2025
Kí la mọ̀ nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn nígbà Kérésìmesì àkọ́kọ́?
Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ Oṣù Kejìlá 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kejìlá 2025

Kí la mọ̀ nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn nígbà Kérésìmesì àkọ́kọ́?

ọ̀dọ́mọbìnrin

Àwọn Olùṣọ́ Àgùtàn, láti ọwọ́ Brian Call

A mọ àwọn nkàn díẹ̀ nípa àwọn olùṣọ́ àgùtàn nígbà Kérésìmesì àkọ́kọ́.

Wọ́n wà nítòsí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà wà “ní orílẹ̀-èdè kannáà” níbití wọ́n ti bí Kristi (Lúkù 2:8). Wọ́n sì lè fi ẹsẹ̀ dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà tí ó ṣì wà níbẹ̀ (wo Luke 2:15–16).

Wọ́n nṣe ojúṣe wọn. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí “ndúró ní pápá, wọ́n nṣọ́ agbo ẹran wọn ní òru” (Lúkù 2:8). Wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùtàn rere àti olùṣòtítọ́, bíiti Olùgbàlà—Olùṣọ́ Àgùntàn Rere (wo Jòhánnù 10:11, 14).

Wọ́n mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Mèssíàh náà. Ó hàn gbangba pé wọ́n mọ ohun tí ángẹ́lì náà nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó kéde ìbí “Kristi Olúwa” (Lúkù 2:11), Mèssíàh tí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nígbà àtijọ́.

Wọ́n ní ìtara nlá. Nígbàtí ángẹ́lì náà sọ fún wọn nípa “ọmọ-ọwọ́ … tó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran” (Lúkù 2:12), wọ́n lọ “pẹ̀lú ìyára” láti rí I (Lúkù 2:16).

Wọ́n pín ìhìnrere náà. Wọ́n “sọ di mímọ̀ ní òkèèrè” ohun tí wọ́n ti gbọ́ tí wọ́n sì rí nípa ọ̀rọ̀ ángẹ́lì náà nípa ìbí Kristi (Lúkù 2:17).

Wọ́n dúpẹ́ wọ́n sì yin Ọlọ́run. Lẹ́hìn gbogbo èyí, wọ́n “padà, wọ́n nyin Ọlọ́run lógo wọ́n sì ndúpẹ́ fún gbogbo ohun tí wọ́n ti gbọ́, tí wọ́n sì rí” (Lúkù 2:20).