Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2025
Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé mo ti ronúpíwàdà nítòótọ́ àti pé a ti dáríjì mí?
Wíwà ní Àyíká Kíkún, láti ọwọ́ Jenedy Page
Olúwa ti wí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, òun náà ni a ti dáríjì, àti pé èmi, Olúwa, kò rántí wọn mọ́.
“Nípa èyí ni ẹ̀yin lè mọ̀ bí ẹnìkan bá ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ẹ kíyèsíi, òun yíò jẹ́wọ́ wọn yíò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 58:42–43).
Nípa ìrònúpìwàdà àtọkànwá, a lè gba ìdáríjì. “Nígbàtí o bá ní ìmọ̀lára ìtùnú láti ọ̀dọ̀ ẹ̀mí, o lè mọ̀ pé agbára ètùtù ti Olùgbàlà nṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé rẹ.” Àti pé tí a bá tún yọ̀ kúrò, a tún lè ronúpìwàdà, gba ìdáríjì, kí a sì máa gbìyànjú síwájú síi.
Ní àfikún, Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá ti kọ́ni pé: “Sátánì yíò máa gbìyànjú láti mú wa gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kò ní ìdáríjì nítorí àwa lè rántí wọn. Òpùrọ́ ni Sàtánì. … Ọlọ́run kò ṣèlérí pé a kò ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Rírántí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àwọn àṣìṣe kannáà lẹ́ẹ̀kan síi. Ṣùgbọ́n tí a bá dúró ní òtítọ́ àti lódodo, ìrántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa yíò rọlẹ̀ ní ákókò.”
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2025. Yoruba. 19629 779