2025
Ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì: Ìdí náà àti Báwo
Oṣù Kẹrin 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Kẹrin, 2025

Ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì: Ìdí náà àti Báwo

Ẹ ní òye ìdí tí Jésù Krístì fi jẹ́ ìdáhùn náà àti bí Ó nṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín.

Jésù Krístì

Ìjúwe nípasẹ̀ Dan Wilson

“Mo ní ìmọ̀lára bi ẹnipé mo nṣe àṣìṣe síi. Ó ṣòro láti tẹramọ́ gbígbìyànjú.”

“Ipò mí jẹ́ líle. Èmi kò ní ìdánilójú bí mo ṣe lè tẹ̀síwájí.”

“Mo ṣe àníyàn nípa ọjọ́ iwájú. Èmi kò mọ bóyá mo ní ohun tí ó gbà láti ṣe àṣeyọrí.”

“Ó rẹ̀ mí, ṣùgbọ́n díẹ̀ síi ṣì wà láti ṣe.”

Ṣé ẹ lè ní ìbámu sí èyíkéyi nínu àwọn ìṣòro wọ̀nyí? Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni, “Eyikeyi àwọn ìbèèrè tàbí àwọn ìdàmú tí ẹ ní, ìdáhùn náà ni à nrí nígbàgbogbo nínú ayé àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì” (“Ìdáhùn Náà Nígbàgbogbo ni Jésù Krístì,” Oṣù Kẹrin. 2023 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò [Lìàhónà, Oṣù Karun 2023, 127]).

Ó rọrùn láti sọ pè, “Jésù Krístì ni ìdáhùn náà.” Yíò gba ìgbìyànjú díẹ̀ síi láti ní òye ìdí náà àti báwo Ni Òun ṣe jẹ́ ìdáhùn.

Kíni Ìdí tí Krístì fi jẹ́ Ìdáhùn?

Nígbà tí Ó farada ẹbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà ṣe àwọn ohun pàtàkì mẹ́ta:

  1. Ó ṣẹ́gun ikú, ó sì jẹ́ kí a jínde.

  2. Ò san owó fún gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀, ó jẹ́kí ó ṣeéṣe fún wa láti ronúpìwàdà, dàgbà, àti láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìyẹn tún ràn wá lọ́wọ́ láti dáríji àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀, nítorí Kristi gbé ẹ̀ṣẹ̀ wọn lé Ara Rẹ̀.

  3. Ó ní ìrírí gbogbo àwọn ìrora, àwọn ìpọ́njú, àwọn àdánwò, àwọn àìsàn, àti àwọn àìlera wa lé Ararẹ̀ (wo Álmà 7:11–13). Ìyẹn túmọ̀ si wípé Òun mọ gangan bí Òun ṣe lè ṣe ìrànlọ́wọ́ kí Ó sì mú yín láradá kí Ó sì fún yín lókun láti farada àwọn ìdánwò àti láti tiraka láti di dídára síi.

Ẹ mú ìṣòro èyíkéyi, kí ẹ sì lè so ojútu náà padà pọ̀ mọ́ ọ̀kan tàbí díẹ̀ síi nípa àwọn òtítọ́ mẹ́ta wọ̀nnì.

Òṣì? Nítorí Jésù Krístì ní ìrírí àwọn ohun gbogbo, Òun mọ gangan ohun tí ó dàbí. Òun kìí yọ ìdíwọ́ kúrò nígbàgbogbo, ṣùgbọ́n Ó lè fún àwọn ènìyàn tí ó ru ẹrù náà lágbára (wo Mosiah 24:15).

Ìkùnà? Nítorí Krístì borí ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ìkùnà wa kò nílò láti wà títíláé. Ìrònúpíwàdà pẹ̀lú ìmúdára àti di díẹ̀ síi ènìyàn tí ó mọ̀ pé a lè jẹ́.

Àìsàn? Nítorí pé Ó ṣẹ́gun ikú, a ò jí gbogbo wa dìde ní pípé pẹ̀lú ara tí kò le ṣàìsàn àti ìrora. Krístì tún “[gbé] àwọn àìsàn … lé orí ara rẹ̀” (Alma 7:11), ní mímú Un di ènìyàn pípé láti pèsè ìtùnú àti àtìlẹ́hìn.

Báwo ni Krístì Ṣe ṣe Ìrànlọ́wọ́?

Ṣùgbọ́n àní nígbàtí a bá mọ ìdí náà tí Olùgbàlà fi jẹ́ ìdáhùn (nítorí ẹnití Ó jẹ́ àti ohun tí Ó ṣe fún wa), a ṣì nílò láti mọ báwo ni a ṣe gba ìrànlọ́wọ́ àti agbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Nihin ni àwọn ọ̀nà díẹ̀:

Àdúrà Nípa gbígbàdúrà ní orúkọ Jésù Kristi, àwọn èèyàn aláìpé bíi tiwa lè bá Ọlọ́run pípé kan sọ̀rọ̀. A lè gbàdúrà fún okun tí a nílò nínú ipòkípò, Ọlọ́run yíò sì dáhùn—kì í ṣe nígbà gbogbo lọ́nà tí a fẹ́ tàbí tí à nretí, ṣùgbọ́n lọ́nà tí yíò bùkún wa. Ìpè Olùgbàlà jẹ́ òtítọ́: “Bèèrè, ẹ̀yin yíò sì rígbà” (Jòhánnù 16:24; 3 Néfì 27:29; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 4:7).

Ẹ̀bùn ti Ẹ̀mí Mímọ́. Baba Ọ̀run, Jésù Krístì, àti Ẹ̀mí Mímọ́ ni ìṣọ̀kan nínú èrèdí. Wọ́n ṣiṣẹ́ papọ̀! Nígbàkugbà tí ẹ ba ní ìtọ́nisọ́nà tàbí ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Ẹmí Mímọ́, ẹ lè ní òye ìyẹn bí Krístì ṣe nràn yín lọ́wọ́ pẹ̀lú.

Pípa Àwọn Májẹ̀mú Mọ́. Bí Alàgbà Dale G. Renlund ti Iyejú Àwọn Àpóstélì Méjìlá ti kọ́ni, “Ọ̀rọ̀ náà ipa-ọ̀nà májẹ̀mú tọ́ka sí oríṣiríṣi àwọn májẹ̀mú nípa èyítí a fi nwá sọ́dọ̀ Krístì tí a sì nso mọ́ Ọ. Nípasẹ̀ àsopọ̀ májẹ̀mú yìí, a ní ààyè sí agbára ayérayé Rẹ̀” (Oṣù Kẹrin. 2023 ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò [Lìàhónà, Oṣù Karun 2023, 36]).

Ore-ọ̀fẹ́ Nígbàtí a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì tí a sì ronúpìwàdà, a lè gba àfikún ìrànlọ́wọ́ àti okun (tí a ń pè ní ore-ọ̀fẹ́ bákannáà) láti ṣe àṣeparí àwọn ohun tí a kì bá lè ṣe fúnra wa (wo Ìtọ́nisọ́nà sí Ìwé Mímọ́, “Ore-ọ̀fẹ́”). Agbára yi, tàbí ore-ọ̀fẹ́, lè wá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà: láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, ọ̀rẹ́, àlejò, ìmọ̀lára. Ní kókó, ohun rere gbogbo nwá láti ọ̀dọ̀ Krístì (wo Mọ́rónì 7:22). Nígbàtí ẹ ba rí sùúrù díẹ̀ sí i, agbára díẹ̀ sí i, okun díẹ̀ sí i làti faradà, ẹ dá ìyẹn mọ̀ bí Krístì ti nràn ọyín lọ́wọ́.

Ẹ Rántí Ìdí àti Báwo

Nítorínáà nígbà míràn tí ẹ bá nílò ìdáhùn sí ìbéèrè tàbí ìṣòro kan, ẹ wo Krístì. Ẹ rántí pé nítorí ìṣẹ́gun Rẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, ikú, àti gbogbo ìpèníjà igbésí-ayé, kò sí ohun tí kò ṣeéṣe. Ẹ wá bí Òun ṣe lè bùkún un yín, ẹ̀yin yíò sì rí ipa Rẹ̀ nínú ìgbésí-ayé yín. Ó fẹ́ràn rẹ jinlẹ̀!