Àlẹ̀mọ́
Baba yín Ọ̀run npè yín láti gba àwọn ìlànà mímọ́. Àwọn ìlànà wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú—tí ẹ ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, Òun sì ṣe àwọn ìlérí pẹ̀lú yín. Ẹ̀ ndá a`wọn májẹ̀mú wọ̀nyí, fún àpẹrẹ, nígbàtí ẹ bá ṣe ìrìbọmi àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀, nígbàtí ẹ bá gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, àti nígbàtí ẹ bá ṣe èdidì fún àkokò àti gbogbo àìlópin nínú ilé Olúwa. Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ yíò mú ayọ̀ àti ìdùnnú wá fún yín yíò sì fi ààyè gbà yín sí agbára Ọlọ́run láti ràn yín lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, níbití ẹ ti lè gbádùn ìyè ayérayé pẹ̀lú Rẹ̀.
Láti kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa ohun tí ẹṣe ìlérí sí Ọlọ́run nígbàtí ẹ̀ ndá àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí—àti ohun tí Ó ṣe ìlérí fún yín—wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 3.5, Ibi-ìkàwé Ìhìnrere.
Ronújinlẹ̀ àwọn ìbèèrè ìsàlẹ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn ìbèèrè tí ẹ̀ nbèèrè nígbàtí a bá fi ọ̀rọ̀ wá yín lẹ́nuwò láti gba ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n ẹ kò nílò láti dúró fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Ẹ ṣe àyẹ̀wò-araẹni ti ẹ̀mí ara yín nígbàkugbà tí ẹ bá fẹ́.
Àkórí àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, Àkórí Iyejú Oyè Àlùfáà Áárónì, àti pé àwọn Òfin Mẹwa báknanáà lè ṣèrànwọ́ àwọn ohun èlò nínú àyẹ̀wò-araẹni yín.
Àwọn Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì fún àwọn Ọ̀dọ́
-
Ṣe ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú àti ẹ̀rí kan nípa Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé; Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì; àti Ẹ̀mí Mímọ́?
-
Ṣé ẹ ní ẹ̀rí Ètùtù Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà yín?
-
Ṣe ẹ ní ẹ̀rí kan nípa Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì?
-
Ṣe ẹ ṣe ìmúdúró Ààrẹ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti bí ẹnìkanṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tí a fún láṣẹ láti lo gbogbo kọ́kọ́rọ́ oyèàlùfáà? Ṣe o ṣe ìmúdúró àwọn ọmọ Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn? Ṣe o ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò àti àwọn olórí ìbílẹ̀ Ìjọ?
-
Olúwa ti wípé gbogbo àwọn ohun ni a níláti “ṣe nínú ìwẹ̀nùmọ́” níwájú Rẹ̀ (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42:41). Ṣé ò ntiraka fún ìwà mímọ́ nínú àwọn èrò àti ìhùwàsí rẹ? Ṣé ò ngbọ́ran sí àṣẹ ìmáradúró?
-
Ṣé ẹ̀ ntẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Ìjọ Jésù Krístì nínú ìwà ìkọ̀kọ̀ àti gbangba yín pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹbí yín àti àwọn míràn?
-
Ṣé ẹ nṣàtìlẹhìn tàbí gbé àwọn ìkọ́ni, ìṣe, tàbí ẹ̀kọ́ tó lòdì sí àwọn ti Ìjọ Jésù Krísti ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn kọ̀ọ̀kan wọnnì ga.
-
Ṣé ẹ̀ ntiraka láti pa Ọjọ́-ìsinmi mọ́ ní mímọ́, ní ilé àti ìjọ; ṣé ẹ̀ nlọ sí àwọn ìpàdé yín; tí ẹ̀ nmúrasílẹ̀ fún àti láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ; tí ẹ sì ngbé ìgbé ayé yín ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ àti òfin ìhìnrere?
-
Ṣé ẹ̀ ntiraka láti jẹ́ olotitọ nínú ohun gbogbo tí ẹ̀ nṣe?
-
Njẹ́ ẹ jẹ́ olùsan idamẹwa-kíkún?
-
Ṣé ẹ ní ìmọ̀ tí ẹ sì ngbọ́ran sí Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n?
-
Njẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ líle kan wà nínú ayé yín tí ẹ nílò láti ṣàtúnṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ oyèàlùfáà bí apákan ìrònúpìwàdà yín?
-
Ṣé ẹ ká ara yín yẹ láti wọnú ilé Olúwa àti láti kópa nínú àwọn ìlànà tẹ́mpìlì?
Àkórí Àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin
Mo jẹ́ àyànfẹ́ ọmọbìnrin ti àwọn obí ọrun, pẹ̀lú ìwà ẹ̀dá àtọ̀runwá àti àyànmọ ayérayé .
Gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì, mo ngbìyànjú láti dàbí Rẹ̀. Mo nwá láti ṣe ìṣe lórí ìfihàn araẹni àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn míràn ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀.
Èmi yíò dúró bí ẹlẹri kan ti Ọlọ́run ni gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo.
Bí mo ṣe ngbìyànjú làti ṣe déédé fún ìgbéga,mo nṣìkẹ́ ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà àti láti wá láti dára si ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́, èmi yíò fún ilé àti ẹbí mi ní okun, ṣe àti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, àti láti gba àwọn ètò àti àwọn ìbùkún ti tẹ́mpìlì mímọ́.
Àkórí Iyejú Oyè-àlùfáà Áárónì.
Èmi jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ Ọlọ́run, àti pé Ó ní iṣẹ́ kan fún mi láti ṣe.
Pẹ̀lú gbogbo ọkàn, okun, inú, àti agbára, èmi yíò ní ìfẹ́ Ọlọ́run, pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́, àti láti lo oyè àlùfáà Rẹ̀ láti sin àwọn ẹlòmíràn, bíbẹ̀rẹ̀ nínú ilé ti ara mi.
Bí mo ṣe nlàkàkà láti sìn, lo ìgbàgbọ́, ronúpìwàdà, kí nsì dára síi ní ojoojúmọ́, èmi ó yege láti gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì àti ayọ̀ pípẹ́-títí ti ìhìnrere.
Èmi yíò múrasílẹ̀ láti di ìránṣẹ́ ìhìnrere aláápọn kan, ọkọ olóòtítọ́, àti bab olùfẹ́ni nípa jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn òtítọ́ ti Jésù Krístì.
Ẹ le ṣèrànwọ́ láti múra ayé sílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Olùgbàlà nípa pípe gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ Krístì kí wọn ó sì gba àwọn ìbùkún ti Ètùtù Rẹ̀.
Àwọn Òfin Mẹwa
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní Ọlọ́run míràn pẹ̀lú mi.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya ère fún ara rẹ.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ lásán.
-
Rántí ọjọ́ ìsinmi, láti yà á sí mímọ́.
-
Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ̀rí èké sí ẹnìkéjì rẹ.
-
Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò.
Wo Ẹksódù 20:3–17.