Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kínní 2025.
Wo ọ̀dọ̀ Krístì
Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36
Àkórí fún àwọn Ọ̀dọ́ ní 2025 yíò ràn yín lọ́wọ́ láti yàn ìgbẹ́kẹ̀lé dípò iyèméjì àti ìgbàgbọ́ dípò ìbẹ̀rù.
Kailey ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ti wà nínú ẹgbẹ́ olùṣe-koríyá títí tí ìjàmbá kan fi jasí ìbàlọ́kànjẹ́ ìpalára ọpọlọ. Ìmúláradá rẹ̀ pa á mọ́ kúrò ní lílọ sí ilé-ìwé, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ní ìmọ̀lára pípatì àti dídánìkanwà. Ó làkàkà níti ẹ̀dùn ọkàn kò sì mọ ibití òun lè lọ fún ìrànlọ́wọ́. Ọ̀rẹ́ kan daba pé kí ó fetísílẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere. Wọ́n kọ́ ọ nípa Ètùtù ti Jésù Krístì. Kikọ́ ẹkọ síi nípa Krístì fún un ní ìrètí, ó sì ní ìmọ̀lára bí enipé Ọlọ́run Fúnrarẹ̀ nnawọ́ jáde sí i.
Kailey wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Èmi kò tíì ní ìmọ̀lára rí pé Ọlọ́run fẹràn mi. Ṣùgbọ́n nísisìyí mo mọ̀ pé Ó fẹràn mi.”
Ìyá rẹ̀, Michelle, ní ìyàlẹ́nu díẹ̀. Òun àti ọkọ rẹ̀, Brock, ti fi Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn sílẹ̀ nígbàtí Kailey wà ní ọdún méje nítorí oríṣiríṣí àwọn ìbèèrè, iyèméjì, àti àníyàn. Wọ́n lérò pé ọmọbìnrin wọn yíò ní inúdídùn síi láìsí gbogbo àwọn ìpàdé àti àwọn òfin. Wọn kò ròo rí lae pé àṣàyàn wọn yíò pa Kailey mọ́ kúrò ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí Michelle àti Brock ti nwò Kailey ti ó nyípadà, wọ́n damọ̀ pé ó ti tó ìgbà pípẹ́ tí wọ́n ti ní ìmọ̀lára sísúnmọ́ Ọlọ́run, àti pé wọ́n fẹ́ láti ní ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi.
Wọ́n pàdé pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù wọn, àti pé láìpẹ́ ẹbí náà, pẹ̀lú arákùnrin Kailey Braeden, padà sínú ìjọ. Níní ìmọ̀lára ìsúnmọ́ Ọlọ́run àti pípadà sopọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀—nípàtàkì nípasẹ̀ àdúrà—mú ìgbàgbọ́ wọn padàbọ̀sípò. Pípadà sí ìjọ kò yanjú gbogbo àwọn ìbèèrè tàbí àníyàn wọn, ṣùgbọ́n wọ́n damọ̀ pé níní ìsopọ̀ líle ti araẹni pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì jù àìgbàgbọ́ wọn lọ.
Gbogbo èyí bẹ̀rẹ̀ nígbàtí ọ̀rẹ́ kan—ọ̀dọ́mọdé bíi tiyín—pè Kailey láti wo ọ̀dọ̀ Krístì. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀!
Jésù Krístì ti wípé, “Ẹ máa wò ọ̀dọ̀ mí nínú gbogbo èrò inú; ẹ má ṣe iyèméjì, ẹ má bẹ̀rù” (Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 6:36). Èyí ni ìmísí tó wà lẹ́hìn Àkórí ti Àwọn Ọ̀dọ́ fún 2025. Ẹ gbà wá láàyè láti pín bí ẹ ti lè yan ìgbẹ́kẹ̀lé dípò iyèméjì àti ìgbàgbọ́ dípò ìbẹ̀rù bí ẹ ti nwo ọ̀dọ̀ Krístì:
Òsì sí ọ̀tún: Arábìnrin Runia, Ààrẹ Freeman, Arábìnrin Spannaus
Tamara W. Runia
Nígbàtí mò bá nlàkàkà, ó máa nrànmílọ́wọ́ nígbàgbogbo láti fi ojú inú wo Jésù Krístì pẹ̀lú àwọn ọwọ́ rẹ̀ ní nínà-jáde. Nígbàtí mo bá wo ọ̀dọ̀ Rẹ̀, mo máa nrántí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà, “Èmi Ó Rìn pẹ̀lú Jésù”: “Òun kò ní fi mí sílẹ̀ láé, àní nígbàtí mo bá ṣubú.”
Emily Belle Freeman
Nígbàtí mò nka ìwé-mímọ́ fún àkórí yí, a nrán mi létí Pétérù lórí Òkun Gálílì. Fífojúsùn lórí ìjì náà mú ìbẹ̀rù àti iyèméjì rẹ̀ pọ̀ si, tí ó mú kí ó rì sínú ìjì ìgbì-omi náà. Ṣùgbọ́n fífojúsùn lórí Olùgbàlà mu ṣeéṣe fún Un láti ṣe àṣeyọrí ohun kan tí óun kò ṣe rí ṣíwájú: ó rìn lórí omi! Ó jẹ́ ohun tó lápẹrẹ, lotitọ́. Kíni ẹ lè ṣe yọrí bí ẹ ti nwo ọ̀dọ̀ Rẹ̀?
Andrea Muñoz Spannaus
Nígbàtí mo bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmọ̀lára ẹ̀rù, láìka ibití mo wà tàbí irú ipò tí mo wà sí, mo máa nmọ̀ọ́mọ̀ ronú nípa ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. Mo máa ntunsọ ní inú mi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pé: ÈMI NI ỌMỌBÌNRIN ỌLỌ́RUN. Mo máa ntẹ̀síwájú láti ṣe èyí títí èmi ó fi bẹ̀rẹ̀ sí nní ìmọ̀lára dídárajù. Ó nṣiṣẹ́ nígbàgbogbo!
Òsì sí ọ̀tún: Arákùnrin Wilcox, Ààrẹ Lund, Arákùnrin Nelson
Bradley R. Wilcox
Bèèrè lọ́wọ́ ararẹ ẹnití ó ṣàníyàn nípa áti tí ó fẹràn rẹ jùlọ. Njẹ́ àwọn òbí àti olórí Ìjọ yín ni bí? Njẹ́ àwọn ènìyàn lórí ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ fún ẹnití ẹ kàn lè jẹ́ nọ́mbà kan ni bí? Wo ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run àti Krístì. Wọ́n nṣe àbojútó nítòótọ́!
Steven J. Lund
Ẹ rántí ohun tí a rán yín létí rẹ̀ nígbàtí ẹ bá nka àwọn àkórí ti Iyejú Oyè-àlùfáà Arọ́nì àti ti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin: Ẹyin jẹ́ àyànfẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ọlọ́run. Ẹ ní ìgbàgbọ́ pé Baba wa ní ètò fún yín. Wíwo ọ̀dọ̀ Krístì túmọ̀ sí rírì pé Ètùtù Rẹ̀ ni ó wà ní oókan ètò náà.
Michael T. Nelson
Kíka àwọn ìwé-mímọ́ jẹ́ wíwo ọ̀dọ̀ Krístì! Àwọn ìyèméjì àti ìbẹ̀rù máa nparẹ́ kúrò ní àdánidá bí a ti nrántí àwọn iṣẹ́-ìyanu àti ìkọ́ni Jésù. A ní oríre gan láti ní àyè sí àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Wọ́n wúlò ní gbogbo ìpò tí a nní ìrírí nínú ìgbésí-ayé wa.
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Ìkínní 2025.. Yoruba. 19615 779