2021
Gbọ́, Fetísílẹ̀, sì Gbọ́ran
Oṣù Kínní (ṣẹrẹ) 2021


“Gbọ́, Fetísílẹ̀, sì Gbọ́ran,” Fún Òkún àwọn Ọ̀dọ́, Jan. 2021, 32.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Ìkínní (ṣẹrẹ) 2021.

Gbọ́, Fetísílẹ̀, sì Gbọ́ran

Fífetísílẹ̀, kíkà, sísọ̀rọ̀ lórí pẹpẹ

Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Guev Design

Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ gan nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú ni fetísílẹ̀ (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 1:1). Ó túmọ̀ sí “láti fetísílẹ̀ pẹ̀lú èrò láti gbọ́ràn.” Láti fetísílẹ̀ túmọ̀ sí láti “gbọ́ Tirẹ̀“—láti gbọ́ ohun tí Olùgbàlà sọ àti láti gbọ́ràn sí ìmọ̀ràn Rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ méjì wọnnì— “Gbọ́ Tirẹ̀“—Ọlọ́run fún wa ní àwòṣe fún àṣeyege, ìdùnnú, àti ayọ̀ ní ayé yí. A níláti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa, fetísílẹ̀ sí wọn, àti gbọ́ràn sí ohun tí Ó ti sọ fún wa!

Níbo ni a lọ láti gbọ́ Ọ?

A lè lọ sínú àwọn íwé mímọ́. Bákannáà a lè gbọ́ Tirẹ̀ nínú tẹ́mpìlì. Bákannáà a ngbọ́ Tirẹ̀ yékéyéké síi bí a ti ntún agbára wa ṣe láti ṣe ìdámọ̀ ìṣínilétí ti Ẹ̀mí Mímọ́. Àti, ní òpin, a lè gbọ́ Tirẹ̀ bí a ṣe ngbọ́ràn sí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn.

Kínni yíò ṣẹlẹ̀ bí ẹ ti nmọ̀ọ́mọ̀ gbọ́, fetísílẹ̀, tí ẹ sì ngbọ́ràn sí ohun tí Olùgbàlà ti sọ àti ohun tí Ó nsọ báyìí nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀? Mo ṣèlérí pé ẹ ó di alábùkún fún pẹ̀lú àlékún agbára láti dojúkọ àdánwò, àwọn ìlàkàkà, àti àìlera. Mo ṣèlérí àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí àti iṣẹ́ yín ojoojúmọ́. Mo sì ṣèlérí pé agbára yín láti ní ìmọ̀lára ayọ̀ yíò pọ̀ si àní bí èwu tilẹ̀ pọ̀ si nínú ìgbé ayé yín.