Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹsan 2025
Jésù Krístì Wà fún àwọn Ọjọ́ Rere Pẹ̀lú
Nígbàtí àwọn nkan bá nlọ déédé, báwo ni a ṣe lè dúró ní fífojúsí Olúgbàlà? Ní ìhín ni àwọn èrò kan.
Ẹ ròó bí ọ̀rẹ́ kan bá nlo àkokò pẹ̀lú yín nìkan nígbàtí wọ́n bá nlàkàkà tí wọ́n sì nyẹra fún yín nígbàtí inú wọn bá dùn. Ìbáṣepọ̀ lílera? Kìí ṣe bẹ́ẹ̀.
Njẹ́ a ṣe èyí rí sí Olùgbàlà wa—wá A ní àwọn àkokò líle kí a sì gbàgbé Rẹ̀ ní àwọn àkokò rere?
À nsọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa bí Jésù Krístì ṣe nràn wá lọ́wọ́ nínú àwọn àkokò líle, bóyá nítorí gbogbo ènìyàn, ní àkokò kan tàbí òmíràn, ti o dojúkọ àwọn nkan líle.
Ṣùgbọ́n àwọn ọjọ́ kan—ọ̀sẹ̀ tàbí ọdún àní, bí a bá ní oríre—níbití àwọn nkan ti nlọ dáadáa lódodo. Nígbàmíràn a ngbàgbé Olùgbàlà ni àwọn àkokò wọnnì. Àwọn ènìyàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì ṣeé. Wọ́n ṣe rere látinú àwọn ìbùkún Ọlọ́run fún àkokò kan ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn wọ́n jákulẹ̀ sínú ìgbéraga nígbàtí wọ́n gbàgbé Rẹ̀.
Àwọn àkokò rere kò túmọ̀sí pé a kò nílò Jésù Krístì mọ́ lọ́gán. Àwọn àkokò ṣíṣerere ni àwọn àkokò pípé láti yọ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà, kìí ṣe láti gbàgbé Rẹ̀.
Nítorínáà báwo ni a ó ṣe dúró ní sísomọ́ Jésù Krístì àti Baba ní Ọ̀run nígbàtí àwọn àdánwò kò bá rán wá létí láti yípadà sí Wọn?
Dúró nínú Ìrẹ̀lẹ̀
Nígbàtí àwọn nkan bá nlọ dáadáa, ó dára láti ṣe ayẹyẹ àwọn ìbùkún àti àṣeyọrí yín. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe gbàgbé ẹnití ó mu ṣeéṣe fún yín láti wà níbi tí ẹ wà. Ọba Bẹ́njámínì sọ́ ní ọ̀nà yí nínú ìwàásù rẹ̀ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì:
“Nítori kíyèsíì, gbogbo wa kò ha íṣe alágbe bi? Njẹ́ a kìí ha gbẹ́kẹ̀lé Ẹní náà, àní Ọlọ́run, fún gbogbo ọrọ̀ tí a ní, fún oúnjẹ àti aṣọ, àti fún wúrà, àti fún fàdákà, àti fún gbogbo dúkìá tí a ní lóríṣiríṣi?” (Mòsíàh 4:19).
Jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nípa àṣeyege yín nípa rírántí ohun tí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ti ṣe fún yín ni ọ̀nà nlá láti fi Wọ́n sínú àwọn àkokò rere yín.
Ẹ Dúró nínú Ìmoore
Ìmoore ni ọ̀kan lára ẹ̀rọ̀ dídárajùlọ sí ìgbéraga àti gbígbàgbé. Dídúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run yíò ràn yín lọ́wọ́ láti rántí Rẹ̀ àti gbogbo ohun rere tí Òun àti Ọmọ Rẹ̀ ṣe nínú ayé yín. Èyí kàn jẹ́ dídára nínú àwọn àkokò rere bí ó ti jẹ́ nínú àwọn àkokò líle.
Ẹ Dúró ní Ìfura
Ọ̀kan lára ìkọlù dídùnmọ́ Sátànì jù ni láti “pàrọwà, àti láti tì [yín] lọ sínú ààbò ẹran ara” (2 Néfì 28:21). Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, òun yíò ní ìfẹ́ rẹ̀ bí ẹ bá nímọ̀lára ìtẹ́lọ́run gan àti ààbò nínú àwọn àkokò rere yín tí ẹ fi gbàgbé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ. Nítorínàá, ẹ máṣe gbàgbé Ọlọ́run! Nígbàtí ẹ bá dúró ní ìfura nípa ẹ̀tàn abẹ́lẹ̀ ti ọ̀tá tí ẹ sì kọ̀ wọ́n àní ní ìgbà àwọn àkokò rere yín, ẹ lè dúró súnmọ́ Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì.
Olùṣọ́-àgùtàn Rere, láti ọwọ́ Michael Malm
Ẹ Dúró Ní Oókan Krístì
Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “Nígbàtí ìfojúsí ti ìgbésí ayé wa bá wà lórí ètò ìgbàlà Ọlọ́run … àti Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ, a lè ní ayọ̀ láìkà ohun tó nṣẹlẹ̀ sí—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀—nínú ìgbésí ayé wa. Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ àti nítorí Rẹ̀. Òun ni orísun gbogbo ayọ̀.”
Báwo ni ẹ ṣe nronú ti òtítọ́ yí léraléra nípa ayọ̀ nígbàtí ìgbésí ayé bá nlọ dáradára? Èyí kìí ṣe àmọ̀ràn títuni-nínú nìkan nítorí ìgbà tí àwọn nkan bá nira. Ó jẹ́ òtítọ́ nígbàgbogbo, pẹ̀lú àwọn ọjọ́ dídárajùlọ yín. Nítorínáà gbogbo yín lè fojúsí Krístì, ní búburú àti rere.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹsan 2025. Yoruba. 19626 779