2025
Kíkọ́ Nauvoo
Oṣù Kẹsan 2025


“Kíkọ́ Nauvoo,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹsan 2025, 26–28.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ̀ndì , Oṣù Kẹsan 2025

Kíkọ́ Nauvoo

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣíwájú ngbé nínú àgọ́ lẹgbẹ́ bèbè Odò Mississippi

Olúwa wí fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ láti kórajọ ní ibi titun kan. Ó jẹ́ nítòsí odò títóbi, níbití ilẹ̀ náà ti tutù tí ó sì ní ẹrẹ̀. Kò dàbí ẹnipé ó jẹ́ ibi rere láti kọ́ ìlú kan. Ṣùgbọ́n Wòlíì Jósẹ́fù Smith mọ̀ pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa, wọ́n lè mu di ẹlẹ́wà.

Ọkùnrin gbé igi sí orí èjìká rẹ̀, ẹṣin kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù pẹ̀lú àwọn ìpèsè ìkọ́lé, àti pákó àwọn àgọ́-igi.
Jósẹ́fù Smith àti àwọn ọkùnrin míràn tí wọ́n nmọ bíríkì bí wọ́n ṣe nkọ́ ilé kan

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nṣiṣẹ́ àṣekára láti mu jẹ́ ibi rere láti gbé. Jósẹ́fù pe ìlú náà ní Nauvoo, èyítí ó túmọ̀ sí “ibi tí ó lẹ́wà.”

Jósẹ́fù Smith nawọ́ sí ibi kan ní orí òkè fún tẹ́mpìlì kan

Olúwa nfẹ́ kí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀ kọ́ tẹ́mpìlì kan ní Nauvoo. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí nṣiṣẹ́ kíákíá.

Jósẹ́fù Smith nkọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ míràn nínú ilé kan

Olúwa ní àwọn ìbùkún nlá láti fún àwọn ènìyàn Rẹ̀. Nínú tẹ́mpìlì, wọ́n lè dá àwọn májẹ̀mú, tàbí àwọn ìlérí pàtàkì, pẹ̀lú Olúwa. Bákannáà wọn yíò kọ́ nípa ètò ìdùnnú Baba Ọ̀run fún gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀.

Tẹ́mpìlì Nauvoo tí a ti kọ́ tán

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nṣiṣẹ́ àṣekára láti kọ́ tẹ́mpìlì náà. Ó gba àkokò pípẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n ní ìnúdidùn láti kọ́ nípa àwọn ìlérí pàtàkì tí Olúwa ti fún wọn nínú tẹ́mpìlì Rẹ̀.

Ojú-ewé Kíkùn

Tẹ́mpìlì Jẹ́ Ilé Olúwa

Ojú-ewé kíkùn ti Ìṣe-ṣíṣe PDF tẹ́mpìlì kan

Ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert

Báwo ni ẹ ṣe ní imọ̀lára sí nígbàtí ẹ bá rí tẹ́mpìlì kan?