“Ètò Ọlọ́run Títíláé fún Ẹbí kan,” Lìàhónà, Oṣù Kejìlá. 2025.
Ọ̀rọ̀ Oṣoòṣú Lìàhónà , Oṣù Kejìlá 2025
Ètò Ọlọ́run Títíláé fún Ẹbí kan
Àwọn ẹbí tí wọ́n gba ètò Ọlọ́run mọ́ra, tí wọ́n fẹ́ràn gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti fẹ́ràn, tí wọ́n sì nbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú wọn yíò jogún “àwọn ìbùkún ìyè àìnípẹ̀kun àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ níjọ́kan.”
Ní sísúnmọ́ òpin iṣẹ́ ìrànṣẹ́ ìgbà-kíkún mi, inú mi dùn nígbàtí wọ́n fún mi ní ẹ̀bùn tí a sì fi èdìdì dì mí sí àwọn òbí mi nínú Tẹ́mpìlì São Paulo Brazil.
Àwọn òbí mi, Apparecido àti Mercedes, wá láti onírúurú àtilẹ̀bá ẹ̀sìn, ṣùgbọ́n àwọn ìrírí ìgbésí ayé wọn múra wọn sílẹ̀ láti tẹ́wọ́gba ìhìnrere tí a múpadàbọ̀sípò.
A tọ́ bàbá mi dàgbà nínú ẹbí rere ṣùgbọ́n kì í ṣe ẹlẹ́sìn. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan ó nífẹ sí ẹ̀sìn. Ó ka Bíbélì, ó lọ sí kíláàsì Bíbélì, ó sì kẹ́kọ ìgbésí ayé Jésù Kristi. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ jẹ́ kí ó ní ìfẹ́ nlánlà nínú ìhìnrere Olùgbàlà àti ẹbí, tí ó fi ìfẹ́-inú rẹ̀ láti fẹ́ ẹnìkan tí ó ní inú kannáà bíiti rẹ̀ sílẹ̀.
Ní ìlòdi, ìyá mi wá láti inú ẹbí ẹlẹ́sìn tó jinlẹ̀. Wọ́n tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà ìhìnrere, wọ́n lọ sí àwọn ìsìn ìjọ, wọ́n sì nfi ìṣòtítọ́ ṣe ẹ̀sìn wọn. Ní dídàgbà sókè ní àyíká náà, màmá mi di irú ẹnití kì í pa ìpàdé ìjọ jẹ rárá.
Àti pé, lẹ́hìn tí àwọn òbí mi ṣe ìgbéyàwó tí àwọn arákùnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti èmi sì wá pẹ̀lú, wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti tọ́ wa dàgbà nínú ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ wọn nípa àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Lọ́jọ́ kan ẹ̀gbọ́n ìyá mi, tó jẹ́ ọmọ ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tí kìí lọ sí ìjọ déédé, sọ fún bàbá mi pé, “O ní ọmọkùnrin mẹ́rin, ọ̀wọ́n. Tí o bá fẹ́ láti tọ́ ẹbí kan ninu oókan Krístì lódodo àti pé kí o ní Ọlọrún nínú ẹbí rẹ, o nílò láti lọ sí ìjọ mi.”
Bàbá mi gbọ́ ohun tí ó sọ, ṣùgbọ́n kò gbé ìgbésẹ̀ kankan títí di ọjọ́ tí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ìgbà-kíkún npin ìwé ìléwọ́ ní àdúgbò wa, tí wọ́n sì kan ilẹ̀kùn wa, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ wa. Ó yára damọ̀ pé ìjọ tí àbúrò ìyá mi ti gbà á níyànjú láti ṣe ìwádìí ni wọn nṣojú fún.
Ìmọ́lẹ̀ àti Òtítọ́
Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó dùn mọ́ àwọn òbí mi nínú lákọkọ́ ní ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ni jíjẹ́pàtàkì tí Ìjọ fi lélẹ̀ lórí ẹbí àti ẹ̀kọ́ náà pé “ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Ọlọ́run ni a nṣeyọrí nípasẹ̀ ẹbí.” Kí wọ́n tó ṣe ìrìbọmi, ohun tí wọ́n nkọ́ wú àwọn òbí mi lórí débi pé wọ́n ké sí àwọn aládugbò wọn láti darapọ̀ mọ́ wọn fún àwọn ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́.
Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó dùn mọ́ àwọn òbí mi nínú ní àkọ́kọ́ ni ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì ni jíjẹ́pàtàkì tí Ìjọ fi lélẹ̀ lórí ẹbí.
Bí wọ́n ṣe nbá àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere pàdé, tí wọ́n sì nbá ìkẹ́kọ ìhìnrere lọ lẹ́hìn ìrìbọmi wọn, àwọn òbí mi kẹ́kọ nípa àwọn ọ̀nà “láti tọ́ àwọn ọmọ [wọn] dàgbà nínú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́” àti bí wọ́n ṣe lè “gbé ilé ara [wọn] kalẹ̀ létòletò nípa ti ẹ̀mí” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:40, 43).
Wọ́n kẹ́kọ pé “ẹbí jẹ́ àárin-gbùngbun nínú ètò Ìṣẹ̀dá fún àyànmọ́ ayérayé ti àwọn ọmọ Rẹ̀” àti pé “ìdùnnú nínú ìgbé ayé ẹbí ṣeéṣe jùlọ láti ṣe àṣeyọrí rẹ̀ nígbàtí a bá fi lélẹ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ Olúwa Jésù Kristi.”
Wọ́n kẹ́kọ pé “àwọn ìgbéyàwó àti àwọn ẹbí tí ó yege ni a gbékalẹ̀ tí a sì múdúró lórí àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbàgbọ́, àdúrà, ìrònúpìwàdà, ìdáríjì, ìtẹríba, ìfẹ́, àánú, iṣẹ́, àti àwọn eré ìdárayá tí ó ṣànfàní.”
Wọ́n kẹ́kọ pé àwọn ẹbí lè jẹ́ ayérayé àti pé “ìbáraẹni kẹ́gbẹ́ tí ó wà ní àárín wa níhìn yíò wà ní àárín wa lọ́hun, kìkì pé yíò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ògo ayérayé” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 130:2).
Wọ́n sì kẹ́kọ pé “èrèdí ìgbẹ̀hìn ti gbogbo ẹ̀kọ́, gbogbo eré ìdárayá nínú Ìjọ ni pé àwọn òbí àti àwọn ọmọ wọn ní ìdùnnú ní ilé, tí a fi èdìdì dì nínú ìgbéyàwó ayérayé, tí wọ́n sì so mọ́ àwọn ìran wọn.”
Pẹ̀lú ìmọ̀ náà, wọ́n fẹ́ kí a fi èdìdì dì wọ́n gẹ́gẹ́bí ẹbí títíláé.
Ojú Kan Síwájú Ayé Àìlópin
Lẹ́hìn tí àwọn òbí mi ṣe ìrìbọmi, wọ́n fi ohun tí wọ́n nkọ́ ṣèwà hù, wọ́n nkúrò nínú ayé lọ sínú ìjọba ìhìnrere. Wọ́n ṣiṣẹ́ láti mú ẹbí wa ṣọ̀kan nípa níní ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́ àti àṣàrò Ìwé Mímọ́ ẹbí, lílọ sí àwọn ìpàdé Ìjọ nínú òtítọ́, àti ṣíṣe iṣẹ́ àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí. Pẹ̀lú ìtiraka wọ̀nnì síwájú ìṣọ̀kan, wọ́n nírètí láti dá ẹbí kan tí ó dojúkọ ètò ìgbàlà pẹ̀lú ojú kan síwájú ayé àìlópin sílẹ̀.
Ní 1965, ọdún tí àwọn òbí mi ṣe ìrìbọmi, tẹ́mpìlì tó súnmọ́ São Paulo, Brazil jù, wà ní Mesa, Arizona, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà máìlì kúrò. Ìrìn-àjò jẹ́ oníyelórí púpọ̀ fún ẹbí wa, nítorínáà àwọn òbí mi níláti dúró títí di ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì São Paulo Brazil ní 1978 ṣáájú kí wọn tó gba àwọn ìlànà tẹ́mpìlì wọn kí a sì fi èdìdí dì wọ́n. Ní àkókò náà, mo nsìn níbi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní Rio de Janeiro.
Ní nkan bí oṣù méjì kí ntó parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi ní Oṣù Kejì ọdún 1980, ààrẹ míṣọ́n mi gba èmi àti ojúgbà mi láyè láti rìnrìn àjò alẹ́ mọ́jú pẹ̀lú àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀ka láti Rio de Janeiro sí tẹ́mpìlì ní São Paulo kí nlè gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì àti èdìdì sísopọ̀ sí àwọn òbí mi. Gẹ́gẹ́bíi ti àwọn òbí mi, mo ti dúró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún de ìlérí àwọn ìbùkún ti àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti àwọn májẹ̀mú.
Ìrírí náà yí ìran mi nípa ọjọ́ ọ̀la padà ó sì fún mi ní ìríran àkọ́kọ́ ti òtítọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Russell M. Nelson àìpẹ́ yìí: “Àkókò nínú tẹ́mpìlì yíò ràn yín lọ́wọ́ láti ronú sẹ̀lẹ́stíà àti láti rí ìran ẹnití ẹ̀yin jẹ́ gan-an, ẹnití ẹ lè dà, àti irú ìgbésí ayé tí ẹ lè ní títíláé.”
Ìgbà kúkúrú tí mo fi wà nínú tẹ́mpìlì ní àkókò náà nípa lórí ìyókù iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi. Pẹ̀lú ìran titun náà, jíjẹ́rìí tẹ́mpìlì àti jíjẹ́pàtàkì ètò Ọlọ́run fún àwọn ẹbí tún ní ipa pípẹ́ títí lórí ìgbésí ayé mi.
Nígbàtí èmi àti aya mi, Rosana, ṣe ìgbéyàwó ní ọdún méjì lẹ́hìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, a fi èdìdì dì wá nínú tẹ́mpìlì pẹ̀lú ìran kan ti títọ́ ẹbí ayérayé wa dàgbà. Láti ṣe bẹ́ẹ̀, a ṣiṣẹ́ papọ̀ láti dá àwọn àṣà ẹbí bí èyítí àwọn òbí wa ti kọ́ wa sílẹ̀, gbogbo wọn dojúkọ Olùgbàlà, àwọn ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti àwọn ẹ̀kọ́ àwọn wòlíì Rẹ̀ òde-òní.
Lóni àwọn ọmọ wa ntọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà pẹ̀lú àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere kannáà ti ìdùnnú. Fún wa, ẹbí jẹ́ ohun gbogbo nítorípé a lóye jíjẹ́ àárin-gbungbun ti ẹbí nínú ètò Ọlọrún.
Gẹ́gẹ́bí Aláṣẹ Gbogbogbò, mo ní ìbùkún ti fífi èdìdí di àwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sí àwọn ìyàwò wọn nínú tẹ́mpìlì. Wíwo ojú wọn ní àkókò tí wọ́n kúnlẹ̀ ní pẹpẹ nínú tẹ́mpìlì jẹ́ ìrírí rírẹwà. Mo rí ìrandíràn mi tí à nbùkún nípa àwọn ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìhìnrere kannáà tí àwọn òbí mi kọ́ mi àti pé Rosana àti èmi ti kọ́ wọn. Mo lè rí àwọn ìbùkún náà tí ó ntẹ̀síwájú nínú àwọn ìran tó nbọ̀. A sì rán mi létí ẹnití ó mú kí ó ṣeéṣe.
Ìránnilétí Kérésìmesì Kan
Ìdílé jẹ́ ààrin-gbùngbùn sí èrò ayọ̀ ti Ọlọ̀run, ṣùgbọ́n láìsí Jésù Krístì Olùgbàlà, ètò náà kò ní ṣeéṣe. Ètùtù Rẹ̀ àti àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tí a rí nínú ìhìnrere Rẹ̀ mú ìlérí ìgbéga ṣeéṣe.
Ààrẹ Nelson ti kéde pé: “Ìgbéraga jẹ́ ọ̀ràn ẹbí nìkan. Nípasẹ̀ àwọn ìlànà ìgbàlà ti ìhìnrere ti Jésù Krístì nìkan ni a lè gbé àwọn ẹbí ga. I`gbẹ̀hìn òpin tí ó ga jùlọ tí a nlàkàkà fún ni pé kí a ní ìdùnnú gẹ́gẹ́bí ẹbí—tí a ti fi ẹ̀bùn tẹ́mpìlì fúnni, fi èdìdì dì, tí a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ìyè ayérayé níwájú Ọlọrun.”
Nígbàtí mo ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ibití Èmi kò tíì rí tẹ́lẹ̀, mo gbìyànjú làti wa ibi ìran kékeré ti ọjọ́ Ìbí-Jésù kan tí ó nrán èmi àti Rosana létì nípa Olùgbàlà. Mó nṣe àkójọpọ̀ ohun púpọ̀.
Nígbàtí èmi àti ìyàwó mi nronú nípa àwọn ìran ìrẹ̀lẹ̀ ọjọ́ Ìbí Jésù, èmi àti ìyàwó mi ronú nígbà kan pé, “Kí ló ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí ayé wa?” Bẹ́ẹ̀ni, ìdáhùn náà, ni Olùgbàlà, Ìhìnrere Rẹ̀, àti ẹbí wa. Láti rán wa létí ìfẹ́ Bàbá Ọ̀run fún wa àti pé nípasẹ̀ Olùgbàlà ni ìlérí ti àwọn ẹbí ayérayé di ṣíṣe, ṣáájú Kérésìmesì ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn a gbé gbogbo àwọn ọjọ́ Ìbí Jésù wa sí orí ṣẹ́lìfù ńlá méjì nínú ilé wa—a sì fi wọ́n sílẹ̀ dípò kí a gbé wọn kúrò lẹ́hìn àwọn ìsinmi Kérésìmesì. Àṣà náà ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti tọ́jú ẹ̀mí Kérésìmesì ní ilé wa yíká-ọdún.
Lójoojúmọ́ bí a ṣe nwo àwọn ìran ọjọ́ Ibí-Jésù náà, wọ́n rọra nrán wa létí ojúṣe àárin-gbùngbùn Olùgbàlà nínú àwọn ìgbésí ayé wa. Wọ́n rán wa létí pé àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé nísisìyí (wo Luku 2:14) àti ayọ̀ ayérayé ní ayé tí ó nbọ̀ dá lé Olùgbàlà àti lórí bíbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú tí a ti dá pẹ̀lú Rẹ̀. Wọ́n sì rán wa létí “pé ó wá sí ayé, àní Jésù, láti jẹ́ kíkàn mọ́ àgbélébu fún aráyé, àti láti ru ẹ̀ṣẹ̀ aráyé, àti láti sọ ayé di mímọ́, àti láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo;
“Pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí gbogbo ènìyàn là ẹnití Bàbá lé di gbígbàlà àwọn tí Baba ti fi sínú agbára rẹ̀ àti tí a dá nípa ọwọ́ rẹ̀” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 76:41–42).
Gẹ́gẹ́bí a ti kẹ́kọ òtítọ́ wọ̀nyí lọ́dọ̀ àwọn òbí wa, èmi àti Rosana ti ṣiṣẹ́ láti fi wọ́n lé àwọn ọmọ wa lọ́wọ́. Ní báyìí àwọn ọmọ wa nkọ́ àwọn ọmọ wọn ní òtítọ́ kannáà. Àwọn irúgbìn tí a gbìn sí ọkàn àwọn òbí mi ní ọgọ́ta ọdún sẹ́hìn ní ilé kékeré wa ní Brazil ti gbilẹ̀ tí wọ́n sì so èso “èyítí ó ṣe iyebíye jùlọ, ti o dun ju gbogbo ohun ti o dun, tí ó sì funfun ju gbogbo èyítí ó jẹ́ funfun, bẹ́ẹ̀ni, tí ó sì mọ́ ju gbogbo ohun tí ó jẹ́ mímọ́ lọ” (Álmà 32:42).
Mo jẹ́ri síi pé àwọn tí wọ́n gba ètò Ọlọ́run fún àwọn ẹbí mọ́ra, fẹ́ràn gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà ti fẹ́ràn, tí wọ́n sì nbu-ọlá fún àwọn májẹ̀mú wọn yíò jogún “àwọn ìbùkún ìyè ayérayé àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ níjọ́kan” pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wọn àti pẹ̀lú Bàbá àti Ọmọ.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kejìlá 2025. Yoruba. 19614 779