyè sí agbára Wọn nípa dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Wọn.”
Agbára ti ọ̀run pọndandan, ẹ̀yin arákùnrin àti aràbìnrin, nítorí à ngbé nínú ayé búburú. Láìsí agbára náà, a kò ní lè “dúró de ọjọ́ bíbọ̀ rẹ̀” tàbí “dúró ní ìgbà tí ó bá dé” (Málákì 3:2). A kò mọ ìgbàtí ọjọ́ náà yíò jẹ́, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ Rẹ̀ ni a ti rán láti “múra ọ̀nà sílẹ̀” fún bíbọ̀ Rẹ̀ (Málákì 3:1). Níbayi, ayé kò yí jẹ́jẹ́ síwájú ọjọ́ náà.
A nílò agbára tí a ṣèlérí fún àwọn olóòótọ́ láti ràn wá lọ́wọ́:
-
Ẹ jẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé wa.
-
Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ sì súnmọ́ Olúwa síi.
-
Ẹ bùkún, tuni-nínú, darí, kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.
-
“Kojú àwọn àdánwò , ìdánwò, àti ìrora ọkàn wa dáradára” (wo Mòsíàh 3:19).
-
Kí a wá àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Krístì bí a ṣe nrìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
-
Ẹ múrasílẹ̀ ní “ìlòdì sí ọjọ́ jíjoni” àti “ibi ti àwọn ẹni búburú” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 109:46).
-
Ẹ ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ Olúwa ṣíwájú Bíbọ̀ Rẹ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì.
Fọ́tò ti Tẹ́mpìlì dome of Tucson Arizona látiọwọ́ James Whitney Young
Ìgbàlà àwọn Olùṣọ́
Iṣẹ́ àti ògo Baba Ọ̀run ni “láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ” (Mósè 1:39 Tẹ́mpìlì kọ̀ọ̀kan dúró bí ìṣọ́ ti ayé nípa ètò ìgbàlà Ọlọ́run, tí ó nnawọ́ sí àárín-gbùgbun ojúṣe Olùgbàlà nínú iṣẹ́ àti ògo náà.
Gbígbáradi pẹ̀lú agbára, gbogbo ọkùnrin àti obìnrin olùpamọ́-májẹ̀mú— tó ṣègbéyàwó tàbí tíkò ṣègbéyàwó—tí wọ́n pa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wọn mọ́ ní òtítọ́ yíò di alábùkúnfún nínú ayé yí àti ní ayé tí ó nbọ̀.
Ààrẹ Nelson ti ṣèlérí pé: “Òpin fún èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa ntiraka ni láti gba ẹ̀bùn agbára nínú ilé Olúwa, láti ní ìsopọ̀ bí ẹbí, láti jẹ́ olóòtọ́ sí àwọn májẹ̀mú tí a ṣe nínú tẹ́mpìlì tí ó mú wa yege fún ẹ̀bùn títóbi jùlọ ti Ọlọ́run—ti ìyè ayérayé. Àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mú tí ẹ dá níbẹ̀ jẹ́ kókó sí ìfùnlókun ìgbé ayé yín, ìgbéyàwó àti ẹbí yín, àti agbára yín láti tako àwọn àtakò èṣù. Ìjọ́sìn yín nínù tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìsìn yín níbẹ̀ fún àwọn babanlá yín yíò bùkún yín pẹ̀lú ìfihàn araẹni púpọ̀ síi àti àláfíà yíò sì dà ààbò bo ìfarajì yín láti dúró lórí ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Bí Àpọ́stélì Olúwa Jésù Krístì kan, mo jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ohun wọ̀nyí jẹ́ òtítọ́.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹwa 2025. Yoruba. 19611 779