2025
Alábùkúnfún nípa Àṣẹ àti Agbára Oyè àlùfáà
Oṣù Kẹsan 2025


“Alábùkúnfún nípa Àṣẹ àti Agbára Oyè àlùfáà,” Làìhónà, Oṣù Kẹsan. 2025.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kesan 2025

Alábùkúnfún nípa Àṣẹ àti Agbára Oyè àlùfáà

Àwọn ọmọ Ìjọ nlo agbára Ọlọ́run láti sìn àti láti bùkún àwọn ẹlòmíràn ní Ìjọ, ní ilé, àti káàkiri àgbáyé.

Alàgbà D. Todd Christofferson

Ẹ̀rí wa sí ayé ni pé oyè àlùfáà mímọ́ ti Ọlọ́run ṣe pàtàkì ní ṣíṣe àṣeyọrí iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Rẹ̀, pé Ó ti mú oyè àlùfáà padàbọ̀sípò sí ilẹ̀ ayé fún èrèdí náà, àti pé ó ti di pípínfúnni nípasẹ̀ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.

Ìṣeéṣe ti Àṣẹ àti Agbára Oyè àlùfáà

Jésù Krístì ni olórí Ìjọ náà. Ìjọ náà ni ohun èlò tí Ó dásílẹ̀ láti ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ pàtàkì ti ìràpadà ọmọ-ènìyàn ní àkokò iṣẹ́-ìríjú ìhìnrere tó kẹ́hìn yí gẹ́gẹ́bí inú iṣẹ́-ìríjú ìgbàtí Ó gbé lórí ilẹ̀ ayé. Nípasẹ̀ Ìjọ:

  • Ó le kéde ìhìnrere Rẹ̀ káàkiri ayé.

  • Ó lè fúnni ní ìrìbọmi àti gbogbo àwọn májẹ̀mú míràn—àní ipa ọ̀nà májẹ̀mú sí ìjọba sẹ̀lẹ́stíà Rẹ̀.

  • A nṣe ìdàpọ̀ àwọn ẹbí fún ayérayé.

  • Ó lè fúnni ní àwọn ẹ̀bùn ìgbàlà, àní sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú láìsí wọn.

  • Ó lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn àìní ti ara àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ́wọ́lọ́wọ́.

Láti ṣe àṣeyọrí àwọn èrèdí ọlọ́lá wọ̀nyí, àti láti múrasílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Olùgbàlà, Ìjọ nílò ìdarí, àṣẹ, àti agbára Ọlọ́run tó nlọ lọ́wọ́. Ìjọ ni “ìjọ alààyè àti òtítọ́” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:30) nítorí Krístì fi dókòwò pẹ̀lú ipò-olórí àti agbára Rẹ̀ nípasẹ̀ oyè àlùfáà, “Oyè àlùfáà Mímọ́, lẹ́hìn Ètò ti Ọmọ Ọlọ́run” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:3).

Ṣùgbọ́n fún oyè àlùfáà mímọ́ yí, Ìjọ yíò jẹ́ ìṣètò ti ẹ̀kọ́ nípàtàkì, ṣíṣe rere nínú ayé ṣùgbọ́n láìlágbára láti ṣe àṣeyege èrèdí ìgbẹ̀hìn ní mímúra àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún ayọ̀ ìyè ayérayé ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Pẹ̀lú oyè àlùfáà yí, àti àwọn kọ́kọ́rọ́ láti darí iṣẹ́ oyè àlùfáà yí, méjèèjì àṣẹ àti ètò ni ó wà nínú Ìjọ.

“Nínú Ìjọ, gbogbo àṣẹ oyè àlùfáà ni a nlò lábẹ́ ìdarí àwọn wọnnì tí wọ́n di àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú.

“Àwọn ọkùnrin ọmọ Ìjọ ngba àṣẹ oyè àlùfáà nípasẹ̀ ìfúnni àti fífi àmì òróró yàn sí àwọn ipò oyè àlùfáà. Gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ lè lo yíyan àṣẹ fúnni bí a ṣe nyà wọ́n sọ́tọ̀ tàbí yàn wọ́n láti ṣèrànwọ́ àṣeyọrí iṣẹ́ Ọlọ́run.”

Nípasẹ̀ àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà, àwọn ààyò Olúwa yíò borí nígbàgbogbo. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè ṣe ìmúdúró àgbéṣe araẹni tí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìdárí Rẹ̀. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè ṣe àṣeyege nínú iṣ̣ẹ́ àlùfáà àrékérekè, wíwá èrè araẹni àti títẹ̀lé araẹni.

Bákannáà oyè àlùfáà nṣe ojúṣe líle nínú ilé àwọn ọmọ Ìjọ. Ààrẹ Dallin H. Oaks, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Kínní, kọ́ni pé, “Ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí àṣẹ oyèàlùfáà tí a lè lò lábẹ́ ìdarí ẹnikan tí ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ mú fún iṣẹ́ náà jẹ́ ìpìlẹ̀ nínú Ìjọ, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nínú ẹbí.” Àwọn baba nṣe àkóso wọ́n sì nlo oyè àlùfáà nínú ẹbí wọn—dá àmọ̀ràn, ṣe àwọn ìpàdé ẹbí, fi oyè àlùfáà tàbí àwọn ìbùkún ìwòsàn fún mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ẹlòmíràn, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ—láìsí ìdarí tàbí fífún ẹnìkan tí ó di awọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà mú.

“Irú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kannáà wúlò nígbàtí kò bá sí baba kan tí ìyá kan sì jẹ́ olórí ẹbí. Ó nṣàkóso nínú ilé rẹ̀ ó sì jẹ́ ẹni tó nmú agbára àti ìbùkún oyèàlùfáà wá sínú ẹbí rẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀bùn tẹ́mpìlì rẹ̀ àti èdìdi nínú tẹ́mpìlì.”

Ìmúpadàbọ̀sípò Oyè àlùfáà ní Ọjọ́ Wa.

Ọjọ́ Karùndínlógún Oṣu Karun, 1829

Jòhánnù Onítẹ̀bọmi mú Oyè Àlùfáà Áárónì padàbọ̀sípò fún Joseph Smith Kékeré àti Oliver Cowdery

Ìmúpadàbọ̀sípò àṣẹ oyè àlùfáà ní àkokò iṣẹ́ ìríjú tó kẹ́hìn yí ntẹ̀síwájú létòletò, ìlọsíwájú ní ìṣísẹ̀-sí-ìṣísẹ̀. Gẹ́gẹ́bí ti ìpìlẹ̀ ìwé mímọ́ fún àkokò iṣẹ́ ìríjú wa, Ìwé ti Mọ́mọ́nì, ni a ṣe ìyírọ̀padà ní 1829, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí fi oyè àlùfáà Rẹ̀ sí ètò. Ní ìfèsì sí àdúrà ìbèèrè ti Jósẹ́fù Smith àti Oliver Cowdery nípa ìríjú, olùjíìnde Jòhánnù Onítẹ̀bọmi farahàn ó sì fi Oyè Àlùfáà Áárónì lé wọ́n lórí, oyè àlùfáà èyítí “ó di àwọn kọ́kọ́rọ́ iṣẹ́́ ìránṣẹ́ awọn ángẹ́lì, àti ìrìbọmi nípa rírìbọmi fún ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mú” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 13:1). Pẹ̀lú àṣẹ náà, Jósẹ́fù àti Oliver ṣe ìrìbọmi fún ara wọn àti lẹ́hìnnáà sí àwọn ẹlòmíràn bí Ìjọ náà ni a ṣètò tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.

Láìpẹ́ lẹ́hìn Ọjọ́ karùndínlógún Oṣù Karun, 1829

Ìmúpadàbọ̀sípò Oyèàlùfáà Mẹ́lkìsédékì

Láìpẹ́ lẹ́hìn tí Jòhánnù Onítẹ̀bọmi farahàn, àwọn àpóstélì àtijọ́ Pétèrù àtijọ́, Jákọ́bù, Jòhánnù farahàn wọ́n sì fi gígajù, tàbí oyè Àlùfáà, Melkísédékì fúnni, pẹ̀lú “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba mi, àti àkokò iṣẹ́ ìríjú ìhìnrere fún … ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ awọn àkókò” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 27:13; bákannáà wo 128:20).

Ọjọ́ Kẹ́ta Oṣu kẹrin, 1836

àwọn pẹpẹ ní Tẹ́mpìlì Kirtland

Àfikún àṣẹ oyè àlùfáà tí a nílò wá tẹ̀le nígbàtí, Ní Tẹ́mpìlì Kirtland, àwọn wòlíì mẹ́ta àtijọ́, Mósè, Élíásì, àti Èlíjàh, farahàn sí Jósẹ́fù àti Oliver wọ́n si fi àwọn kọ́kọ́rọ́ kíkójọ Ísráẹ́lì tí ó jẹmọ́ tẹ́mpìlì Olúwa (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 110:11–16).

Ìgbà-ẹ̀rùn 1829 sí Oṣù Kẹ́rin 1835

Joseph Smith Kékeré képe àwọn Ènìyàn Mímọ́ ọmọ ìjọ ìṣíwájú nínú àwọn ìpè titun

Àwọn ìfihàn ìsisìyí tí a fi pe àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Ẹ̀kọ́ àti Májẹ̀mú kọ́ Wòlíì Joseph Smith nípa fífi àmì òróró yàn fún àwọn ọkùnrin sí àwọn ipò ti àwọn oyè àlùfáà gíga (Mẹlkisédékì) àti mímúrasílẹ̀ (Áárónì); yíyàn àwọn olóyè oyè àlùfáà, bíiti àwọn bíṣọ́ọ̀pù; àti ìṣètò iyejú àti ìgbìmọ̀ oyè àlùfáà.

1835–1973

àwọn olùlànà nsọdá àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀

Ìdarí ti wòlíì ntẹ̀síwájú láti tọ́ ìṣètò oyè àlùfáà àti ìṣe sọ́nà ní Ìjọ. Fún àpẹrẹ, àwọn iyejú Àádọ́rin ni a ṣètò ní àkokò Kirtland láti ran Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá lọ́wọ́. Lẹ́hìn ìkólọ nlá sí Ìwọ̀-òòrùn àti fífọ́nká àwọn ọmọ Ìjọ sọdá àwọn agbègbè ààlà gbígbòòrò, àwọn iyejú wọ̀nyí ni a yàn láti ṣiṣẹ́ ní àwọn èèkàn Ìjọ.

1973–Ìsisìyí

akọrin nkọrin ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò

Lábẹ́ àkóso àwọn Ààrẹ Spencer W. Kimball (1895–1985), Ezra Taft Benson (1899–1994), àti Gordon B. Hinckley (1910–2008), àwọn Àádọ́rin àti iyejú wọn bẹ̀rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ tààrà lábẹ́ Iyejú àwọn Méjìlá ní ipele gbogbogbò Ìjọ àti ní àwọn agbègbè Ìjọ. Àwọn Iyejú ní ipele èèkàn ni a ti dádúró. Ní òní, àwọn iyejú méjìlá ti Aláṣẹ Gbogbogbò àti Àádọ́rin Agbègbè nràn àwọn Àpóstélì lọ́wọ́ “ní gbígbé ìjọ ga àti títún gbogbo àlámọrí ti irúkannáà ṣe ní gbogbo orílẹ̀-èdè” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 107:34). Àfikún àwọn iyejú ti Àádọ́rin ni a lè dásílẹ̀ láti mú Ìjọ gbòòrò si.

Alàgbà Christofferson kí àwọn ọmọ ìjọ̀ ní Gambia

Alàgbà Christofferson kí àwọn arákùnrin Sampson àti Daniel Amako ní Gambia, West Africa, ní Oṣù Kejì 2022.

Oyè àlùfáà: Agbára láti Bùkúnfún

Ní ọ̀rọ̀ kan, èrèdí àṣẹ oyè àlùfáà àti agbára tí Jésù Krístì múpadàbọ̀sípò niláti bùkún wa. Ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ìjọ nlo agbára Ọlọ́run láti sìn àti láti bùkún àwọn ẹlòmíràn ní Ìjọ, ní ilé, àti káàkiri àgbáyé. Àwọn ọmọ ìjọ darapọ̀ mọ́ Olùgbàlà ní ṣíṣe àṣeyọrí iṣẹ́ Rẹ̀ nípa ìgbàlà àti ìgbéga, ní gbígba àwọn ẹ̀bùn àti agbára tí ó kọjá ti arawọn láti ran ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ láti kún ilẹ̀ ayé (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 65:2, 5–6).

Olúwa ti ṣe àlàyé pé “oyè Àlùfáà [Melkísédékì] títóbijù yí nṣe ìpínfúnni ìhìnrere wọ́n sì di kọ́kọ́rọ́ ti àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba, àní kọ́kọ́rọ́ ti ìmọ̀ Ọlọ́run mú.

“Nítorínáà, nínú awọn ìlànà ibẹ̀, agbára ìwàbí Ọlọ́run nfarahàn.

“Àti láìsí àwọn ìlànà ibẹ̀, àti àṣẹ oyè àlùfáà, agbára ìwàbí Ọlọ́run kò lè fi ara hàn fún àwọn ènìyàn nínu ẹran ara” (Ẹ̀kọ́ àti Májẹ̀mú 84:19–21).

Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ìlànà, ni àwọn ayẹyẹ ìpínfúnni oyè àlùfáà tàbí àwọn oúnjẹ Olúwa nípa èyí tí à ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrìbọmi ó sì ntẹ̀síwájú nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú tí a gbà nínú ilé Olúwa. Ó jẹ́ ní pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ ni à ndi yíyípadà kúrò ní “ẹlẹ́ran ara” ọkùnrin àti obìnrin sí ènìyàn mímọ́ (wo Mòsíàh 3:19) nípa oore ọ̀fẹ́ ètùtù Krístì àti dída olùdáláre àti olùyàsímímọ́ pẹ̀lú—aláìlẹ́bi àti aláìlábàwọ́n—níwájú Ọlọ́run (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:29–31; 3 Néfì 27:16–20).

Àyọsọ yí látinú “Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Jésù Krístì: Ìkéde Igba Ọdún Kan sí Àgbáyé,” láti ọwọ́ Àjọ Ààrẹ Kínní àti Ìgbìmọ̀ ti awọn Àpóstélì Méjìlá, ṣe àfihàn àkópọ̀ ìbámu:

“A kéde pé Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, tí a ṣètò ní Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin, 1830, ni Ìjọ Krístì Májẹ̀mú Titun tí a múpadàbọ̀sípò. Ìjọ yí ni ó rọ̀mọ́ ìgbé ayé pípé ti olórí igun-òkúta rẹ̀, Jésù Krístì, àti Ètùtù Àìlópin Rẹ̀ àti gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Àjíìnde ti rí gan. Jésù Krístì ti pe àwọn Àpóstélì lẹ́ẹ̀kansi ó sì ti fún wọn ní àṣẹ oyè-àlùfáà. O pe gbogbo wa láti wá sí ọ́dọ̀ Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀, láti gba Ẹ̀mí Mímọ́, àwọn ìlànà ìgbàlà, àti láti jèrè ayọ tí ó dúró títí.