Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kejì 2026
Ṣe ẹ fẹ́ ní Inú Dídùn síi? Gbìyànjú Ìdúpẹ́
Nígbàtí ìgbésí ayé yín bá kún fún àwọn ìyípadà, ìmoore lè ṣèrànwọ́ fún yín láti dojúkọ ohun dídára àti láti dúró pẹ̀lú ìrètí.
Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Maggie Stephenson
“Ẹ̀yin kì yíò ní inú dídùn ju bí ẹ ti nní ìmoore lọ.”
Gẹ́gẹ́bí àyọkà yí láti ọwọ́ Alàgbà Gary B. Sabin ti Àádọ́rin dábàá, bí inú yín ṣe dùn tó ní ipa tààrà nípa bí ẹ ṣe nní ìmoore tó. Ó mọ́gbọ́n wa—nígbàtí ẹ bá ní ìmoore, ẹ dojúkọ àwọn ohun dídára dípò àwọn ohun òdì.
Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbé ayé kìí fìgbàgbogbo lọ bí a ti ṣètò. Àwọn ìyípadà àìròtẹ́lẹ̀ lè jẹ́ kí ó ní ìlàágùn, ìbànújẹ́, tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ju ìdùnnú lọ. Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn nkan bá le, ìmoore lè ṣèrànwọ́ fún yín láti dúró pẹ̀lú ìrètí. Gbìyànjú àwọn ọ̀nà mẹ́ta wọ̀nyí láti mú ìmoore wá síi sínú ìgbé ayé yín.
1. Ẹ wa Rere náà
Nígbàmíràn, ó nira jùlọ láti ní ìmoore nígbàtí ẹ bá lérò bí ẹ ṣe nṣàìní ohunkan. Ṣùgbọ́n àwọn ìbùkún wo ni ẹ lè máa fójú fò nípa kíkọjúsí ohun tí ẹ kò ní dípò ohun tí ẹ ní?
Bí ẹ ṣe nwá àwọn ohun dídára nínú ìgbé ayé yín, bí àkokò ṣe nlọ yíò di ìrọ̀rùn láti wá.
2. Fi Ìmoore hàn sí Olùfúnni
Nígbàtí ẹ bá ka àwọn ìbùkún yín, ẹ máṣe gbàgbé ibi tí wọ́n ti wá.
Dídúpẹ́ lọ́wọ́ Baba Ọ̀run fún àwọn ẹ̀bùn Rẹ̀—pẹ̀lú ẹ̀bùn Ọmọ Rẹ̀—le mú ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀ jinlẹ̀ síi. Ààrẹ D. Todd Christofferson, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Ààrẹ Ìkínní, tún ṣàlàyé pé, “Níní ìmọ̀lára àti fífi ìmoore hàn sí Ọlọ́run … nfún ìjọsìn ní ọgbọ́n àtúnṣe aláyọ̀,” tó nmú ayọ̀ àti agbára wá fún yín tí ó sì nran ẹ̀rí yín lọ́wọ́ láti wà ní ààbò.
3. Ẹ fojúsi Ètò Baba Ọ̀run
Ó hàn gbangba, níní ìmoore kò túmọ̀ sí ìpatì àwọn ohun líle ní ìgbé ayé tàbí ìmọ̀lára ìdùnnú ní gbogbo ìgbà. Àní Jésù Krístì ní ìmọ̀lára ó sì jẹ́wọ́ ìrora (wo Álmà 7:11; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 19:18–19). Ìbànújẹ́ jẹ́ apákan déédé ti ayé-ikú.
Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan kò yí padà láé: Ètò àánú ti Baba Ọ̀run. Gbogbo ìbànújẹ́ àti ìpalára tí ẹ ní ìrírí rẹ̀ nínú ayé ni a ó sọ di títọ́ nítorí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ (wo Ìfihàn 21:4).
Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá ṣe àlàyé: “Níní ìmoore ní àwọn àkokò ìrẹ̀wẹ̀sì kò túmọ̀ sí pé inú wa dùn sí àwọn ipò wa. Ó túmọ̀ sí pé nípasẹ̀ ojú ìgbàgbọ́, a nwo kọjá àwọn ìpèníjà ti òde òní.”
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejì 2026. Yoruba. 19935 779