Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹta 2025
Báwo ni a ṣe le gbé nínú ayé kí a sì “gbé àwọn ohun ti ayé yìí sí ẹ̀gbẹ́ kan”?
Àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn Ẹnití Òun Ti Yàn, láti ọwọ́ Casey Childs
Olúwa ti wí pé, “Iwọ yío gbé àwọn ohun ti ayé yìí sí ẹ̀gbẹ́ kan, kí o sì lépa fún àwọn ohun ti ó dárajù” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 25:10). Èyí kò túmọ̀ sí pé a kò kọbi-ara sí àwọn ìnílò wa ti ara àti ti ayé, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé a kò gbé ọkàn wa lé ọrọ̀, agbára, ipò, tàbí ìtẹ́wọ́gbà ti aráyé. Níhin ni àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ díẹ̀ tí a ti kọ́wa nípa gbígbé nínú ayé:
Ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́. “Ẹ kọ́kọ́ lépa ìjọba Ọlọ́run, àti òdodo rẹ̀” (Máttéù 6:33). Nínú ọkàn wa àti ayé wa, àwọn òfin Ọlọ́run àti àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀ ni ó jẹ wá lógún jùlọ.
Ẹ lépa ẹ̀kọ́ kíkọ́ “Bí ẹ ti nkọ́ nípa ayé ní àyíká yín, ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ bákannáà nípa Olùgbàlà. … Bí ẹ bá ti nkọ́ ẹ̀kọ́ síi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó le ṣe ìrànlọ́wọ́ síi fún ìmúdàgbà ìjọba Ọlọ́run kí ẹ sì ní ipá lórí aráyé fún rere” (Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ́ni Kan fún Ṣíṣe Àwọn Yíyàn [2022], 31, 32).
Iṣẹ́ “Iṣẹ́ jẹ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì kan ti ìhìnrere. Ó nmú ìdàgbàsókè wá ó sì nmú wa gbèrú. … Kìí ṣe pé Olúwa fẹ́ kí a pèsè fún àwọn ẹbí wa nìkan ṣùgbọ́n láti fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ rere kan’ [Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 58:27]” (“Iṣẹ́ Ṣíṣe,” Àwọn Àkòrí àti Àwọn Ìbéèrè, Ibi Ìkàwé Ìhìnrere).
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹta 2025. Yoruba. 19628 779