Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹta 2026
Ẹ́ksódù 12
Ìrékọjá Wa—Oúnjẹ Olúwa náà
Ìlà wíwọ́pọ̀ kan wà ní àárín Ìrékọjá àtijọ́ àti oúnjẹ́ Olúwa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ wa.
Ìjúwe láti ọwọ́ Alyssa Tallent
Kí àwọn ará Ísráẹ́lì àtijọ́ tó lè kúrò nínú ìgbèkùn ní Égíptì, a ní kí wọ́n gbọ́ran sí àwọn ìkọ́ni pàtó láti ọ̀dọ̀ Olúwa nítorí kí ángẹ́lì apanirun náà lè da wọn sí, tàbí kọjá lórí wọn (wo Ẹksódù 12). Lẹ́hìn tí wọ́n kúrò ní Égíptì, àwọn ará Ísráẹ́lì ṣe àkíyèsí àpèjẹ kan ní ọdọọdún, tí a pè ní Irékọjá, láti rántí bí Olúwa ṣe tú àwọn ènìyàn májẹ̀mú Rẹ̀ sílẹ̀.
Nínú ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní ayé ikú Rẹ̀, Jésù Krístì wà níbi oúnjẹ Ìrékọjá. A npe oúnjẹ náà ní Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn nisisìyí. Olùgbàlà lo ọ̀ràn náà láti fi ìlànà ti oúnjẹ Olúwa hàn, èyítí à nkópa nínú rẹ̀ nísisìyí ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (Wo Máttéù26:26–28; Lúkù22:19–20; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 20:77, 79.)
Ní ìhín ni àwọn ìlà méjì wíwọ́pọ̀ ní àárín Ìrékọjá àkọ́kọ́, Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn ti Olúwa, àti oúnjẹ́ Olúwa ní òní tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rántí ìtúsílẹ̀ wa nípasẹ̀ Olùgbàlà.
Búrẹ́dì náà
Ìrékọjá: Fún ọjọ́ méje, àwọn ará Ísráẹ́lì jẹ búrẹ́dì aláìwú (èyítí ó jẹ́ méjèèjì kíákíá láti ṣe àti dínkù sí kíkebu àti díbàjẹ́).
Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn: Jésù Krístì bùkún ó sí já búrẹ́dì aláìwú ti Ìrékọjá, Ó sì fi í fún àwọn ọmọẹ̀hìn náà. Ó wí fún wọn láti jẹ ẹ́ ní ìrántí ti ara Rẹ̀, èyítí Ó mọ̀ pé yíòjá láìpẹ́ tí yíò sì kú ṣùgbọ́n tí yíò dìde lẹ́ẹ̀kansi.
Oúnjẹ Olúwa: À njẹ búrẹ́dì ní ìrántí ara Jésù Krístì.
Jésù Krístì ni Búrẹ́dì Ìyè. Nípasẹ̀ Àjínde Rẹ̀, gbogbo wa ni yíò jínde pẹ̀lú ara àìkú pípé, àti àìdíbàjẹ́. Ó túwasílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ikú.
Ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn Náà
Ìrékọjá: Ọ̀dọ́-àgùtàn Ìrékọjá jẹ́ àìní-àbàwọ́n, ọkùnrin ọmọ ọdún ọ̀dọ́-àgùtàn. A paá, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó sì gba sínú abọ́ kan. Hyssop (àgbo kan) ni a ó rì sínú abọ́ náà a ó sì lòó láti tẹ́ ẹ̀jẹ̀ náà yíká òde ẹnuilẹ̀kùn ilé. Èyí ni àmì òde tí ó nfi àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa hàn láti di rírékọjá nípa ángẹ́lì apanirun kí wọ́n lè di títúsílẹ̀ kúrò nínú ìgbèkùn ní Égíptì.
Oúnjẹ́ Alẹ́ Ìkẹhìn: Jésù Krístì lo wáínì láti rọ́pò ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀. Òun wí fún àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti mu ú ní ìrántí ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀, èyítí yíò di títasílẹ̀ fún wọn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti bí ara májẹ̀mú titun kan.
Oúnjẹ́ Olúwa: À nmu omi ní ìrántí ẹ̀jẹ̀ Jésù Krístì.
Jésù Krístì ni Ọ̀dọ́-àgùntan Ọlọ́run. Ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀ ni a tasílẹ̀ bí Ó ti jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìlera wa. Ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀—ìrúbọ Rẹ̀—nwẹ̀ wá nù. Ó túwasílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2026. Yoruba. 19936 779