“Baba Ọ̀run Fẹ́ Bá Yín Sọ̀rọ̀,” Làìhónà, Oṣù Kẹta 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹta 2025
Baba Ọ̀run Fẹ́ Bá Yín Sọ̀rọ̀
Ẹ jẹ́kí ìgbàgbọ́ yín nínú Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ràn yín lọ́wọ́ pín ìkelè níyà kí ẹ sì gba ohùn ti Baba.
Àwa jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run, tí a jọ npín ilẹ̀ ayé papọ̀ jìnnà sí ilé wa ti ọ̀run. Èyí ni ayé kíkú wa, àkókò láti gba àgọ́ ara wa, yan rere dípò ibi, “tọ́ kíkorò wò, ki [awa] le mọ láti díyelé rere” (Mósè 6:55), mú ìgbàgbọ́ wa dàgbà nínú Olùgbàlà wa Jésù Krístì àti Ètùtù mímọ́ Rẹ̀, kí a sì gba èrò ìdùnnú ti Baba mọ́ra. A wà níhin láti dà bíi Baba wa Ọ̀run síi.
Láìsí ìrántí kan nípa gbígbé ṣaájú ayé-kíkú wa, àwa, nígbàmíràn, nní ìmọ̀lára dídánìkanwà fún ayé tí a fi sílẹ̀ lẹ́hìn. Baba wa ti fún wa ní ẹ̀bùn ti ẹ̀mí láti wà ní sísopọ̀ mọ́ Òun àti láti gba ìtọ́ni; ìdarí, áti ìtùnú láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. A mọ ẹ̀bùn yí dáradára, òun ni a npè ní àdúrà.
Ẹ Gbàdúrà sí Baba Yín Ọ̀run.
Sí Ádámù àti Éfà àti gbogbo ẹnití yío bá tẹ̀lé wọn, angẹ́lì kan kọ́ni pé, “Ìwọ yío ronúpìwàdà kí o sì ké pe Ọlọ́run ní orúkọ Ọmọ náà títí láéláé (Mósè 5:8).
Jésù kọ́ni pé:“Ẹ bèèrè, a ó sì fi fún yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣíi sílẹ̀ fún yín” (Máttéù 7:7). “Nígbàtí ẹ̀yin bá ńgbàdúrà, … ẹ gbàdúrà sí Baba yín … ní ìkọ̀kọ̀” (Máttéù 6:6). “Nítorínáà báyìí ni kí ẹ̀yin ó máa gbàdúrà: Baba wa tí nbẹ ní ọ̀run, Ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ rẹ” (Máttéù 6:9).
Jésù gbàdúrà títílọ sí Baba Rẹ̀. “Ó jáde lọ sí orí òkè kan láti gbàdúrà, Ó sì tẹ̀síwájú ní gbogbo òru nínú àdúrà sí Ọlọ́run” (Lúkù 6:12). “Àti pé … ó kọjá lọ sí òkè kan láti gbàdúrà” (Markù 6:46). “Wọ́n sì wá sí ibìkan èyítí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Gẹ́tsémánè: ó sì wí fún àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ pé, Ẹ jókòó nìhin, nígbàti èmi yío gbàdúrà” (Markù 14:32). Nígbàtí ó wà ní orí àgbélèbú, Jésù gbàdúrà fún àwọn ológun tí wọ́n kàn Án mọ́gi: “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n nṣe.” (Lúkù 23:34).
Àwọn ìwé mímọ́ gbà wá nímọ̀ràn láti “gbàdúrà nígbà gbogbo” (Lúkù 21:36; 2 Néfì 32:9; 3 Néfì 18:15; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 10:5; 19:38; 20:33; 31:12). “Dá ìmọ̀ràn pẹ̀lú Olúwa nínú ohun gbogbo tí ìwọ bá nṣe, òun yíò sì tọ́ ọ sọ́nà fún rere” (Álmà 37:37). Ní àfikún, a “nṣe gbogbo ọpẹ́ àti ìyìn èyítí gbogbo ọkàn [wa] ní agbára láti ní” (Mòsíà 2:20), ní mímọ rírì gbogbo ohun tí Baba wa nṣe fún wa.
Ààrẹ Russell M. Nelson ṣàlàyé pé: “Ìmọrírì-araẹni ti ẹ̀mí ńbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mímọ̀ pé òwúrọ̀ titun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀sọ̀ Ọlọ́run. … Ó npawá mọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́ ó sì ntìwá lẹ́hìn láti àkókò kan sí òmíràn (wo Mòsíà 2:21).”
Néfì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá fetísílẹ̀ sí Ẹ̀mí èyí tí nkọ́ ènìyàn láti gbàdúrà, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé ẹ̀yin gbọdọ̀ gbàdúrà; nítorí ẹ̀mí ibi kì í kọ́ ènìyàn láti gbàdúrà, ṣùgbọ́n ó nkọ́ ọ pé òun kò gbọdọ̀ gbadura” (2 Néfì 32:8).
Àlàyé láti inú Krístì tí ńfa Ọmọbìnrin Jáírù Dìde, láti ọwọ́ Greg K. Olsen
Pẹ̀lú àpẹrẹ Olùgbàlà wa àti ìmọ̀ràn àwọn ángẹ́lì àti àwọn wòlíì ní gbogbo àwọn sẹ́ntíúrì, a mọ̀ ní kedere láti gbàdúrà lójoojúmọ́ láti fi ìmoore hàn fún àwọn ìbùkún wa, àti láti fi àdúrà kan sí inú ọkàn wa nígbàkugbà. A ní ojúṣe láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba wa.
Ṣùgbọ́n èyí tó lógo jù pàápàá, Baba wa ní Ọ̀run ndáhùn sí àwọn àdúrà wa. Ìbéèrè kan tó nírònú nínú ayé kíkú yìí ni pé, báwo ni a ṣe le gbà kí a sì ní òye dídára síi nípa àwọn ìdáhùn, ìdarí, àti ìtùnú tó nwá láti ọ̀dọ̀ Baba wa?
Nínú ó lé ní dẹ́kéèdì méje ìgbésí ayé mi, mo mọ̀ pé Baba wa nbá wa sọ̀rọ̀. A kò dá nìkan wà. Àwọn ẹ̀dá ọ̀run ńṣe iṣọ́ lórí wa wọ́n sì nrànwá lọ́wọ́ bí a ti nlépa láti tẹ̀lé Olùgbàlà.
Gbígba àwọn ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wa nínú Baba wa Ọrun àti nínú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì. Jésù wí pé, “Máṣe bẹ̀rù, ṣá gbàgbọ́ nìkan” (Markù 5:36). A ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀, a nṣe bí a ti le ṣe dára jùlọ láti pa àwọn òfin mọ́, a sì nwò fún ọwọ́ Rẹ̀ nínú ohun gbogbo. “Àti nínú ohunkóhun kọ́ ni ènìyàn ti ṣẹ Ọlọ́run … bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọn kò jẹ́wọ́ agbára rẹ̀ nínú ohun gbogbo, àti tí wọn kò gbọ́ràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 59:21).
Ọwọ́ Ọlọ́run nínú ígbésí ayé wa kò túmọ̀ sí pé Ó nfa ibi tàbí àwọn àjálù burúkú tí wọ́n wà nínú ayé wa. Ṣùgbọ́n, ó túmọ̀ sí pé nínú àwọn àkókò ìṣoro àti àìdára yín, Òun ó dúró tì yín, fún àwọn agbára yín lókun, tù yín nínú, yío sì “ya àwọn ípọ́njú yín sí mímọ́ fun èrè yín” (2 Néfì 2:2).
Ẹ Gbọ́ Ohùn Rẹ̀
Bí a ti nní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ tí a sì npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, a nkọ́ ní ti abínibí láti gbọ́ ohùn Rẹ̀ dáradára síi.
Ní Oṣù Kẹsan 1993, ọdún àkọ́kọ́ mi bíi Aláṣẹ Gbogbogbò, Ààrẹ James E. Faust (1920–2007), ọmọ ẹgbẹ́ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá nígbànáà, pe ìyàwó mi, Kathy, àti èmi láti wà pẹ̀lú òun níbi àkànṣe ìsìn kan ní Fásitì Brigham Young. Ẹ rántí, 1993 jẹ́ ṣaájú ìtànkálẹ̀ wíwà-ní-àrọ́wọ́tó ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká, ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn, àti ayélujára.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ohùn ti Ẹ̀mí Náà,” Ààrẹ Faust kìlọ̀ pé: “Ní ìran tiyín ẹ ó ní ìyọlẹ́nu nípasẹ̀ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ohùn ti yío máa sọ fún yín bí ẹ ó ti gbé ìgbésí ayé, bí ẹ ó ti ṣe sí àwọn ìfẹ́ inú yín, bí ẹ ó ti ní gbogbo rẹ̀ tán Ẹ ó ní tó bíi ọgọ́run márun àwọn ìkànnì ẹrọ amóhùn-máwòrán ní orí ìka yín. Oríṣiríṣi àwọn ohun èlò ìgbàlódé, àwọn módẹ́mù kọ̀npútà àjùmọ̀lò, àwọn ibi ìkó-ọ̀rọ̀-sí, àti àwọn pátákó ìkéde, ìwé títẹ̀ orí tábìlì, ẹ̀rọ alátagbà sátẹ́láìtì, àti àwọn fánrán ìbáraẹni-sọ̀rọ̀ yio wà tí yío fún yín lọ́rùn pẹ̀lú ìwífúnni. … Ohùn náà tí ẹ gbọdọ̀ kọ́ láti fetísí ni ohùn ti Ẹ̀mí.”
Ààrẹ Boyd K. Packer (1924–2015), Ààrẹ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, kọ́ni nípa ohùn jẹ́jẹ́, kékeré ti Ẹ̀mí ní ṣíṣe àtúnwí ìrírí kan ti John Burroughs, onímọ̀ àdánidá kan, bí ó ti nrìn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ kọjá níbi ìgbafẹ́ elérò-púpọ̀ kan. Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Packer:
“Tayọ àwọn ariwo ìgbésí ayé inú ìlú [Ọ̀gbẹ́ni Burroughs] gbọ́ orin ẹyẹ kan.
“Ó dúró ó sì fetísílẹ̀! Àwọn ti wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ kò gbọ́ ọ. Ó wo àyíká. Kò sí ẹnikẹ́ni míràn tí ó kíyèsí i.
“Ó dààmú rẹ̀ pé gbogbo wọn yío pàdánù ohun kan tí ó rẹwà tóbẹ́ẹ̀.
“Ó mú ẹyọ owó kan láti apò rẹ̀ ó sì jù ú sínú afẹ́fẹ́. Ó gbá ibi pèpéle náà pẹ̀lú igun kan, tí kò pariwo ju orin ẹyẹ náà lọ. Gbogbo wọn yípadà, wọ́n le gbọ́ èyí!
“Ó ṣòro láti ya orin ẹyẹ kan sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo àwọn ariwo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ilú. Ṣùgbọ́n o lè gbọ́ ọ. O lè gbọ́ ọ kedere bí o bá kọ́ ara rẹ láti fetísilẹ̀ fún un.”
Àwọn ìkọ́ni ti Ààrẹ Packer nípa Ẹ̀mi Mímọ́ ṣẹlẹ̀ ní 1979, ní àkókò kan nígbàtí ìgbésí ayé sì dákẹ́ jẹ́jẹ́ púpọ̀ tí ariwo àgbáyé sì jẹ́ rírẹ̀sílẹ̀ síi ju bí ó ti wà nísisìyí lọ.
Ààrẹ Nelson kọ́ni pé, “Bí ẹ bá nṣe àfiyèsí sí àwọn nkan láti inú ibákẹ́gbẹ́ ìrohìn ju bí ẹ ti nṣe sí àwọn ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ti Ẹ̀mi, nígbànáà ẹ nfi ara yín sí inú ewu ti ẹ̀mí.”
Ààrẹ Faust wí pé, “Bí a bá níláti fetísílẹ̀ sí ohùn Ẹ̀mí náà, àwa náà gbọdọ̀ ṣí etí wa, kí a yí ojú ìgbàgbọ́ sí orísun ohùn náà, ki a sì wò pẹ̀lú ìdúróṣinṣin sí ihà ọ̀run.”
Ohùn ti Ẹ̀mí yí nwá sí ọgbọ́n ìwòye àti àwọn ìmọ̀lára wa. “Èmi ó wí fún yín nínú iyè yín àti nínú ọkàn yín, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, èyí tí yíò wá sórí yín àti tí yíò gbé nínú ọkàn yín” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 8:2). Ẹ fetísílẹ̀ sí ẹ̀rí ọkàn yín—ìfihàn máa nsábà bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀.
Ní àkókò àbẹ̀wò sí Agbo Ilé Ibùgbé Àwọn Ọmọbìnrin Ìlú Àwọn Ọmọkùnrin ní Ìlú Markina, Philippines, ni Oṣù Kejì 2024, Alàgbà Andersen kọ́ àwọn ọ̀dọ́ náà pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run: “Ó fẹ́ràn yín. Ẹ sì le bẹ̀bẹ̀ sí I. Òun yíò gbọ́ àwọn àdúrà yín.”
Ẹ gbàdúrà pẹ̀lu Ọkàn tó Ngbàgbọ́
Àwọn ìdáhùn àti ìtẹ̀mọ́ra ni a kò lè kàn nípá. A ngbàdúrà a sì ndúró pẹ̀lú ọkàn tó ngbàgbọ́. Àwọn ìdáhùn kan kò ní wá nínú ayé yí, ṣùgbọ́n sí àwọn olódodo, Olúwa yío fi ìgbà gbogbo rán àlàáfíà Rẹ̀ (wo Jòhánnù 14:27). Àwọn ìdáhùn máa nsábà wá nígbàtí a bá ngbàdúrà láti ran àwọn tó wà ní àyíka wa lọ́wọ́. Ní àwọn ìgbà míràn, wọ́n nwá ní “ìlà lórí ìlà, ẹsẹ lórí ẹsẹ” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 98:12).
Ohùn ti ọ̀run le wá sí ọ̀dọ̀ wa ní àwọn àkókò tí a kò retí àti ní àwọn ibi tí a kò retí, ṣùgbọ́n a nrí àwọn ànfààní wa to gbayì jùlọ ní àwọn àyè to dákẹ́ jẹ́jẹ́ àti ní àwọn ibi mímọ́. Nínú ìdúrójẹ́ mi nínú àwọn àdúrà àti àròjinlẹ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, mo máa nrí àwọn ìbùkún tí kò wọ́pọ̀. Kíka àwọn ìwé mímọ́ ní ojojúmọ́, ní ti ara ẹni, láìsí ìdíwọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ àṣetúnṣe ní àwọn ìgbà kan, ó máa nmú ohùn ti Ẹ̀mí wá sí ọkàn wa bíi iná ní àwọn ìgbà míràn.
Ní ìgbàmíràn, àwọn ìtẹ̀mọ́ra máa njẹ́ láti inú ohun tí a nkà ní pàtó, àti pé ní àwọn ìgbà míràn, ohun tí a nṣe àròjinlẹ̀ lé lórí nmú ìdáhùn wá fún àníyàn tó yàtọ̀ gidi. Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ Alàgbà Robert D. Hales pé: “Nígbàtí a bá fẹ́ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, à ngbàdúrà. Àti nígbàtí a bá fẹ́ kí Òun bá wa sọ̀rọ̀, a nwá inú àwọn ìwé mímọ́.”
Bí ariwo ati ìdíwọ́ ti ayé ti nlọ kiri ní àyíká wa, Olúwa ti darí wòlíì Rẹ̀ láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì púpọ̀ àti púpọ̀ síi. Nínú àwọn ilé mímọ́ ti Olúwa wọ̀nyí, bí a ti nfi àwọn ìpèníjà wa sílẹ̀ ní òde ṣùgbọ́n tí a nwọlé pẹ̀lú àwọn àdúrà àti àwọn àníyàn wa, wọ́n nkọ́ wa ni àwọn òtítọ́ ti ayérayé.
Ní ọdún kan sẹ́hìn, Ààrẹ Nelson fún wa ní ìlérí tó lápẹrẹ yìí pé: “Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, níhin ni ìlérí mi. Kò sí ohun tí yíò ràn yín lọ́wọ́ ju láti dì ọ̀pá irin mú ṣinṣin ju jíjọ́sìn nínú tẹ́mpìlì déédé bí àwọn ipò yín bá ti gbà. Kò sí ohun tí yíò dáàbò bò yín jù bí ẹ bá ti nkojú àwọn ìkùùku òkùnkùn ayé. Kò sí ohun tí yíò gbé ẹ̀rí yín ga nípa Olúwa Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ tàbí ràn yín lọ́wọ́ láti ní òye ètò títóbi jùlọ Ọlọ́run síi. Kò sí ohun tí yíò tu ẹ̀mí yín lára síi ní àwọn ìgbà ìrora. Kò sí ohun tí yíò ṣí àwọn ọ̀run sílẹ̀ síi. Kò sí!”
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kọ̀ọ̀kan nmú àfikún ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ìbùkún wá. Nínú Oṣù Kẹrin tó nbọ̀, lẹ́ẹ̀kansíi, a ó pàdé nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò láti gbọ́ ohùn Olúwa. A nwá sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò lẹ́hìn tí a ti gbàdúrà tí a sì ti múrasílẹ̀. Fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, àwọn àníyàn kánkán àti àwọn ìbéèrè ìtara a máa wà. A nwá láti ṣe ìsọdọ̀tun ìgbàgbọ́ wa nínu Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, kí a sì fi okun fùn agbára wa lati kojú àdánwò. A wá láti jẹ́ kíkọ́ láti òkè ọrun wá. Mo ṣe ìlérí fún yín pé bí ẹ ti nmúrasílẹ̀ tí ẹ sì nwá pẹ̀lú àdúrà sí àwọn abala ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, ẹ ó ní ìmọ̀lára àwọn ìdáhùn sí àwọn àníyàn yín, ẹ ó sì mọ̀ pé “ọwọ́ ti ọ̀run” wà lórí yín.
Ẹ ní ìgbàgbọ́ pé Baba yín Ọ̀run nbá yín sọ̀rọ̀. Ó nṣeé! Ẹ jẹ́kí ìgbàgbọ́ yín nínú Òun àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ó ràn yín lọ́wọ́ pín ìkelè níyà kí ẹ sì gba ohùn Baba yín. Mo jẹ́rìí pé Ó wà níbẹ̀ Ó sì fẹ́ràn yín ju bí àwọn ọ̀rọ̀ ti lè sọ lọ.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹta 2025. Yoruba. 19605 779