“Bíbùkún Gbogbo Ẹbí Ilẹ̀ Ayé,” Làìhónà, Oṣu Kẹ́ta. 2026.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹta 2026
Bíbùkún Gbogbo Ẹbí Ilẹ̀ Ayé
Bí a bá tẹ̀lé tí a sì pín ètò Baba wa Ọ̀run fún àwọn ẹbí, Òun yíò wà pẹ̀lú wa, ṣe ìmúdúró wa, yíò sì dà wá pọ̀ nínú ìrìnàjò wa padàsí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Àlá ti Jákọ́bù ní Bẹ́tẹ́lì, láti ọwọ́ J. Ken Spencer
Láìpẹ́, Arábìnrin Uchtdorf àti èmi lọ síbi ìrìbọmi ọ̀kan lára àwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ wa. Bí a ṣe nwo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìràn aláyọ̀ tí wọ́n nṣe àjọyọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yí, a ní ìmọ̀lára ìmoore ìjìnlẹ̀ sí Baba wa Ọ̀run fún ètò ìgbàlà Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀. A ní ọgbọ́n bí ẹbí àti àwọn májẹ̀mú mímọ́ ti jẹ́ pàtàkì sí I làti ìbẹ̀rẹ̀ gangan.
Jíjẹ́ pàtàkì náà ni a lè rí nínú àkọsílẹ̀ Májẹ̀mú Láéláé ti òtítọ́ Jákọ́bù, ẹnití ó lọ sí ìrìnàjò líle jíjìn láti wá ìyàwó, gbéyàwó nínú májẹ̀mú, kí ó sì gbé ẹbí kan kalẹ̀. Ní ọjọ́rọ̀ kan, Jákọ́bù dúró láti sinmi fún alẹ́ náà ṣùgbọ́n ó rí àwọn òkútà nìkan fún ìrọ̀rí rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ ti rẹ̀ ẹ́ gan nítorí ó ṣì gbìyànjú láti sùn lọ—ó sì lá àlà kan.
Pẹ̀lú àwọn ìlépa líle rẹ̀ nípa májẹ̀mú ìgbéyàwó àti ẹbí dájúdájú ní inú rẹ̀, Jákọ́bù rí “a gbé àkàsọ̀ kan dúró lórí ilẹ̀, orí rẹ̀ dé òkè ọ̀run: sì kíyèsíi àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run ngòkè, wọ́n sì nsọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀.
“Sì kíyèsíi, Olúwa dúró lókè rẹ̀, ó sì wípé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run Ábráhámù baba rẹ, àti Ọlọ́run Ísáákì” (Gẹ́nẹ́sísì 28:12–13).
Nígbànáà Olúwa ṣe àwọn ìlérí májẹ̀mú pàtàkì kan sí Jákọ́bù—àwọn ìlérí tí Ó ti ṣe bákannáà pẹ̀lú baba Jákọ́bù, Ísáákì, àti baba-baba rẹ̀, Ábráhámù, pẹ̀lú:
-
Àwọn ìlérí pé Jákọ́bù yíò di baba ti “ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn” (Gẹ́nẹ́sísì 28:3; bákannáà wo ẹsẹ 14).
-
Àwọn ìlérí ilẹ̀ fún àtẹ̀lé Jákọ́bù (wo Gẹ́nẹ́sísì 28:4, 13).
-
Àwọn ìlérí pé nípasẹ̀ Jákọ́bù àti “èso rẹ̀ ni a ó bùkún gbogbo ẹbí ayé” (Genesis 28:14; àfikún àtẹnumọ́).
Mímọ́ gidi ni ìrírí Jákọ́bù tí ó fi kéde: “Olúwa nbẹ ní ìhín yí nítòótọ́. … Èyí kìí ṣe ibi òmíràn bíkòṣe ilé Ọlọ́run, èyí sì ni ẹnuibodè ọ̀run” (Gẹ́nẹ́sísì 28:16–17). Nítorínáà, Jákọ́bù sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, èyítí ó túmọ̀sí “ilé Ọlọ́run” (Gẹ́nẹ́sísì 28:19, àkọsílẹ̀ ránpẹ́ ìsàlẹ̀ a).
Àwọn ìbùkún ilérí tí a fún Jákọ́bù nínú àlá bèèrè pé kí Jákọ́bù ṣe àfiwé gígùn nínú ayé lódodo. Gẹ́gẹ́bí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, kò le láti rí ìsopọ̀ ní àárín àlá Jákọ́bù, àwọn májẹ̀mú Olúwa, àti ilé Olúwa. Àwọn tẹ́mpìlì jẹ́ ọ̀pọ̀ bíiti àkàsọ̀ tí Jákọ́bù rí. Àwọn ìkọ́ni, àwọn ìlànà, àti àwọn májẹ̀mú ti ilé Olúwa sopọ̀ mọ́ ọ̀run àti ayé. Àwọn májẹ̀mú ni a lè fiwé láti yí lórí àkàsọ̀ kan tí ó nmú wa súnmọ́ Olúwa si. Àti pé, nípasẹ̀ iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí à nfúnni nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́, à nbùkún “gbogbo Ẹbí Ilẹ̀ Ayé—tó kọjá, lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ọjọ́ ọ̀là.
Irú Àwárí kan!”
Alàgbà Bruce C. Hafen, olùfẹ̀hìntì ọmọ Àádọ́rin kan, nígbàkanrí gba ipè fóònù láti ọ̀dọ̀ Olóòtú ìwé ìròhìn orílẹ̀-èdè kan. Olóòtú náà nfẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ìwé àìpẹ̀ tí ó ṣe ìwákiri àkọọ́lẹ̀ ìtàn ìgbàgbọ́ nípaọ̀run káàkiri onírúurú àwọn ẹ̀sìn.
“Àwọn olóòótú ri pé àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ ìtànká ẹbi fún ọ̀run—àti àwọn ẹbí ní ọ̀run,” Alàgbà Hafen kọ̀wé. Ṣùgbọ́n nígbàtí púpọ̀jùlọ àwọn ènìyàn ṣì gbàgbọ́ nínú ayé lẹ́hìn ikú, ìfẹ́ ayérayé, àti àtúndàpọ̀ ẹbí ọ̀run, “púpọ̀jùlọ àwọn ìjọ krìstẹ́nì nfi èsì díẹ̀ fúnni sí ẹbi inú yí”—pẹ̀lú àyọkúrò kan: Ì̀jọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.
Nínú Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Olùgbàlà, a ní àwọn tẹ́mpìlì mímọ́. A ní ìgbeyàwó ayérayé, pẹ̀lú àṣẹ èdìdi tí ó nbùkún kọjá ikú ti ara. A ní ìlérí ọjọ́ ọ̀la ayérayé pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ ní ọ̀dọ̀ Baba àti Ọmọ. Fífunni ní gbogbo èyí, àwọn olóòtú parí pé ìgbìrò àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nípa ọ̀run ni ó pé jùlọ—àti pé, èmi yíò fikun, dídunnú jùlọ.
“Irú àwárí kan!” Alàgbà Hafen ṣe àkíyèsí. “Púpọ̀jùlọ a`wọn ènìyàn ní òní nlọ́ra fún ẹbí ayérayé, àti [ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì] mú lílóra náà ṣẹ dáradára ju eyikeyi míràn ti àwọn èrò tí a mọ̀ [tàbí àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn]. Èmi ní ìfẹ́ pé kí gbogbo ayé lè gbọ́ tí àwọn ọmọ [wa] nkọrin ìròhìn rere: ‘Àwọn ẹbí lè wà papọ̀ títíláé.’”
Àwọn ẹbí kìí ṣe rírọnilọ́rùn ìṣètò àwùjọ lásán. Wọ́n jẹ́ a`wòṣe ayérayé ti ọ̀run. Wọ́n jẹ́ “àárín-gbùngbun sí ètò Ìṣẹ̀dá fún àyànmọ́ ayérayé ti àwọn ọmọ Rẹ̀.” Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Russell M. Nelson (1924–2025) ti kọ́ wa: “[Olúwa] dá ayé [nítorí] kí a lè gba ẹran ara kí asì di àwọn ẹbí. Ó gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀ láti gbé áwọn ẹbí ga. Ó npèsè àwọn tẹ́mpìlì nítorí kí àwọn ẹbí lè wà papọ̀ títíláé.”
Ṣùgbọ́n ìfẹ́ inú wa nínú àwọn ẹbí alágbára kìí ṣe nípa àwọn àyànmọ́ ayérayé nìkan. Ẹbí nṣe ojúṣe pàtàkì kan nínú ìdùnnú ayé ikú wa bákannáà. Baba wa Ọ̀run, ẹnití ó mọ ohun tí ó nmú ìdùnnú pípé wá nisisìyí àti ní ayérayé, rán a`wọn ọmọ Rẹ̀ wá sínú ẹbí—ní àìpé bí wọ́n ti lè jẹ́—àti láti pè wá láti gbéró àti láti ṣìkẹ́ àwọn ẹbí alágbára. Bẹ́ẹ̀ni, “àìlera, ikú, tàbí àwọn ipò míràn tí ó lè mú kí olúkúlùkù gbàmọ́ra.” Ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó lè rọ́pò àwọn ojúṣe pàtàkì yíyàn tọ̀run ti ọkọ àti aya, baba àti ìyá.
Ṣe ìwáàdí lórí “ìṣẹ̀dálẹ̀, dídè pọ̀, àwọn ẹbí òbí méjì” tẹ̀síwájú láti fihàn pé ẹbí jẹ́ àìlètúká ní dídá ààbò bo ìdè ìfẹ́ àti ìfẹ́ni.” Ó jẹ́ “kókó ọ̀sàbà fún ìmúdúró, títúnṣe dáadáa, àti ìfura ọ̀làjú àwùjọ olúkúlùkù.”
Aláápọn Olùgbèjà Ẹbí
Bẹ́ẹ̀ni, kò níláti yà wá lẹ́nu pé ohunkan ṣe pàtàkì sí ètò Ọlọ́run pé a ó kojú àtàkò. Sátánì kò tíì jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹbí rí, ìtiraka rẹ̀ sì ndi kánmọ́kánmọ́ síi “nítorí ó mọ̀ pé òun ní àkokò kúkurú” (Ìfihàn 12:12). Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ M. Russell Ballard (1928–2023), Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, wípé, “Sátánì mọ̀ pé ọ̀nà dídájú àti dídárájùlọ láti dàmú iṣẹ́ Olúwa ni láti mú ìdínkù bá dídára ẹbí àti jíjẹ́ mímọ́ ilé.”
Mímọ ohun tí a mọ̀ nípa ẹbí ayérayé Ọlọ́run, ètò Rẹ̀ fún àwọn ọmọ Rẹ̀, àti jíjẹ́ pàtàkì ayérayé àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí, a níláti wà ní àárín olùgbèjà aláápọn jùlọ ayé ti ẹbí.
Báwo ni a ó ti ṣe èyí?
Ààrẹ Dallin H. Oaks fúnni ní àmọ̀ràn yíl: “Ìkéde ẹbí … ni àtún-tẹnumọ́ Olúwa nípa àwọn o`títọ́ ìhìnrere tí a nílò láti ṣe ìmúdúró wa nípasẹ̀ àwọn ìpènijà sí ẹbí.”
Nínú ìgbé ayé araẹni wa, a lè ṣe “àwọn ohun kékeré àti jẹ́jẹ́” (Álmà 37:6) tí ó nfún ìbáṣepọ̀ ẹbí lókun. Èyí pẹ̀lú títẹ̀lẹ́ àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ti àwọn ẹbí àti ìgbeyàwó tó yege tí a lásílẹ̀ nínú ìkéde ẹbí: “ìgbàgbọ́, àdúrà, ìrònúpìwàdà, ìdáríjì, ọ̀wọ̀, ìfẹ́, àánú, iṣẹ́, àti àwọn ìṣe ìdárayá dídára.” Láìka ipò ẹbí wa lọ́wọ́lọ́wọ́ sí, a lè ṣe ìfihàn nípa àwọn ìṣe wa pé àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí jẹ́ pàtàkì ayérayé sí wa.
Gẹ́gẹ́bí “àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rere” nínú àwọn ìletò wa, a lè “mú àwọn òṣùwọ̀n wọnnì tí a yà láti ṣe ìmúdúró kí a sì fún ẹbí lókun.”
A jẹ́ àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa ọjọ́ ìkẹhìn. A jẹ́ ajogún àwọn ìlérí sí Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù—àwọn ìlérí tí ó ní ohun gbogbo láti ṣe pẹ̀lú àwọn ẹbí. Àwọn ìlérí wọnnì nwá pẹ̀lú ìpè mímọ́ láti bùkún “gbogbo àwọn ẹbí ayé.” Àti pé ọ̀nà pàtàkì kan tí a fi nṣe èyí ni nípa gbígbé, gbígbèjà, àti pípín òtítọ́ ayérayé pé “ẹbí ni a yàn nípasẹ̀ Ọlọ́run” àti pé “àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tí ó wà nínú àwọn tẹ́mpìlì mímọ́ nmu ṣeéṣe fún àwọn olúkúlùkù láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti fún àwọn ẹbí láti jẹ́ dídàpọ̀ ní ayérayé.”
“Mo wà pẹ̀lú rẹ”
Nígbàtí Arábìnrin Uchtdorf àti èmi nwo àwọn ọmọ ẹbí wa tí wọ́n ndá àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú olùfẹ́ni, Baba wa ayérayé Ọ̀run, ọkàn wa kún fún ayọ̀ àti ìmoore. A yọ̀ kìí ṣe nínú àwọn ọmọ wa àti àwọn ọmọ wọn nìkan ṣùgbọ́n nínú àwọn òbí wa àti àwọn òbí wọn. À nronújinlẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ìjìnlẹ̀ bí àwọn májẹ̀mú ìhìnrere ṣe ndà wá pọ̀ ní gbogbo àwọn ìran. Ó jẹ́ ìrírí kan tí kò dàbí rírí “a gbé àkàsọ̀ kan lé orí ilẹ, … orí rẹ̀ dé òkè [dé] òkè ọ̀run: sì kíyèsíi àwọn ángẹ́lì ngòkè wọ́n sì nsọ̀kalẹ̀” (Genesis 28:12).
Àwọn ìbùkún tí Olúwa ṣe ìlérí fún Jákọ́bù nínú àlá rẹ̀ nà sí gbogbo àwọn ọmọ májẹ̀mú Rẹ̀—pẹ̀lú ẹ̀yin àti èmi. Gẹ́gẹ́bí Olúwa ti ṣe fún Jákọ́bù, Òun yíò dá wa lóhùn “ní ọjọ́ ìpọ́njú [wa]” (Gẹ́nẹ́sísì 35:3) bí a bá yàn Án.
“Kíyèsíi,” Olúwa wípé, “Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi ó sì pa ọ́ mọ́ ní ibi gbogbo tí ìwọ nlọ, … nítorí èmi kì yíò kọ̀ ọ́ sílẹ̀” (Gẹ́nẹ́sísì 28:15).
Bíiti Jákọ́bù, gbogbo wa ní aginjù kan láti sọdá. Nígbàmíràn àwọn ìlérí ìbùkún dàbí ó jìnnà réré. Nígbàtí àwọn wàhálà líle koko tàbí àwọn ìpènijà bá wá, a lè ṣe àyẹ̀wò ìfẹ́ Olúwa. Àní a lè ní ìmọ̀lára pé Ọlọ́run ti pa wá tì. Pẹ̀lú àwọn ìtiraka dídárajùlọ wa bí ọmọẹ̀hìn kan, a lè ní ìmọ̀lára pé a kìí gba àwọn ìbùkún tí à nretí fún.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, ipa ọ̀nà májẹ̀mú ni ipa ọ̀nà aláyọ̀, bíótilẹ̀jẹ́pé ní àwọn àkokò tí ó lè gba àbàwọ́n pẹ̀lú omijé. Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára pé apákan ètò ìdùnnú kò di mímúṣẹ nínú ayé yín nísisìyí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Olúwa ní ìfẹ́ yín yíò sì bùkún yín ní àkokò Tirẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọgbọ́n Rẹ̀.
Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti àwọn ìlérí Rẹ̀ nmísí wa láti wo iwájú, kìí ṣe ẹ̀hìn. Nítorí Rẹ̀, ọjọ́ ọ̀la wa kò nílò láti wà ní ìgbèkùn nípa ohunkóhun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àtẹ̀hìnwá tàbí tí ó ndí ìwò wa lọ́wọ́lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo wa jẹ́, tàbí yíò di, pípalára ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Ṣùgbọ́n a gbàgbọ́ nínú Olùwòsàn Nlá. A gbẹ́kẹ̀lé E—púpọ̀ gidi, nítòótọ́, pé a rọ̀mọ́ àwọn ìlérí Rẹ̀, rọ wọ́n “ní kíkún,” àní nígbàtí wọ́n ṣì wà “ní ọ̀nà réré” (Hébérù 11:13).
“Kí a rán wa létí pé, ní ọ̀nà àti àkokò ti Olúwa, kò sí àwọn ìbùkún tí a yíò dìmú kúrò lọ́dọ̀ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Rẹ̀,” ni Ààrẹ Nelson wí. Olúwa yio dá olukúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan lẹ́jọ́ yío sì san àn fún wọn ní ìbámu sí ìfẹ́ inú àtọkànwá àti ohun ṣíṣe pẹ̀lú.”
Mo ṣe ìlérí pé bí a ṣe ntẹ̀lé tí a sì npín ètò Baba wa Ọ̀run fún àwọn ẹbí, Òun yíò wà pẹ̀lú wa, ṣe ìmúdúró wa, yíò sì dàpọ̀ mọ́ wa nínú ìrìnàjò. Òun kò ní dánìkan fi wá sílẹ̀ láéláé, nípàtàkì nígbàtí àwọn àdánwò bá wá sí ọ̀dọ̀ wa tàbí sí ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ wa. Òun yíò gbé wa, gbé wa sókè, yíò sì mú wa wá sí ilẹ̀ ìlérí ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀—ní ayérayé.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹta 2026.. Yoruba. 19937 779