Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Lẹ́hìn Àwọn Àṣìṣe Yín—Àní Àwọn Títóbi Náà
Oṣù Kẹrin 2026


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹrin 2026

Lẹ́hìn Àwọn Àṣìṣe Yín—Àní Àwọn Títóbi Náà

A lè kọ́ púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ Àpóstélì Pétérù nípa Olùgbàlà, Ètùtù Rẹ̀, kí a sì gbíyànjú lẹ́ẹ̀kansi.

Pétérù nsẹ́ Krístì

Sísẹ́ Pétérù, láti ọwọ́ Carl Bloch

Púpọ̀jù lára wa ó kéréjù ti ṣe ìrántí kan tí a lérò pé a lè gbàgbé pátápátá. Bóyá ó jẹ́ àkokò kan nípa ìtinilójú kedere, ìrora ìjámbá ti ara kan, tàbí àríyànjiyàn kan nígbàtí ẹ sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ lérò pé ẹ lè mú padà, àwọn ìgbà púpọ̀ wà nínú ayé nígbàtí à “nṣe-àṣejù” tàbí pàápàá ìró bọ́tìnì “píparẹ́” kan tí ó dùnmọ́ni gidigidi.

Ìmúṣẹ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìkorò Kan

Àpóstélì Pétérù jẹ́ ẹni kan tí ó fanimọ́ra nínú Májẹ̀mú Titun Ó ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà láti rìn lórí omi síwájú Jésù, ṣùgbọ́n àwọn àkokò péré lẹ́hìnnáà ó fi ààyè gba àwọn ẹ̀rù rẹ̀ láti borí rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀sí rì, ó kígbe jáde sí Olúwa fún ìrànlọ́wọ́ (wo Màttéù 14:28–31). Nígbàtí a kò mọ gbogbo àlàyé kíníkíní ìgbé ayé Pétérù, a mọ̀ àkokò kan nígbàtí ó sọkún kíkorò.

Ní àwọn wákàtí kan ṣíwájú kí a tó mú Jésù Krístì, Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Pétérù yíò sẹ́ Òun ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ṣíwájú kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì. Pétérù kọ̀ láti gbàgbọ́ irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ó sì “sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àtẹnumọ́ púpọ̀, Bí ó tilẹ̀ di àti bá ọ kú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ bí ó ti wù kí ó rí” (Marku 14:31).

Bẹ́ẹ̀ni, àsọtẹ́lẹ̀ Olùgbàlà padà di òtítọ́. Pẹ̀lú ojo àti ẹ̀rù tí ó yí mímú Olúgbàlà ká, ìgboyà Pétérù mú u kùnà. Lẹ́hìn tí ó ti sẹ tẹ́lẹ̀ pé òun mọ Olùgbàlà lẹ́ẹ̀mejì, tíwọ́n sì ntẹ̀ẹ́ ní ẹ̀ẹ̀kẹ́ta, Pétérù “bẹ̀rẹ̀ láti gẹ́gun àti láti búra, ó wípé, èmi kò mọ ọkùnrin yí ẹnití ẹ̀ nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀” (Márkù 14:71).

Nígbàtí àkùkọ kọ lẹ́ẹ̀mejì tí Pétérù sì rántí àsọtẹ́lẹ̀ Olùgbàlà, “ó … sọkún kíkorò” (Máttéù 26:75).

Ṣùgbọ́n ìyẹn kọ́ ni òpin ìtàn rẹ̀!

Igun Kan Yípo, Títíláé

Nípasẹ̀ ohun gbogbo a lè kọ́ ẹ̀kọ́ nínú àwọn ìwé mímọ́, ẹ̀rù Pétérù kò borí ẹ̀rí rẹ̀ nípa Jésù Krístì lẹ́ẹkansi mọ́ láé. Ó jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ìgboyà nípa Olùgbàlà ní gbogbo ànfàní, bí ó ti wù kí ewu araẹni náà rí ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ rántí, Pétérù nkọ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ṣẹ̀ kan Jésù Krístì mọ́ àgbélèbú! Ewu náà jẹ́ òdodo.

Nígbàtí Pètérù wo ọkùnrin arọ kan láti ìbí sàn, ó pàṣẹ fun, “Ní orúkọ Jésù Krístì ti Násárẹ́tì dìde kí o sì máa rìn” (Ìṣe àwọn Àpóstélì 3:6), a mú u lẹgbẹ pẹ̀lú Jòhánnù wọ́n sì bií léère bí ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu yí.

Pétérù fi pẹ̀lú ìgboyà dáhùn, “Kí èyí kí ó yé gbogbo yín, àti gbogbo ènìyàn Ísráẹ́lì, pé nípa orúkọ Jésù Krístì ti Násárẹ́tì, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélèbú, tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yí fi dúró níwájú yín ni dídá ara ṣáká.

“Èyí ni òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé. Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn: nítorí kò sí orúkọ míràn lábẹ́ ọ̀run tí a fi fúnni nínú ènìyàn, nípa èyítí a lè fi gbà wá là” (Ìṣe àwọn Àpóstélì 4:10–12).

Irú ìdáhùn onígboyà kan! Àti ẹ̀rí kedere nípa àwọn ìdánilójú rẹ̀.

Àwọn Ìránṣẹ́ Àìpé, Lílè Sìn Ní Pípé

Ọ̀kọ̀ọ̀kan lárá wa ni yíò dẹ́ṣẹ́ nínú ayé yí. Pẹ̀lú àwọn ìtiraka wa jùlọ gan, a ó kùnà nípa àwọn ìrètí àti èrò-inú wa láti àkokò sí àkokò. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Jeffrey R. Holland (1940–2025), Ààrẹ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, kọ́ni nígbàkan, “Bíkòṣe nínú ọ̀ràn ti Ọmọ Bíbí Rẹ̀ pípé nìkanṣoṣo, àwọn àìpé ènìyàn jẹ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rí."

A kò túmọ̀ yíyẹ ti ẹ̀mí yín tàbí fi òpin si nípa àwọn àṣìṣe yín—àní àwọn títóbi wọnnì! Nítorí ó ronúpìwàdà àti pé Krístì dáríjì í, sísẹ́ Krístì ti Pétérù kò dẹ́kun rẹ̀ kúrò ní jíjẹ́ ẹ̀rí, kíkọ́ni, àti yíyínipadà pẹ̀lú agbára nlá lẹ́hìnwá. Àwọn ìwé mímọ́ kún fún àwọn àpẹrẹ ti àwọn ọmọẹ̀hìn míràn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, ronúpìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Krístì.

Sátánì yíò gbìyànjú nígbàgbogbo láti pàrọwà síi yín pé àwọn àṣìṣe yín npọ̀ si àti pé ẹ kò ní lè borí wọn. Ẹ pa àwọn irọ́ rẹ̀ tì!

Arábìnrin Tamara W. Runia, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, kọ́ni: “Ẹ nílò láti gbọ́ èyí, nítorínáà èmi ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí síta: Ẹ kìí ṣe ohùn náà ní orí yín tàbí àwọn àṣìṣe tí ẹ ti ṣe. Ẹ lè nílò láti sọ ìyẹn síta bákannáà. Ẹ sọ fún Sátánì, ‘Kìí ṣe òní.’ Ẹ fi í sí ẹ̀hìn yín.

“Ẹ ní ìmọ̀lára fífà náà, ìkorò tọ̀run tí ó nyí yín síwájú Olùgbàlà yín, kí ẹ sì wo oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tí nwọnú ayé yín àti ayé àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn. Mo ṣe ìlérí pé ní ìṣẹ́jú tí a bá mú ìrora-ọkàn pẹ̀lú ìgboyà wá síwájú Rẹ̀, Òun wà níbẹ̀ lọ́gán.”

Jésù Krístì

Christus Consolator, láti ọwọ́ Carl Bloch

Àwọn Ọjọ́ Dídán Níwájú

Ní àkokò Ọdún Àjínde yí, bí ẹ ti nṣe àròjinlẹ̀ Ètùtù Olùgbàlà síi ní kíkún, ẹ rántí pé okun láti ronúpìwàdà àti láti gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansi ni ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn títóbijùlọ tí ẹ lè gbà láé. Nítorí ti Jésù Krístì, àwọn àṣìṣe bíburújùlọ yín ni a lè dáríjì kí a sì jù sọnù bíi àwọn ẹ̀wọ̀n wíwúwo.

“Olùgbàlà dán ju òkùnkùn ìtìjú náà títíláé,” Arábìnrin Runia ti kọ́ni.

Nítorí ti Jésù Krístì, ìrètí lè tàn dídán nígbàgbogbo níwájú yín bí ẹ ti dúró nń ìdojúkọ Ọ́.