2025
Ìran Ìkínní
Oṣù Kejìlá 2024


“Ìran Ìkínní,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2025, 26–28.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kínní 2025

Ìran Àkọ́kọ́

Ẹ le ka ìtàn yí nínú Ìwé-ìtàn—Josèph Smith 1:1–20.

Joseph Smith nwo ọkùnrin kan tí ó nwààsù sí ẹgbẹ́ kan

Nígbàtí Joseph Smith wà ní ọ̀dọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọ kọ́ni ní àwọn ohun tó yàtọ̀ nípa Jésù Krístì. Joseph kò mọ ìjọ èyíti yío dárapọ̀ mọ́.

Joseph Smith nka Bíbélì

Ní ọjọ́ kan, ó ka James 1:5 nínú Bíbélì. Ó wípé bí a bá nílò ọgbọ́n, a lè bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Joseph pinnu láti ṣe èyí.

Joseph Smith nrìn lọ sínú àwọn igi

Ní ọjọ́ rírẹwà kan ní ìgbà ìrúwé, Joseph lọ sínú àwọn igi láti gbàdúrà sí Baba Ọ̀run.

Joseph Smith ngbàdúrà

Joseph kúnlẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà. Ṣùgbọ́n nígbànáà ó ní ìmọ̀lára òkùnkùn ní gbogbo àyíká rẹ̀. Ẹ̀rù bà Joseph. O bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.

Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì nfi ara hàn sí Joseph Smith

Lójijì, Joseph rí ìmọ́lẹ́ dídán kan tí ó nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó rí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì tí wọ́n dúró lórí afẹ́fẹ́. Baba Ọ̀run pe orúkọ Joseph. Nígbànáà Ó nawọ́ sí Jésù Krístì ó sì wípé, “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!”

Jésù Krístì

Jésù wí fún Joseph pé kò gbọdọ̀ darapọ̀ mọ́ eyikeyi nínú àwọn ìjọ náà.

Joseph Smith kúnlẹ̀ ó sì nwo òkè

Joseph yíò ṣèrànwọ́ mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere padàbọ̀sípò sórí ilẹ̀-ayé.

Joseph Smith nrẹrin ó sì nkúrò nínú àwọn igi

Joseph kò ní ìyọnu mọ́. Ó kún fún ayọ̀! Ó mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn òun. Àwọn ènìyàn kan kò gbàgbọ́ pé òun ti rí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́.

Kíkun Ojú-ewé

Baba Ọ̀run Ngbọ́ ó sì Ndáhùn àwọn Àdúrà Mi

Ojú-ewé kíkùn ti Ìran Ìkínní

Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert

Baba Ọ̀run dáhùn àdúrà Joseph Smith. Òun yíò dáhùn tiyín pẹ̀lú!