2024
Jésù Krístì Ni Orísun ti “Yíyè,” “Rere,” àti “Ìrètí Dídára Púpọ̀”
Oṣù Kejìlá 2024


“Jésù Krístì Ni Orísun ti ‘Yiyè,’ ‘Rere,’ àti ‘Ìrètí Dídára Púpọ̀,’” Làìhónà, Oṣù Kejìlá 2024.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kejìlá 2024

Jésù Krístì Ni Orísun ti “Yíyè,” “Rere,” àti “Ìrètí Dídára Púpọ̀”

Ní àkokò pàtàkì ti ṣíṣe ayẹyẹ ìbí ti ọmọ-ọwọ́ náà ní Bẹ́thlẹ́hẹ́mù, njẹ́ kí a rántí nígbàgbogbo pé Jésù Krístì wá sínú ayé láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa.

Màríà àti Jósẹ́fù pẹ̀lú Jésù ọmọ-ọwọ́ náà

Ìṣẹ̀dá Náà, láti ọwọ́ Sharlotte Andrus

Àpóstélì Pétérù àti àwọn wòlíì Jákọ́bù àti Mórónì Ìwé Mọ́mọ́nì tẹnumọ pé ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí ìrètí nínú Krístì ní irú àwọn ọ̀nà ìkọ́ni kannáà.

Fún àpẹrẹ, Pétérù kéde pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Krístì, gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tí ó ti bí wa lẹ́ẹ̀kan sí ìrètí ìyè nípasẹ̀ àjínde Jésù Krístì kúrò nínú òkú” (1 Pétérù 1:3; àtẹnumọ́ àfikún). Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsí lílo ọ̀rọ̀ náà “yíyè” láti júwe “ìrètí.”

Jákọ́bù kéde pé, “Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin àyànfẹ́, ẹ bá làjà, nípasẹ̀ ètùtù Krístì, Ọmọ Bíbí rẹ̀ Kanṣoṣo, ẹ̀yin sì lè rí àjĩnde gbà, gẹ́gẹ́bí agbára àjínde tí ó wà nínú Krístì, kí a sì fi yín gẹ́gẹ́bí àkọ́bí Krístì sí iwájú Ọlọ́run, nípa ìgbàgbọ́, tí ẹ sì ti gba ìrètí ogo dáradára nínú rẹ̀ kí ó tó fi ara rẹ̀ hàn nínú ẹran ara” (Jákọ́bù 4:11; àtẹnumọ́ àfikún). Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsí lílo ọ̀rọ̀ náà “rere” láti júwe “ìrètí.”

Mórónì sí sọ pé, “Èmi sì rántí pẹ̀lú pé ìwọ ti wípé ìwọ ti pèsè ilé fún ènìyàn, bẹ̃ni, àní lãrín àwọn ibùgbé Baba rẹ, nínú èyítí èníyàn lè ni ìrètí tí ó dára púpọ̀; nítorí èyí ènìyàn gbọ́dọ̀ ní ìrètí, bí kò rí bẹ̃ kò lè gba ogún nínú ibi èyíti ìwọ ti pèsè sílẹ̀” (Ẹtérì 12:32; àtẹnumọ́ àfikún). Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyèsí lílo ọ̀rọ̀ náà “dídára” láti júwe “ìrètí.”

Kíni Ìrètí nínú Krístì

Ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí ìrètí nínú Krístì ni ayọ̀ ti ìyè ayérayé tí à nretí nípasẹ̀ “èrè, àti àánú, àti oore-ọ̀fẹ́ ti Mèsíàh Mímọ́” (2 Nefi 2:8) àti ìfẹ́-inú alágbára fún ìlérí àwọn ìbùkún òdodo. Ẹ̀yàn-ọ̀rọ̀ “yíyè,” “rere,” àti “dídára púpọ̀” nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí daba ìgbòòrò-títí àti ìdánilójú ìjáfáfá ti Àjínde àti ìyè ayérayé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.

Wòlíì Mọ́mọ́nì ṣe àlàyé:

“Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin mi, emí yíò bá yín sọ̀rọ̀ nípa ìrètí. Báwo ní ẹ̀yin ṣe lè ri ìgbàgbọ́ gbà, bíkòṣepé ẹ̀yin ní ìrètí?

“Kí sì ni ẹ̀yin yíò ní ìrètí fún? Ẹ́ kíyèsĩ mo wí fún yín pe ẹ̀yin yio ní ìrètí nípasẹ̀ ètùtù Krístì àti agbára àjínde rẹ̀, kí a gbé yín dìde sí ìyè tí kò nípẹ̀kun, èyítí ó sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ yín nínú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀.

“Nítorí èyí, bí ẹnikẹ́ni bá ní ìgbàgbọ́ ó gbọ́dọ̀ ní ìrètí; nítorí láìsí ìgbàgbọ́ kò lè sí ìrètí rárá” (Mórónì 7:40–42).

Ètò Ìdùnnú ti Baba

Ìrètí nínú Krístì tí ó jẹ́ yíyè, rere, àti dídára púpọ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pé Ọlọ́run Baba Ayérayé wà láàyè. Òun ni Baba wa, awà sì ni àwọn ọmọ ẹ̀mí Rẹ̀. Níti-ọ̀rọ̀ a jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí ti Ọlọ́run a sì ti jogún àwọn ìwà àtọ̀runwá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Baba ni olùdásílẹ̀ ètò ìdùnnú (wo Ábráhámù 3:22–28). Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí ti Ọlọ́run, àwa “tẹ́wọ́gba ètò Rẹ̀ nípa èyí tí àwọn ọmọ Rẹ̀ lè gba àgọ́ ara kí a sì jèrè ìrírí ti ilẹ̀-ayé láti gbèrú sí jíjẹ́ pípé àti nígbẹ̀hìn láti dá ìpín àtọ̀runwá wọn mọ̀ bí ajogún ìyè ayérayé.” Nínú ìwé-mímọ́, a kọ́ pé: “Baba ní àgọ́ ara ti ẹ̀ran ara àti àwọn egungun tí ó ṣe é fọwọ́kàn bíi ti ènìyàn; Ọmọ bákannáà” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 130:22). Bayi, gbígba àgọ́ ara ṣe pàtàkì nínú ìṣètò gbígbèrú síwájú ìpín àtọ̀runwá wa.

A jẹ́ méjì àwọn ẹlẹ́ran ara Ẹ̀mí wa, ara ayérayé wa, ni a wọ ní aṣọ nínú àgọ́ ara tí ó jẹ́ kókó sí àwọn ìfẹ́ inú àti ìpebi ti ayé-ikú. Ètò Ìdùnnú ti Baba ni a ṣe láti pèsè ìdarí fún àwọn ọmọ Rẹ̀, láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti padà láíléwu sílé sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú ara àjínde, ìgbéga, àti láti gba àwọn ìbùkún ayọ̀ àti ìdùnnú ayérayé.

Màríà pẹ̀lú ọmọ náà Jésù

Ọmọ Náà Krístì, láti ọwọ́ Sharlotte Andrus

Ojúṣe Ìrapadà ti Jésù Krístì nínú Ètò Baba

Jésù Krístì ni Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo ti Baba Ayérayé. Ó wá sínú ayé láti ṣe ìfẹ́ Baba Rẹ̀ (wo 3 Nefi 27:13). Jésù Krístì ni ẹni àmì òróró kan ti Baba láti jẹ́ aṣojú araẹni Rẹ̀ nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ìgbàlà gbogbo ènìyàn. Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa nítorí Ó ti ṣẹ́gun méjèjì ìkú àti ẹ̀ṣẹ̀.

Álmà sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn Gídeon nípa iṣẹ́ ìgbàlà ti Mèsíàh pé:

“Òun yíò sì jáde lọ, ní ìfaradà ìrora àti ìpọ́njú àti àdánwò onírurú; èyítí ó rí bẹ̃ kí ọ̀rọ̀ nã lè ṣẹ èyítí ó wípé òun yíò gbé ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ lé ara rẹ̀.

“Òun yíò sì gbé ikú lé ara rẹ̀, kí òun kí ó lè já ìdè ikú èyítí ó de àwọn ènìyàn rẹ̀; òun yíò sì gbé gbogbo àìlera wọn lé ara rẹ̀, kí inú rẹ̀ lè kún fún ãnú, nípa ti ara, kí òun kí ó lè mọ̀ nípa ti ara bí òun yíò ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ nínú gbogbo àìlera wọn.

“Nísisìyí, Ẹ̀mí-Mímọ́ mọ ohun gbogbo; bíótilẹ̀ríbẹ̃ Ọmọ Ọlọ́run jìyà nípa ti ara kí ó lè gbé ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ ka orí ara rẹ̀, kí ó lè pa gbogbo ìwàìrékọjá nwọn rẹ́ nípa agbára ìdásílẹ̀ rẹ̀” (Álmà 7:11–13).

Àkọ́kọ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìhìnrere ni ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì. Ìgbàgbọ́ òtítọ́ ní ìfojúsùn nínú àti lórí Olùgbàlà ó sì nmú wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ kí a sì ní ìgboyà pípé nínú agbára Rẹ̀ láti gbà wá là kúrò lọ́wọ́ ikú, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó sì bùkún wa pẹ̀lú okun kọjá ti ara wa.

Mórónì jẹri pé, “Àti nitori ìràpadà ènìyàn, èyítí ó wá nípasẹ̀ Jésù Krístì, a mú wọn padà wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa; bẹ̃ni, nípa èyí ní a ra gbogbo ènìyàn padà, nítorípé ikú Krístì mú àjíndé wá sí ìmúṣẹ, èyítí ó sì mú ìràpadà kuro nínú õrun àìnípẹ̀kun wa sí ìmúṣe, nínú õrun èyíti gbogbo ènìyàn yíò jínde nípa agbara Ọlọ́run nígbàtí ìpè nã yíò dún; wọn yíò sì jáde wa, àti èyítí ó kere àti èyítí ó tóbi, gbogbo wọn ní yíò sì dúró ní iwájú ìdájọ́ rẹ̀, nítorípé á ti rà á padà a sì ti túu sílẹ̀ kuro nínú ìdè ikú ayérayé, ikú èyítí íṣe ikú ti ara” (Mọ́mọ́nì 9:13).

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Olùgbàlà ti já ìdè ikú. O jínde, Ó wà láàyé, Òun sì ni orísùn yíyè, rere, àti ìrètí dídára púpọ̀ kanṣoṣo.

Ìdákọ̀ro kan sí Ẹ̀mí

Wòlíì Ẹ́térì jẹri pé, “Nítorí èyí, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run lè ní ìrètí dájúdájú fún ayé tí ó dára jù, bẹ̃ni, àní àyè ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, ìrètí èyítí nwá nípa ìgbàgbọ́, tí ó sì nrọ̀mọ́ ọkàn ènìyàn, èyítí yíò mú wọn dúró gbọingbọin àti ní ìdúróṣínṣin, tí wọn sì kún fún iṣẹ́ rere ní gbogbo ìgbà, tí a sì darí wọn láti yìn Ọlọ́run lógo” (Ẹ́térì 12:4; àtẹnumọ́ àfikún).

Ní àkokò pàtàkì ti ṣíṣe ayẹyẹ ìbí ti ọmọ-ọwọ́ yí ní Bẹ́thlẹ́hẹ́mù, njẹ́ kí a rántí nígbàgbogbo pé Jésù Krístì wá sínú ayé láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ó fún wa ní àwọn ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí àìlóye ti ìyè, ìmọ́lẹ̀, ìsọdọ̀tun, ìfẹ́, àláfíà, ìrísí, ayọ̀, àti ìrètí.

Mo pè yín láti wá ẹ̀bùn ti-ẹ̀mí títọ́ ti ìrètí nínú Olùgbàlà nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìkọ́ni àti ijẹri ti àwọn wòlíì àtijọ́ àti òde-òní nípa ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ àti Àjínde bí ó tirí. Bí ẹ ti nṣe bẹ́ẹ̀, mo ṣe ìlérí pé ẹ̀rí yín nípa àtọ̀runwá Olùràpadà yíò gba okun, ìyípada ọkàn yín yíò jinlẹ̀ si, ìfẹ́-inú yín àti ìpinnu láti dúró bí akọni ajẹri nípa Rẹ̀ yíò pọ̀ si, ẹ ó sì di alábùkúnfún pẹ̀lú ìrọ̀mọ́ sí ọkàn yín—àní yíyè, rere, àti ìrètí dídára púpọ̀.

Pẹ̀lú àwọn Àpóstélì tí wọ́n ti jẹri nípa Rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, mo fi pẹ̀lú ayọ̀ kéde ẹ̀rí mi pé Jésù Krístì ni alààyè Ọmọ Ọlọ́run alààyè. Òun ni ológo olùjínde Olùràpadà pẹ̀lú àgọ́ ara, ẹran ara àti àwọn egungun. Àti nítorí ìràpadà àti ìlàjà pẹ̀lú Ọlọ́run tí Olúwa mú ṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn, a lè gba ìdánilójú ti-ẹ̀mí àti yíyè, rere, àti ìrètí dídára púpọ̀ “nínú Krístì ni a ó sọ di yíyè” (1 Kọ́ríntì 15:22).

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ẹbí Náà: Ìkéde Kan Sí Àgbáyé,” Ibi Ìkàwé Ìhìnrere.