Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹwa 2025
Kínìdí tí Olúwa fi ní Ìjọ kan?
Èrèdí Ìjọ Krístì ni “láti mú kí àwọn olúkúlùkù àti ẹbí lè ṣèrànwọ́ fún Ọlọ́run ní mímúṣẹ iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga Rẹ̀.” Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn nṣèrànwọ́ “láti mú àwọn ọmọ [Ọlọ́run] yege fún ipò gígajùlọ ti ògo, èyí tí ó jẹ́ ìgbéga tàbí ìyè ayérayé.”
“Olùgbàlà … pàṣẹ fún [Ìjọ] láti ṣe àṣeparí èrèdí Rẹ̀—wíwàásù ìhìnrere, fífúnni ní a`wọn ìlànà àti májẹ̀mú, àti mímu ṣeéṣe fún agbára Rẹ̀ láti dá wa láre a`ti láti yà wá sí mímọ́.”
Àwọn ọmọ Ìjọ ní àyè sí agbára Jésù Krístì àti àwọn ìbùkún nípasẹ̀ àṣẹ àti àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà, ìtọ́sọ́nà ti wòlíì, àwọn ìwé mímọ́, àti ìletò àwọn Ènìyàn Mímọ́.
Ìjọ bákannáà ni a ti pàṣẹ fún láti: “Ẹ dìde kí ẹ sì tàn dáradára, kí i`mọ́lẹ̀ yín ó lè jẹ́ òdiwọ̀n fún àwọn orílẹ̀-èdè” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 115:5).
Àwọn ọmọ Ìjọ ntiraka láti “tàn dáradára” nípa gbígbé ìhìnrere, pípe gbogbo ènìyàn láti gba ìhìnrere, dída ẹbí pọ̀ fún ayé àìlópin, àti ṣíṣe ìtọ́jú fún àwọn òtòṣì àti aláìní. Èyí ni iṣẹ́ ìgbàlà àti ìgbéga ti Ọlọ́run.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹwa 2025. Yoruba. 19624 779