“Ìdarí nípasẹ̀ àwọn Wòlíì Alààyè,” Làìhónà, Oṣù Kẹsan 2022.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kesan 2021
Ìdarí nípasẹ̀ àwọn Wòlíì Alààyè
Àwọn wòlíì ni àwọn ọkùnrin tí a pè láti ọwọ́ Baba Ọ̀run láti sọ̀rọ̀ fún Un. Wọ́n njẹri nípa Jésù Krístì wọ́n sì nkọ́ni ní ìhìnrere Rẹ̀. Àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gbàgbọ́ nínú méjèèjì àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní.
Ọlọ́run Nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn Wòlíì
Àwọn wòlíì ngba ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nígbàtí àwọn wòlíì bá ní ìmísí láti kọ́ wa, ó jẹ́ ìkannáà bíi pé Ọlọ́run nbá wa sọ̀rọ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:38). A lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé wọ́n nsọ̀ ohun tí Ọlọ́run nfẹ́ kí a mọ̀ fún wa.
Mórónì Nṣe Àkékúrú Àwọn Àwo, láti ọwọ́ Tom Lovell
Àwọn Wòlíì Kọ́ni Nípa Jésù Krístì
Gbogbo àwọn wòlíì jẹri nípa Jésù Krístì. Wọ́n kọ́ wa pé Òun ni Ọmọ Ọlọ́run. Wọ́n kọ́ wa nípa ayé, àpẹrẹ, àti Ètùtù Rẹ̀. Wọ́n sì nfi hàn wá bí a ó ṣe tẹ̀lé E tí a ó sì gbọ́ran sí àwọn òfin Rẹ̀.
Àwọn Ojúṣe àwọn Wòlíì
Àwọn wòlíì nkọ́ni ní ìhinrere Jésù Krístì. Wọ́n nṣe àlàyé àwọn ìbùkún tí a ngbà nígbàtí a bá gbọ́ran sí àwọn òfin àti àwọn àbájáde tí à ngbà bí a kò bá ṣeé. Ní ìgbàmíràn, wọ́n lè ní ìmísí láti sọ fún wa nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú.
Mósè àti àwọn Tàbìlì, láti ọwọ́ Jerry Harston
Àwọn Wòlíì Àtijọ́
Ọlọ́run ti kọ́ àwọn ènìyàn nípasẹ̀ àwọn wòlíì làti ìbẹ̀rẹ̀. Nínú àwọn wòlíì tí wọ́n gbé ní ìgbà Májẹ̀mú Láéláé ni Ádámú, Nóàh, Ábráhámù, Mósè, Ìsàíàh, àti àwọn míràn. Àwọn wòlíì wà bákannáà ní àárín àwọn ènìyàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Nínú àwọn wòlíì wọ̀nyí ni Léhì, Mòsíàh, Álmà, àti Mórónì. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ ohun tí wọ́n kọ́ni nípa kìka àwọn ìwé-mímọ́.
Àwọn Wòlíì Òde Òní
Joseph Smith ni wòlíì àkọ́kọ́ ní ìgbà òde-òní. Ó mú Ìjọ Jésù Krístì padàbọ̀sípò sí ilẹ̀-ayé. Russell M. Nelson ni wòlíì àti Ààrẹ Ìjọ ní òní. Àwọn olùdámọ̀ràn Rẹ̀ nínú Àjọ Ààrẹ Kínní àti àwọn Àpóstélì Méjìlá jẹ́ àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihànbákannáà.
Fífetísílẹ̀ sí àwọn Wòlíì
Wòlíì nbá wa sọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò àti ní àwọn ìgbà míràn. Ó nkọ́ wa ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí a mọ̀ àti bí a ó ṣe tẹ̀lé Jésù Krístì ní òní. A lè rí àwọn ìkọ́ni rẹ̀ nínú Làìhónà àti ní ChurchofJesusChrist.org.
Àwọn Ìbùkún ti Títẹ̀lé Wòlíì
A ó di alábùkún-fún bí a bá tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni ti wòlíì. Nígbàtí a bá tẹ̀lé wòlíì, a lè mọ̀ pé à nṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí a ṣe. A lè ní ìmọ̀lára àlááfíà nínú ayé wa kí a sì súnmọ́ Jésù Krístì si.
© 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọrọ Oṣoòṣù Lìàhónà, Oṣù Kẹsan 2022. Yoruba. 18299 779