Làìhónà
Ipa-ọ̀nà Májẹ̀mú Aláyọ̀
Làìhónà Oṣù Kejì 2026


“Ipa-ọ̀nà Májẹ̀mú Aláyọ̀,” Làìhónà, Oṣù Kejì 2026.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Lìáhónà , Oṣù Kejì 2026

Ipa-ọ̀nà Májẹ̀mú Aláyọ̀

Ìyanu àti ọlánlá ti àwọn ọmọ ẹbí tí a so pọ̀ níwájú Baba àti Ọmọ nmú ẹ̀rù àti ayọ̀ tí ó tayọ wá sí ọkàn mi ó sì fi ẹ̀mí ìmoore kún inú mi.

Alàgbà Patrick Kearon àti ìyàwó rẹ̀, Jennifer

Alàgbà Patrick Kearon àti ìyàwó rẹ̀, Jennifer

Nígbàtí Ísráẹ́lì àti Elizabeth Haven Barlow kúrò ní Nauvoo, Illinois, lọ sí àfonífojì Salt Lake ní 1848, wọ́n fi ọmọdékùnrin kan sílẹ̀ lẹ́hìn tí a sin ní ìtẹ́ òkú Nauvoo kékeré kan. James Nathaniel Barlow kékeré, ọmọ àkọ́kọ́ wọn, ti kú ní kété lẹ́hìn ìbímọ ní Oṣù Karun 1841.

Pẹ̀lú lílọ sí Àfonífojì Salt Lake, ó ṣeé ṣe kí Ísráẹ́lì àti Elizabeth kò retí láé láti tún wo ibojì ọmọkùnrin wọn mọ́. Ṣùgbọ́n nígbàtí wọ́n pè Ísráẹ́lì fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan ní England ní ọdún díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ó gba Nauvoo kọjá bí ó ti nrìn ìrìn àjò lọ sí ìhà ìlà oòrùn. Ní ìbèèrè láti ọ̀dọ̀ Elizabeth, ó dúró láti wá ibojì ọmọkùnrin wọn kí ó sì gbé àwọn ìyókù rẹ̀ lọ sí ibi-ìsìnkú pàtàkì, ní ìlà-oòrùn ti ìlú.

Lẹ́hìn ọjọ́ kan ti wíwá áìní-ayọrísí, Ísráẹ́lì wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ alábòjútó ìbílẹ̀ náà. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n rí ibojì náà, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Màríà ẹ̀gbọ́n James. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn pósí náà ti bàjẹ́ tí wọ́n sì ti fọ́. Nínú lẹ́tà sí ìyàwó rẹ̀, Isráẹ́lì kọ̀wé, “Nítorínáà mo yípadà mo sí pinnu pé èmi yíò fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ títí di ọjọ́ iwájú.”

Kò rìn jìnnà kúrò ní ibojì nígbàtí ó gbọ́ ohùn kan. Ní rírántí ìrírí náà, ó kọ̀wé pé, “Kì í ṣe èyí tí a gbọ́, ṣùgbọ́n ó yàtọ̀ sí ọkàn mi débi pé èmi kò lè sọ ọ́ pé: ‘Baba, má fi mí sílẹ̀ ní ìhín.’” Ísráẹ́lì padà sí ibojì, ní ìparí láti yọ ọmọdékùnrin kékeré rẹ̀ kúrò lẹ́hìn gbogbo rẹ̀. “Mo nímọ̀lára àlàáfíà inú jẹ́jẹ́ tí ó sì yàtọ̀ púpọ̀ èyítí èmi kò nímọ̀lára rẹ̀ tẹ́lẹ̀. … Púpọ̀ yí ni èmi yíò sọ: pé èmi kò ní ìfura púpọ̀ síi nípa iṣẹ́ kíṣẹ́ tí a ṣe ní ìgbésí ayé mi.”

Ní ọjọ́ kejì Oṣù Kẹsan, 1853, Ìsráẹ́lì Barlow àti alábojútó gbé àwọn òkú James ati Maria lọ sí ibi-ìsìnkú pàtàkì ti Nauvoo, ó sàmìsí ààyè náà pẹ̀lú “àwọn òkúta ní orí àti ẹsẹ̀ àwọn ibojì.”

Ísráẹ́lì sọ fún Elizabeth pé bí òun ṣe nlọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibojì, “Mo ní ìfẹ́ inú láti ya ara mi sí mímọ́ àti ohun gbogbo tí èmi lè pè ní tèmi sí ọwọ́ Olúwa, kí a lè kà mí sí ẹni yíyẹ láti jáde wá pẹ̀lú [James] ní òwúrọ̀ Àjínde Ìkínní.”

Ìfọkànsìn Ísráẹ́lì fún ìhìnrere Jésù Krístì, papọ̀ pẹ̀lú bíbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú mímọ́, gba Krístì láàyè láti ní ìyè àìnípẹ̀kun—tí ó tóbi jùlọ nínú gbogbo ìbùkún—ó ṣeé ṣe fún un, àwọn baba nlá rẹ̀, àti àtẹ̀lé rẹ̀.

Èyí kannáà jẹ́ òtítọ́ fún gbogbo wa.

àwọn àtẹ oúnjẹ Olúwa

Àworan láti ọwọ́ Jerry Garns, lè jẹ́ ẹ̀dà fún lílò Ìjọ nìkan

Àwọn Ìlérí Mímọ́

Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, fẹ́ràn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa kọjá ohunkóhun tí a lè rò lọ. Kò sí ibìkan tí ìfẹ́ Wọn ti hàn ju nípasẹ̀ àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí tí ó so mọ́ àwọn májẹ̀mú tí a fifún wa ní ìrìbọmi àti nínú ilé Olúwa.

“Ọ̀kan nínú àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì jùlọ ti ẹ̀sìn tí a fihàn ní ti májẹ̀mú mímọ́,” Ààrẹ Russell M. Nelson (1924–2025) kọ́ni. “Ní èdè tó bófin mu, májẹ̀mú sábà máa ntọ́ka sí àdéhùn tó wà ní àárín àwọn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nínú àkóónú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, májẹ̀mú ṣe pàtàkì jùlọ. Ó Jẹ́ Ìlérí mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.”

Gbogbo ìlérí mímọ́ tí a ṣe tí a sì pa mọ́ nbùkún wa. Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà wa Jésù Krístì fẹ́ láti fà wá súnmọ́ Wọn. Wọ́n fẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ kí a sì dàgbà nínú ìgbàgbọ́ àti òye. Wọ́n fẹ́ láti fún wa ní agbára ọ̀run. Wọ́n fẹ́ kí a rí ìwòsàn àti àlàáfíà nínú ayé níbi tí irú àwọn ìbùkún bẹ́ẹ̀ ṣì wà láìsí àní-àní. Wọ́n fẹ́ kí a ní ìrírí ayọ̀ ní ayé yí àti ní ayé tó nbọ̀. Ṣíṣàn láti inú ìfẹ́ pípé yí, Wọ́n fún wa ní àyè láti wọ inú májẹ̀mú ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Wọn. A ní ìbùkún ìràpadà sí àwọn májẹ̀mú wọnni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà ìpàdé oúnjẹ Olúwa.

A nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa nínú ẹ̀mí ìdúpẹ́ nítorí a ní ìbùkún ayọ̀ ti gbígbé orúkọ Jésù Krístì lé ara wa, ní rírántí Rẹ̀ àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa tí a fihàn nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ètùtù Rẹ̀—pé Ó jìyà, ṣẹ̀jẹ̀, ó sì kú fún wa. Oúnjẹ Olúwa náà tún nbùkún wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú ànfàní láti fi níní ìfẹ́ wa hàn láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, tún àwọn májẹ̀mú wa ṣe, kí a sì dá májẹ̀mú titun kan (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:77, 79).

“Nígbàgbogbo, mo ngbọ́ ìsọ̀rọ̀ pe à nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa láti tún àwọn májẹ̀mú ti a dá ní ìrìbọmi ṣe. Nígbàtí èyí jẹ́ òtítọ́, ó ju bẹ́ẹ̀ lọ,” ni Ààrẹ Nelson sọ. “Mo ti dá májẹ̀mú titun. Ẹ ti dá àwọn májẹ̀mú titun. … Báyìí ní àbábọ̀ fún èyítì [Olúwa] ti ṣe ẹ̀là ọ̀rọ̀ pé a ò fìgbàgbogbo ní Ẹ̀mí Rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wa. Irú ìbùkún wo lèyí!”

Nígbàtí a bá ronúpìwàdà tí a sì jẹ oúnjẹ Olúwa pẹ̀lú ọkàn mímọ́, a gba Ẹ̀mí Mímọ́ a sì “wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹnipé a ṣe ìrìbọmi lẹ́ẹ̀kansi. Èyí ni ìrètí àti àánú tí Jésù fifún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa.”

Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ayọ̀ tó láti ronúpìwàdà kí a sì rí ìdáríjì nípasẹ̀ ìfẹ́ ìràpadà Krístì!

Tẹ́mpìlì Nauvoo Illinois

Àwòrán Tẹ́mpìlì Nauvoo Illinois láti ọwọ́ Jennifer Rose Maddy

Ilé Ayọ̀ Rẹ̀

Lẹ́hìn dídi Ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, Ààrẹ Nelson máa nsọ̀rọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà nípa ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìta gbangba rẹ̀ àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Ìjọ. A nwọ ipa-ọ̀nà náà nípasẹ̀ “ìrònúpìwàdà àti ṣíṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ omi” (2 Néfì 31:17), ó sọ ní àkokò kan lẹ́hìnnáà, àti “nígbànáà a sì wọ inú rẹ̀ tán nínú tẹ́mpìlì.”

Gẹ́gẹ́bí jíjẹ oúnjẹ Olúwa ṣe nrán wa létí àwọn májẹ̀mú wa àti àwọn ìbùkún tó rọ̀ mọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára nínú tẹ́mpìlì. Bí a ṣe nṣe àwọn ìlànà nípasẹ̀ arọ́pò fún àwọn tí wọ́n ti kọjá lọ, a rántí àwọn ìlérí mímọ́ tí a ti ṣe àti àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí pé a ó gbà.

Nípasẹ̀ ipa-ọ̀nà májẹ̀mú, a di ajùmọ̀-jogún sí gbogbo àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí fún Ábráhámù, Isaac, Jákọ́bù, àti àtẹ̀lé wọn.” Láìka àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí náà sí, Ábráhámù, Isaac àti Jákọ́bù kò gbé ìgbésí ayé tó rọrùn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwa. Gẹ́gẹ́bí tiwọn, a dojúkọ ìpọ́njú, ìbáwí, àti òfò bí a ṣe “ndán wa wò nínú ohun gbogbo” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 136:31; bákannáà wo 101:4–5). Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn wòlíì àti àwọn ènìyàn mímọ́ olódodo ti ìgbà àtijọ́, a mọ ẹni tí a lè gbẹ́kẹ̀lé (wo 2 Néfì 4:19).

Ayé ikú wa jẹ́ ṣùgbọ́n àkokò kan nínú wíwàláyè wa, ṣùgbọ́n àkókò náà—nígbà míràn tí ó le gan-an—jẹ́ pàtàkì títí ayérayé. Bẹ́ẹ̀ni, Baba wa Ọ̀run fẹ́ kí a kẹ́kọ̀ọ́ kí á sì dàgbà. Àti pé, bẹ́ẹ̀ni, ìdàgbà náà nígbà míràn pẹ̀lú ìjákulẹ̀ àti ìjìyà. Ṣùgbọ́n Ó fẹ́ kí ìgbé ayé wa lẹ́wà àti ìrètí. Sí òpin náà, àti láti mú ìrìnàjò wa padà sọ́dọ̀ Rẹ̀ rọrùn, Ó ti pèsè Olùgbàlà, ẹnití ó jẹ́ “olùdúró” ti àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Baba Rẹ̀. Nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì, Baba mú ìlérí tí a ṣe fún àwọn ọmọ Rẹ̀ nínú tẹ́mpìlì ṣẹ.

Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti ẹbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà wa ti kojú ó sì ti wo gbogbo ohun tí a yíò bá pàdé nínú ayé sàn. Àti nítorí ilé mímọ́ Rẹ̀—ilé ayọ̀ Rẹ̀—gbogbo rẹ̀ yíò dára láìka ìdààmú sí. Ìkúnra pípa májẹ̀mú mọ́ gbá ìbànújẹ́, ìrora, ẹ̀dùn, àti ìjákulẹ̀ kúrò. A kò nílò láti dààmú tàbí bẹ̀rù. Dípò bẹ́ẹ̀, a lè yọ̀ pé a ti san iye owó ìràpadà wa (wo 1 Kọ́ríntì 6:20) àti pé ipa-ọ̀nà májẹ̀mú sí ìyè ayérayé ni a ti fi lélẹ̀.

ipa-ọ̀nà májẹ̀mú nítòótọ́ jẹ́ ipa-ọ̀nà ìfẹ́ ìràpadà. Bí a ṣe nbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a dá nínú tẹ́mpìlì, a ngba àwọn ìbùkún agbára títóbijù, ìfẹ́ títóbijù, àánú títóbijù, òye títóbijù, àti ìrètí títóbijù. Ìyanu àti títóbi nlá ti àwọn èdidi tẹ́mpìlìi—ti àwọn ọmọ ẹbí tí a so papọ̀ nínú ìfẹ́ fún gbogbo ayérayé—nmú ẹ̀rù àti ayọ̀ tí ó tayọ wá sí ọkàn mi ó sì nkún ẹ̀mí mi pẹ̀lú ìmoore.

“Ìgbàkugbà tí irú àjálù eyikeyi bá ṣẹlẹ̀ nínú ìgbé-ayé yín, ibi ààbò jùlọ láti wà ní ti ẹ̀mí ni gbígbé inú àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín!” Ààrẹ Nelson gbani nímọ̀ràn. Mo mọ̀ látinú ìrírí ayé-ikú didun àti ìgbà míràn kíkorò ti ara mi níti òtítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì.

ìjúwe ti tọkọtaya tí wọ́n di ọmọ-ọwọ́ mú

James Nathaniel Barlow, ọmọ àkọ́kọ́ ti àti Elizabeth Barlow, kú ní kété lẹ́hìn ìbímọ ní Oṣù Karun 1841. Àwọn ọdún lẹ́hìnnáà, a fi èdidì dìí nípasẹ̀ arọ́pò sí àwọn òbí rẹ̀ ní Tẹ́mpìlì Logan Utah.

Ìjúwe láti ọwọ́ Allen Garns

Kó Wọn Jọ Sí ilé

Lẹ́hìn tí Israel Barlow ti ṣe ìdágbére ìkẹ́hìn fún ọmọdékùnrin rẹ̀ kékeré, ó kọ̀wé sí ìyàwó rẹ̀ pé, “Àwọn ìrònú àìwà ara mi lọ́nà jíjìn, kò sí nínú ayé láti padà sí ibojì [James] mọ́, ní fífi fọ́nrán ìfẹ́ni ìkẹhìn tí mo ní títí di ìgbà tí ó fi fọ́ pẹ̀lú omijé lórí ibojì rẹ̀.”

Mo ròó pé omijé ayọ̀ púpọ̀ sí i—omijé ayọ̀ ní àkokò yí—ní ó jábọ́ ní ọjọ́ kẹrin Oṣù Kejìlá 1889. Ní ọjọ́ náà, James Nathaniel Barlow kékeré ni a fi èdidì dì sí àwọn òbí rẹ̀ ní Tẹ́mpìlì Logan Utah. Nígbànáà, Israel ti kọjá lọ, nítorínáà àwọn míràn dúró gẹ́gẹ́bí aṣojú fún òun àti James.

Arábìnrin Kearon àti èmi nímọ̀lára kan pàtó àti ìyọ́nú nla fún Israeli àti Elizabeth. Ọmọkùnrin wa àkọ́kọ́, ọmọdékùnrin kan tó njẹ́ Sean, kú nígbà iṣẹ́ abẹ ọkàn nígbà tí ó wà ní ọmọ ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré. Èyí jẹ́ ìpàdánù tó da ilẹ-aye rú fún wa. Nígbà náà, a máa ó máa nyà wá lẹ́nu pé bóyá a lè yè. A sin ín sí ibojì kékeré kan tó ronilára ​​ní England. Ọdún marundinlógún lẹ́hìnnáà, wọ́n ní kí ẹbí wa kúrò ní ilé wa ní United Kingdom láti sìn fún ìgbà kíkún nínú Ìjọ, a sì fi ibojì kékeré ná sílẹ̀.

A kò pàdánù ọmọ wa lórí ìrìn ìwọ̀-oòrùn, àti pé a kò jìyà àwọn ìnira tí kò ní òye ti àwọn Barlow, ṣùgbọ́n a ní ìbẹ̀rẹ̀ ti òye ohun tí wọ́n là kọjá. Isà òkú ọmọdékùnrin wa jìnnà gan-an, síbẹ̀ gẹ́gẹ́bí àwọn Barlow, a ní ìgbàgbọ́ tí ó dúró ṣinṣin nínú Àjínde Jésù Krístì àti ẹ̀dá ayérayé ti ẹbí wa nípasẹ̀ májẹ̀mú èdìdì mímọ́.

Gbogbo wa la ní àwọn baba nlá àtàwọn olólùfẹ́ míràn lẹ́hìn ibojì tí wọ́n nsọ fún wa pé, “Má fi mí sílẹ̀ níbí.” Nítorí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì, kò sí ẹni tí a nílò láti fi sílẹ̀ sẹ́hìn. Ipè wa ni láti fẹ́ràn wọn, sìn wọ́n, àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kó wọn jọ sílé.

Baba wa Ọ̀run fẹ́ràn wa, ẹ̀yin ati èmi. Ó ti fún wa ní àwọn tẹ́mpìlì kí “ohunkóhun tí [àwa] bá dè ní ilẹ̀ ayé, ni a ó so ní ọ̀run” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 128:8; bákannáà wo Máttéù 18:18). Ó rán Ọmọ Rẹ̀ láti já àwọn ìdè ikú, ní líla ọ̀nà sílẹ̀ fún ìsopọ̀ ayérayé àti ìpàdé ayérayé.

Ìdí nìyí tí a fi ní àwọn ìlànà. Ìdí nìyí tí a fi ndá àwọn májẹ̀mú. Ìdí nìyí tí a fi nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì. Ìdí nìyí tí a fi nya ara wa sí mímọ́ fún iṣẹ́ àti ògo Ọlọ́run (wo Mósè 1:39). Àti pé ìdí nìyí tí a fi nda omijé ayọ̀, ní mímọ̀ pé àtúndàpọ̀ ayérayé ndúró de àwa àti àwọn olólùfẹ́ wa níwájú Baba àti Ọmọ.

Njẹ́ kí á rí ayọ̀ àti àlááfíà bí a ṣe npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ tí a sì ndarapọ̀ mọ́ Olúwa nínú iṣẹ́ ìgbàlà ológo Rẹ̀.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Ora H. Barlow, Ìtàn Israel Barlow àti Mormon Mores (1968), 306–8; kíka ọ̀rọ̀ àti àmì ti di ìgbàlódé; bákannáà wo Brent A. Barlow, “Baba, Máṣe Fi Mí Sílẹ̀ Níbí,” Ẹ́nsáìnì, Oṣù Kéje 2009, 34–36.

  2. Wo Russell M. Nelson, “Àwọn Májẹ̀mú,” Lìáhónà, Oṣù Kọkànlá 2011, 86.

  3. Wo “Mo Dúró Ní Gbogbo Ìyanu,” Àwọn orin, nọ́mbà 193.

  4. Russell M. Nelson nínú Dale G. Renlund, “Jíjẹ́ Olóòtítọ́ sí Jésù Krístì Láìyẹsẹ̀,“ Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2019, 25, àkọsílẹ̀-ìsàlẹ̀ 18.

  5. Jésù Krístì Ní Kí Á Má a Jẹ Oúnjẹ Olúwa”, Lìàhónà, Oṣù Kẹta 2021, 7.

  6. Russell M. Nelson, “Bí A Ti Nlọ Síwájú Papọ̀,” Lìàhónà, Oṣù Kẹrin 2018, 7.

  7. Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” Lìàhónà, Oṣù Kẹwa 2022, 6.

  8. Fún titòsílẹ̀ àwọn ìbùkún tí a ṣèlérí wọnnì, wo Russell M. Nelson, “Àwọn Májẹ̀mú,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2011, 87.

  9. Wo Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,” 10.

  10. Wo Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin Náà,“ 7.

  11. Russell M. Nelson, “Tẹ́mpìlì àti Ìpìlẹ̀ Ti-ẹ̀mí Yín,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá 2021, 96.

  12. Israel Barlow, ní Ora H. Barlow, Ìtàn Israel Barlow Náà, 308; kíka ọ̀rọ̀ àti àmì ti di ìgbàlódé.

  13. Ọjọ́ fífi èdidi dì ni a pèsè nípasẹ̀ Ibi-Ìkàwé Àkọọ́lẹ̀-Ìtàn Ìjọ.