“Ìran Ìkínní,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2025, 26–28.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kínní 2025
Ìran Àkọ́kọ́
Ẹ le ka ìtàn yí nínú Ìwé-ìtàn—Josèph Smith 1:1–20.
Nígbàtí Joseph Smith wà ní ọ̀dọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọ kọ́ni ní àwọn ohun tó yàtọ̀ nípa Jésù Krístì. Joseph kò mọ ìjọ èyíti yío dárapọ̀ mọ́.
Ní ọjọ́ kan, ó ka James 1:5 nínú Bíbélì. Ó wípé bí a bá nílò ọgbọ́n, a lè bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Joseph pinnu láti ṣe èyí.
Ní ọjọ́ rírẹwà kan ní ìgbà ìrúwé, Joseph lọ sínú àwọn igi láti gbàdúrà sí Baba Ọ̀run.
Joseph kúnlẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà. Ṣùgbọ́n nígbànáà ó ní ìmọ̀lára òkùnkùn ní gbogbo àyíká rẹ̀. Ẹ̀rù bà Joseph. O bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.
Lójijì, Joseph rí ìmọ́lẹ́ dídán kan tí ó nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó rí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì tí wọ́n dúró lórí afẹ́fẹ́. Baba Ọ̀run pe orúkọ Joseph. Nígbànáà Ó nawọ́ sí Jésù Krístì ó sì wípé, “Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!”
Jésù wí fún Joseph pé kò gbọdọ̀ darapọ̀ mọ́ eyikeyi nínú àwọn ìjọ náà.
Joseph yíò ṣèrànwọ́ mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere padàbọ̀sípò sórí ilẹ̀-ayé.
Joseph kò ní ìyọnu mọ́. Ó kún fún ayọ̀! Ó mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ràn òun. Àwọn ènìyàn kan kò gbàgbọ́ pé òun ti rí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́.
Kíkun Ojú-ewé
Baba Ọ̀run Ngbọ́ ó sì Ndáhùn àwọn Àdúrà Mi
Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert
Baba Ọ̀run dáhùn àdúrà Joseph Smith. Òun yíò dáhùn tiyín pẹ̀lú!
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2025. Yoruba. 19632 779