“Páùlù Ronúpìwàdà,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kéje 2021
“Páùlù Ronúpìwàdà”
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, ,Oṣù Kéje (Agẹmọ) 2021
Páùlù Ronúpìwàdà
Àwọn Iṣe Àpóstélì 9:1–22; 13:9
Lẹ́hìn tí Jésù kú, àwọn ọmọẹ̀hìn tẹramọ́ kíkọ́ àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ènìyàn ní ó fẹ́ràn ohun tí wọ́n kọ́ni. Ọkùnrin kan tí a pè ní Páùlù burú sí àwọn ẹni tí ó ntẹ̀lé Jésù.
Ní ọjọ́ kan nígbàtí Páùlù nrin ìrìnàjò, ó rí ìmọ́lẹ̀ dídán láti ọ̀run. Ó gbọ́ ohùn Jésù! Jésù wí fún Páùlù kí ó ronúpìwàdà kí ó sì tẹ̀lé Òun.
Ìmọ́lẹ́ dídán náà mú kí Páùlù fójú. Ọkùnrin mímọ́ kan tí a pè ní Ananias wo àwọn ojú Páùlù sàn. Páùlù yàn láti ṣe ìrìbọmi.
Lẹ́hìn ìyẹn, Páùlù kọ́ àwọn ènìyàn nípa Jésù Krístì. Ó jẹ́ ìránṣẹ́ ìhìnrere, olùkọ́ni, àti olórí nlá nínú Ìjọ Krístì.
Mo lè yàn láti jẹ́ onínúrere dípò jíjẹ́ ẹni búburú. Mo lè fi ìgbàgbogbo yàn láti tẹ̀lé Jésù.
Kíkùn Ojú-ewé
Páùlù Ti Wo Jésù
© 2021 by Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ètọ́ ni a fi pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀pada-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ́ndì Oṣooṣù, Oṣù Kéje 2021. Yoruba 17471 000