“Ìròhìn Rere ti Ìfẹ́ àti Ayọ̀,” Làìhónà, Oṣù Kínní 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kínní 2025
Ìròhìn Rere ti Ìfẹ́ àti Ayọ̀
Àwọn ìbùkún Ìmúpadàbọ̀sípò yẹ kí ó mú inú wa dùn kí wọn sì kún wa pẹ̀lú ìmoore fún ìfẹ́ nlá Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ ìrètí àti àláfíà wa sí gbogbo ènìyàn ní pé Jésù Krístì wà láàyè àti pé ó ti mú ìhìnrere àti Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí.
“Àwọn ohun wọ̀nyí ti jẹ́ ológo àìlèjúwe tó sí ẹ̀dá ènìyàn!” ni Ààrẹ Joseph Smith kéde. “Ní tòótọ́ a lè yẹ̀ wọ́n wò bí ìròhìn ayọ̀ nlá sí gbogbo ènìyàn; àti ìròhìn, bákannáà, tí ó yẹ láti kún ayé kí ó sì fi ìdùnú sí ọkàn olúkúluku nígbàtí ó bá dún ní etí rẹ̀.”
Fún àwọn sẹ́ntúrì tó tẹ̀lé iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà lorí ilẹ̀ ayé, àwọn ọmọ Ọlọ́run wá A wọ́n sì pòngbẹ fún ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ síi. Nísisìyí ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere Jésù Krístì àti Ìmúpadàbọ̀sìpò tó nlọ lọ́wọ́ tẹ̀síwájú láti bùkún gbogbo ènìyàn àti láti múra ayé sílẹ̀ fún ọjọ́ náà nígbàtí Jésù Krístì yíò padà wá láti “ṣàkóso bí Ọba àwọn Ọba àti láti jọba bí Olúwa àwọn Olúwa.” Èyí ni ìfihàn ìjìnlẹ̀ ti ìfẹ́ àìlópin ti Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa. Mo láyọ̀ pé mo lè lo ayé mi ní kíkéde àwọn òtítọ́ wọ̀nyí sí gbogbo ayé.
Àwọn Aláìdàbí àti Olókìkí
Ọjọ́ titun dé fún ẹbí ẹ̀dá nínú igbó-ṣúúrú ti àwọn igi, níbití Ọlọ́run Baba àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ti farahàn tí wọ́n sì bá Joseph Smith sọ̀rọ̀ ní ìdáhùn sí àdúra Joseph kékeré nípa ìjọ èyí tí òun níláti darapọ̀ mọ́ (wo ìtàn—Joseph Smith 1:14–20). Jésù Krístì wí fún Joseph láti máṣe darapọ̀ mọ́ eyikeyi ìjọ. Ó ṣèlérí pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere Rẹ̀ ni a ó fihàn sí Joseph ní ọjọ́ iwàjú.
Sí ọ̀pọ̀lọpọ̀, Joseph dàbí ẹnití kò ṣeéṣe jùlọ láti jẹ́ pípè sí irú iṣẹ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀, wọ́n sì tọ́ láti rò bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ ẹnití kò kàwé àti ọmọdékùnrin aláìkàyẹ láti oko kékeré kan ní ìlú kan tó farasin. Gẹ́gẹ́bí àwọn kan ti sọ nípa Olùgbàlà ní ọjọ́ Rẹ̀, “Ṣé ohun rere kankan lè jáde wá ní Násárẹ́tì?” (Jòhánnù 1:46), ó ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu pé ohun rere lè wá láti ọ̀dọ̀ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tí kò kẹkọ ní Palmyra, New York. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Joseph—bí ó ti lè dàbí àìṣeéṣe tó—Baba Ọ̀run àti Olúwa Jésù Krístì yíò mú ohun tó lápẹrẹ nítòótọ́ wá sí ìmúṣẹ. Èyí níláti mú ìrètí wá fún wa pé nínú ọ̀nà kékeré àti ìrẹ̀lẹ̀ wa, àwa bákannáà lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Olúwa.ní àwọn ọ̀nà tó nítumọ̀.
Ní àkokò, Olúwa képe Joseph “ó sì ba sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, ó sì fun ní àwọn òfin” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:17). Joseph gba àwọn ìfihàn iyebíye àti ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó mú ìmọ́lẹ̀ titun wá sí òye wa nípa ètò ìfẹ́ni Baba Ọ̀run àti ìfẹ́ ìràpadà Jésù Krístì àti agbára ìrúbọ̀ ètùtù Rẹ̀. Pẹ̀lú ìyanu, àwọn ìròhìn ayọ̀ wọ̀nyí wá ní àkokò kan rẹ́gí nígbàtí ìmúdàgbà pàtàkì nínú ìkónilọ, ìbárasọ̀rọ̀, àti àwọn agbègbè míràn yíò fi àyè gba ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run láti tàn jáde láti bùkún púpọ̀ àti púpọ̀ síi ninu àwọn ọmọ Rẹ̀.
Ángẹ́lì Mórónì Ngbé àwọn Àwo Wúrà fún Joseph Smith, láti ọwọ́ C. C. A. Christensen
Ẹ̀rí Alágbára ti Ìfẹ́ Ọlọ́run
Ìfarahàn ángẹ́lì Mórónì sí Joseph Smith ṣe pàtàkì sí Ìmúpadàbọ̀sípò àti ẹ̀rí alágbára ti ìfẹ́ Ọlọ́run. Mórónì wí fún Joseph nípa àkọsílẹ̀ kan, tí a kọ sórí àwo wúrà, tí a rì mọ́lẹ̀ sítòsí (wo Ìwé-ìtàn—Joseph Smith 1:33–34). Nígbẹ̀hìn, Joseph ni a ó fún ní “agbára láti òkè wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:8) láti ṣe ìyírọ̀padà àkọsílẹ̀ náà sí ohun tí yíò di Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyí tí ó dúró lẹgbẹ Bíbélì tí ó sì jẹ́ ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì.
Nínú gbogbo Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a kà nípa àwọn ènìyàn tí, ní ọgọgọrun ọdún ṣaájú Krístì, wọ́n mọ̀ wọ́n sì sọtẹ́lẹ̀ nípa bíbọ̀ Rẹ̀ wọ́n sì nfojúsọ́nà fún un. Bákannáà a rí àkọsílẹ̀ àrà-ọ̀tọ̀ ti ìfarahàn araẹni ti àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà tó jínde ní àárín àwọn ará Néfì, ní àkókò èyí tí Ó pè gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ kí wọ́n sì fọwọ́kan àmì ní ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀ àti àpá ìṣó ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Rẹ̀ (wo 3 Néfì 11:14–15). Ó wo aláìsàn, arọ, afójú sàn—“gbogbo àwọn tí a pọ́n lójú ní èyíkéyí ọ̀nà”—àti lẹ́hìnnáà Ó bùkún-fún àwọn ọmọ kékeré Ó sì gbàdúrà fún wọn (wo 3 Néfì 17:7–9, 21). A kẹkọ púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ nípa ìfẹ́ àti àánú Olùgbàlà láti inú àkọsílẹ̀ mímọ́ yi.
Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀ri pé “Jésù ni Krístì.” Àwọn ìdánilójú nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì fi léraléra rán wa létí pé Baba wa ní Ọ̀run àti Olùgbàlà wa fẹ́ràn wa kọjá ohunkóhun tí a lè rò.
Àwọn ìbùkún Oyè-àlùfáà àti Ìjọ
Ìmúpadàbọ̀sípò náà ntẹ̀síwájú pẹ̀lú ìfarahàn àwọn ìránṣẹ́ ti ọ̀run míràn sí Joseph Smith. “Jòhánnù onítẹ̀bọmi tí ó jíìnde mú àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi nípa rírìbọmi padàbọ̀sípò fún ìmúkúrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀. Mẹ́ta nínú àwọn Àpóstélì Méjìlá àkọ́kọ́—Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù—ṣe ìmúpadàbọ̀sípò jíjẹ́ àpóstélì àti àwọn kọ́kọ́rọ́ àṣẹ oyè-àlùfáà. Àwọn míràn wá bákannáà, nínú èyítí Èlíjàh wà, ẹnití ó mú àṣẹ padàbọ̀sípò láti so áwọn ẹbí papọ̀ títíláé nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ayérayé tí ó rékọjá ikú.”
Ní Ọjọ́ Kẹfà Oṣù Kẹ́rin, 1830, Jésù Krístì nípasẹ̀ Wòlíì Joseph gbé ìjọ kan kalẹ̀ tí a ṣe àwòṣe rẹ̀ bíi ti ìjọ tí Ó gbékalẹ̀ ní àwọn ìgbà Májẹ̀mú Titun (wo Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:6), ní pípé pẹ̀lú “ìpìlẹ̀ àwọn àpóstélì àti wòlíì, Jésù Krístì fúnrarẹ̀ ní jíjẹ́ òkúta pàtàkì igun ilé” (Ephesians 2:20). Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nmú àwọn ìbùkún agbára oyè-àlùfáà tí a mupadàbọ̀sípò wà ní àrọ́wọ́tó sí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run tí wọ́n nmúra arawọn sílẹ̀ láti gbà á.
Bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ wa, a lè rí ayọ̀ nínú ìrònúpìwàdà ojojúmọ́ bí a ti nyípadà sí Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà wa. Sí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí pé wọn kò kúnjú-ìwọ̀n tàbí jẹ́ ti ara kan: gbogbo wọn ni a pè láti wá sọ́dọ́ Krístì àti Ìjọ Rẹ̀. Ìjọ náà kìí ṣe ilé-ìdáwà fún àwọn ẹni pípé ṣùgbọ́n ó jẹ́ ilé-ìwòsàn fún àwọn aláìsàn. Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá rán wa létí pé “à nwá sí ilé ìjọsìn kìí ṣe láti fi àwọn wàhálà wa pamọ́ ṣùgbọ́n láti wò wọ́n sàn.”
Ní ilé ìjọsìn à nrí ayọ̀ nínú àwọn ànfàní láti yí ara wa padà síta, sin àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú ìfẹ́, kí a sì pín àwọn ìrírí ti araẹni wa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ oore ti Krístì. A lè jẹ́ “kíkà mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ Krístì” kí a sì “di rírántí àti bíbọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” (Moroni 6:4). Ó ti jẹ́ ìbùkún títóbi-jùlọ kan tó!”
Èrèdí kan fún Ayọ̀ Nlá
Wòlíì Joseph Smith kéde nígbàkan rí pé, “Nísisìyí, kíni à ngbọ́ nínú ìhìnrere èyí tí a ti gbà? Ohùn ìdùnnú kan! Ohùn àánú láti ọ̀run; ohùn òtítọ́ láti inú ilẹ̀-ayé; ìròhìn ayọ̀ fún àwọn okú; ohùn ti ìdùnnú kan fún àwọn alààyè àti òkú; ìròhìn ayọ̀ ti ìdùnnú nlá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:19).
Àwọn ìròhìn ayọ̀ wọ̀nyí ti wá nítorí Baba Ọ̀run àti àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, fẹ́ràn wa wọ́n sì ní ìfẹ́-inú—ju ohunkóhun lọ—láti kí wá káàbọ̀ padà sí ọ̀dọ̀ Wọn, kí àwa lè ní irú ìgbésí-ayé tí Wọ́n ngbé títíláé. Ìmúpadàbọ̀sípò náà nfihàn pé Wọ́n ti ṣe ohun gbogbo tó ṣe dandan láti mú èyí jẹ́ ìṣeéṣe ológo fún gbogbo wa. Nínú ìrìnàjò ayérayé wa, a ó ní ìrírí àwọn àdánwò àti ìṣòrò, ṣùgbọ́n “[àwa] wà, kí [a] lè ní ayọ̀” (2 Néfì 2:25) ní ayé yí àti èyí tó nbọ̀. Wòlíì Joseph mọ èyí dáradára ju ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Joseph dojúkọ àtàkò àti ìnúnibíni léraléra, síbẹ̀ ó pa “ìṣẹ̀dá ọlọ́yàyà àbínibí rẹ̀ mọ́” (Ìwé-ìtàn—Joseph Smith 1:28). Ó dúró ní jíjẹ́ aláyọ̀, alágbára, àti onísùúrù, ó sì ṣe àṣeyọrí iṣẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tí a ti fun láti ṣe. Mo gbé oríyìn fún gbogbo àwọn Ènìyàn Mímọ́ ìṣaájú tí wọ́n gbàgbọ́, ṣe àtìlẹhìn, tí wọ́n sì tẹ̀lé Wòlíì Joseph Smith tí wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ sí gbígbé Ìjọ náà ró. A jẹ wọ́n ní irú gbèsè ìmoore àti ìbu-ọlá fún bẹ́ẹ̀.
Kò dán mọ́rán ní àwọn ọjọ́ ìṣaájú ti Ìjọ, ó sì lè ṣe àìdán-mọ́rán ní òní. Ṣùgbọ́n Ìmúpadàbọ̀sípò nlọ lọ́wọ́. Pẹ̀lú Jésù Krístì ní orí Ìjọ yí, àwọn wòlíì alààyè yíò tẹ̀síwájú láti tọ́ wa sọ́nà. Àwọn ilé Olúwa yíò tẹ̀síwájú láti máa jẹ́ kíkọ́, kí àwọn ìbùkún májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run lè so wá pọ̀ mọ́ Ọ àti sí àwọn àyànfẹ́ wa ní ẹ̀gbẹ́ méjèjì ìkelè (wo Matteu 16:19). Ìfẹ́ Ọlọ́run àti Jésù Krístì yíò nà sí gbogbo ayé bí a ti ntẹ̀lé àṣẹ Olùgbàlà láti bọ́ àwọn àgùntàn Rẹ̀ kí a sì pín ìhìnrere Rẹ̀. A ó jẹri àwọn òtítọ́ ti Imúpadàbọ̀sípò ní lílọ síwájú ní àwọn ọ̀nà àti sí àwọn ibi tí ìbá ti ṣòro láti lérò ní ọjọ́ Joseph.
A lè rí okun àti ayọ̀ nlá—bí Wòlíì Joseph ti ṣe—bí a ti nrọ̀mọ́ tí a sì ngbé igbé ayé àwọn òtítọ́ iyebíye wọ̀nyí. Ìpè tí Joseph ṣe sí àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní ọjọ́ rẹ̀ ṣì ntẹ̀síwájú pẹ̀lú wa ní òní: “Njẹ́ a kì yíò tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ títóbi tóbẹ́ẹ̀ kan bí? Ẹ tẹ̀síwájú kì ẹ má sì ṣe rẹ̀hìn. Ìgboyà, … àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun naa! Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ó yọ̀, kí ẹ sì dunnú gidigidi” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 128:22).
Njẹ́ kí ìròhìn ayọ̀ ti ìfẹ́ àti ti ìdùnnú tí Ìmúpadàbọ̀sípò nmú wá kó bùkún kí ó sì tọ́ ìgbésí-ayé wa sọ́nà—nísisìyí àti nígbà gbogbo.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kínní 2025. Yoruba. 19600 779