7.
Àwọn ìlànà àti májẹ̀mú nfún wa ní ààyè sí agbára ti ọ̀run.
Baba yín Ọ̀run ní ìtara láti kọ́ni àti láti bùkún yín. Ọ̀nà kan tí Ó fi nṣe èyí ni nípasẹ̀ àwọn ìlànà bíi ìrìbọmi, ífẹsẹ̀múlẹ̀, àti oúnjẹ Olúwa. Nípasẹ̀ àwọn ìlànà bíi ti ìwọ̀nyí, à ndá májẹ̀mú, tàbí ṣe ìlérí, pẹ̀lú Ọlọ́run. Pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nmú agbára Ọlọ́run pọ̀si nínú ayé yín ó sìnmúra yín sílẹ̀ fún ìyè ayérayé. Èyí ni ìdí tí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú fi jẹ́ iyebíye sí wa—nítorí wọ́n nfi okun fún ìsopọ̀ wa sí Baba wa Ọ̀run àti Olùgbàlà wa wọ́n sì nràn wá lọ́wọ́ láti dàbíi Tiwọn.
Òtítọ́ Ayérayé
Àwọn ìlànà nnawọ́ yín sí Jésù Krístì. Ìlànà kan jẹ́ ayẹyẹ mímọ́ pẹ̀lú àwọn ìtumọ̀ tí ó ní àmì tí ó kọ́ni nípa Jésù Krístì. Oúnjẹ Olúwa, fún àpẹrẹ, kìí ṣe búrẹ́dì àti omi lásán. Ó rán wa létí nípa Olùgbàlà.
Àwọn májẹ̀mú ni àmì ìfẹ́ Ọlọ́run, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìrètí. Wọ́n nmú ìbáṣepọ̀ yín pẹ̀lú Ọlọ́run lọ sí ipele jíjinlẹ̀ si. Wọ́n nmú kí májẹ̀mú fihàn pé ẹ ní ìfẹ́ Ọlọ́run ẹ sì ní ìfarajì sí I. Ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé E, Òun sì lè gbẹ́kẹ̀lé yín. Pẹ̀lú ìfarajì jíjinlẹ̀ náà ni ààyè títóbijù nwá sí agbára Rẹ̀ ó sì nṣèrànwọ́ bí ẹ ti npa àwọn májẹ̀mú yín mọ́.
Ẹ̀ ndá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nígbàtí ẹ ṣe ìrìbọmi àti nígbàtí ẹ bá ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa. Nígbàtí ẹ bá ṣe ìrìbọmi, ẹ lè ṣ̣e ìlérí láti gbé orúkọ Jésù Krístì lé orí ara yín, sìn Ín, àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ nínú ayé yín. Ní ìgbà oúnjẹ Olúwa, bákannáà ẹ ṣe ìlérí láti rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlérí yín. Bí ẹ ti nfẹ́ láti pa wọ́n mọ́, àwọn ìlérí Ọlọ́runláti fún yín ní Ẹ̀mí Mímọ́ bí ojúgbà lemọ́lemọ́.
Àwọn ìfipè
Ẹ ṣìkẹ́ oúnjẹ Olúwa bíi ẹ̀bùn mímọ́. Ẹ fi ìfarajì yín hàn sí Jésù Krístì nípa mímúrasílẹ̀ fún ìrírí mímọ́ ní ìgbà oúnjẹ Olúwa. Ẹ ronújinlẹ̀ nípa ohun tí ẹ lè ṣe láti mú kí ìlànà yí jẹ́ ìfàmìsí ẹ̀mí ti ọ̀sẹ̀ yín.
Ẹ wá Olùgbàlà nínú àwọn ìlànà. Nígbàtí ẹ bá wò tàbí kópa nínú ìlànà kan, bèèrè lọ́wọ́ ara yín, “Kíni èmi ó kọ́ látinú èyí nípa Jésù Krístì?” tàbí “Báwo ni ó ṣe nmú mi súnmọ́ Ọ si?” Ẹ kíyèsí ohun tí Ẹ̀mí nkọ́ ọ yín.
Ẹ jẹ́ kí àwọn májẹ̀mú yín tọ́ àwọn ìṣe yín sọ́nà. Nígbàtí ẹ bá ní yíyàn kan láti ṣe, ẹ rántí ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ olóòtítọ́ sí I. Ẹ bí ara yín léèrè: Njẹ́ èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn májẹ̀mú mi? Fún àpẹrẹ, ṣe mo ní ìfẹ́ tí mò sì nṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, tí wọ́n nílò ìtùnú, tí wọ́n sì dúró bí ẹlẹri Krístì—níbigbogbo àti nígbàgbogbo?
Àwọn ìlérí ìbùkún
Ẹ lè ní agbára láti borí àdánwò, ẹ̀ṣẹ̀, àti àwọn àdánwo ayé. Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ nfún wa ní ààyè sí agbára Ọlọ́run. Pẹ̀lú agbára náà, ẹ lè kojú ohunkohun pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé. Jésù Krístì ni okun yín!
Ẹ lè di mímọ́ kí ẹ sì dáríjì. Ara ìlérí Ọlọ́run sí yín fún pípa májẹ̀mú ti ìrìbọmi yín mọ́ ni ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín. Èyí túmọ̀ sí pé bí ẹ ṣe nronúpìwàdà tí ẹ sì npa àwọn ìlérí yín mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, Òun yíò dáríjì yín kí ó sì mú yín dára si.
Ẹ lè ní Ẹmí Mímọ́ pẹ̀lú yín nígbàgbogbo. Ìlérí míràn sopọ̀ mọ́ ìrìbọmi àti oúnjẹ Olúwa ni ojúgba lemọ́lemọ́ ti Ẹ̀mí Rẹ̀ àti ṣíṣé iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì. Ẹ kò ní láti dánìkan kojú àwọn ìpènijà yín. Ọlọ́run ko pa àwọn ọmọ májẹ̀mú Rẹ̀ tì láé—ẹ lè gbẹ́kẹ̀lé èyí.
Ẹ lè ní àtìlẹhìn àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ti ìletò àwọn ènìyàn májẹ̀mú nínú Ìjọ Olùgbàlà. Ẹ gbéga kí ẹ sì gba ara yín níyànjú. Ẹ ó ṣọ̀fọ̀ papọ̀ ẹ ó sì yayọ̀ papọ̀. Ẹ ó gbé ẹru ara yín. Ẹbí yín, bíṣọ́ọ̀pù, àwọn aṣaájú, àti àwọn ọmọ Ìjọ míràn wà ní ìhín láti ràn yín lọ́wọ́, ẹ̀yin náà sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
Àwọn Ìbèèrè àti Ìdáhùn
Njẹ́ èmi lè jẹ́ ọmọlẹ́hìn rere ti Jésù Krístì láìsí àwọn ìlànààti àwọn májẹ̀mú? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn rere wà tí wọ́n ntẹ̀lé Jésù Krístì lódodo, àní bíótilẹ̀jẹ́ pé wọn kò ṣe ìrìbọmi rí tàbí ti lọ sí tẹ́mpìlì. Bákannáà, Baba Ọ̀run nfẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ gba àwọn ìlànà Rẹ̀ kí wọ́n sì dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ kí wọ́n lè ní ààyè púpọ̀jù sí ìrànlọ́wọ́, àánú, àti okun Rẹ̀. Èyí ni ọ̀kan lára kókó àwọn èrèdí tí Jésù Krístì fi mú Ìjọ Rẹ̀ padàbọ̀sípò! Gbogboọmọ Ọlọ́run yíò ní ànfàní—nínú ayé yí tàbí tó tẹ̀le—láti tẹ́wọ́gba àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú bèèrè fún ìyè ayérayé.
Èmi kò fi ìgbàgbogbo jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn májẹ̀mú mi. Ṣé ìrètí wà fún mi? Bẹ́ẹ̀ni! Ìhìnrere Jésù Krístì ni ìhìnrere ìrètí àti àwọn ìbẹ̀rẹ̀ titun. Èyí ni ìdí tí àwa fi njẹ oúnjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Baba Ọ̀run mọ̀ pé a ó ṣe àwọn àṣìṣe a ó sì nílò ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Olùgbàlà fi ayé Rẹ̀ fún yín láti fún yín ní ọ̀nà padà. Bí ẹ ti nlo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì tí ẹsì nronúpìwàdà, ẹ lè ṣe àtúngbà ààyè sí agbára Ọlọ́run.
Wo 1 àwọn ará Kọ́ríntì 11:23–26 (jíjẹ oúnjẹ Olúwa fihàn pé a gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì a`ti Ètùtù Rẹ̀); Mòsíàh 18:10, 13 (májẹ̀mú ìrìbọmi); Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 13 (Oyè Àlùfáà Áárónì wà pẹ̀lu àwọn kọ́kọ́rọ́ ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi, àti àwọn ángẹ́lì oníṣẹ́ ìránṣẹ́); 20:37 (àwọn ìnílò fún ìrìbọmi); 20:77, 79 (àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa).
Ìbèèrè Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì
-
Ṣé ẹ̀ ntiraka láti pa Ọjọ́-ìsinmi mọ́ ní mímọ́, ní ilé àti ìjọ; ṣé ẹ̀ nlọ sí àwọn ìpàdé yín; tí ẹ̀ nmúrasílẹ̀ fún àti láti ṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yíyẹ; tí ẹ sì ngbé ìgbé ayé yín ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣẹ àti òfin ìhìnrere?