“Àjọ Ìrékọjá,” Fríẹ́ndì Oṣù Kẹ́rin 2026, 46–48.
Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹ́rin 2026
Àjọ Ìrékọjá
Mósè lọ bá Fáráò ó sì ní kí ó fún àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì ní òmìnira kúrò lẹ́rú. Fáráò kọ̀. Olúwa rán àjàkálẹ̀-àrùn sí Égípítì, ṣùgbọ́n Fáráò sọ pé rárá síbẹ̀.
Olúwa wípé Òun yíò rán àjàkálẹ̀-àrùn tó kẹ́hìn Àkọ́bí ọmọ gbogbo ẹbí ní Égípítì yíò kú. Ṣùgbọ́n bí àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì bá tẹ̀lé àwọn àṣẹ Rẹ̀, àjàkálẹ̀-àrùn náà yíò ré wọn kọjá.
Olúwa sọ fún àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì láti rúbọ ọ̀dọ́-àgùtàn abo pípé kan kí wọ́n sì kun ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùtàn náà sí òkè ẹnu-ọ̀nà wọn.
Àjàkálẹ̀ àrùn náà wá. Gbogbo àkọ́bí àwọn Égípítì kú, pẹ̀lú ọmọkùnrin Fáráò. Ṣùgbọ́n àkọ́bí àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì ni a gbàlà nítorí wọ́n gbọ́ran sí Olúwa.
Fáráò wí fún Mósè àti àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì láti fi Égípítì sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Fáráò bínú. Òun àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sáré lé wọn.
Àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì tẹ̀dó sí Òkun Pupa. Nígbà tí wọ́n rí àwọn Égípítì tí wọ́n nbọ, ẹ̀rù bà wọ́n. Mósè wípé Olúwa yíò dá ààbò bò wọ́n.
Mósè gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, Olúwa sì la òkun náà. Àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì sọdá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀.
Nígbàtí àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì ti wà láìsí ewu ní ẹ̀gbẹ́ kejì òkun, omi náà padà sílẹ̀ ó sì ri àwọn ọmọ-ogun náà. Àwọn Ọmọ Ísráẹ́lì sì ní òmìnira níkẹhìn.
Ojú-ewé Kíkùn
Jésù Krístì Ti Jínde fún Mi
Ìjúwe láti ọwọ́ Audrey Day. A lè ṣe ẹ̀dà fún lílò Ìjọ nìkan.
Kíni ẹ lè ṣe láti rántí Jésù Krístì ní Ọdún Àjínde yí àti ní gbogbo ọdún?
© 2026 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Fríẹ́ndì Oṣooṣù, Oṣù Kẹ́rin 2026. Yoruba.. 20062 779