Fríẹ́ndì
Mósè Wòlíì náà
Fríẹ́ndì Oṣù Kẹta 2026


“Mósè Wòlíì náà,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹ́ta 2026, 46–48.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2026

Mósè Wòlíì náà

Mósè nínú aṣọ Égíptì tí ó nwo ara Égíptì kan tí ó nfìyà jẹ ẹrú ara Ísráẹ́lì kan

Mósè jẹ́ ará Ísráẹ́lì, ṣùgbọ́n a tọ́ ọ nípasẹ̀ ọmọbìnrin Fáráò ní Égíptì. Mósè banújẹ́ pé ará Égíptì burú sí àwọn ará Ísráẹ́lì wọ́n sì mú wọn ṣe ẹrú wọn.

Mósè pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀  yíká ẹrú ará Ísráẹ́lì kan, tí ó ntìí lẹ́hìn

Ní ọjọ́ kan Mósè rí ará Égíptì kan tí ó nlu ará Ísráẹ́lì kan. Mósè gbèjà ará Ísráẹ́lì náà.

Mósè dánìkànwà nínú aginjù

Nígbàtí Fáráò mọ̀, ó nfẹ́ láti pa Mósè, ṣùgbọ́n Mósè sá kúrò ní Égíptì.

Mósè pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀

Mósè wá sí ibi kan tí a pè ní Mídíánì, níbití ó ti pàdé obìnrin kan tí a pè ní Zipporah. Wọ́n ṣe ìgbéyàwó wọ́n sì ní àwọn ọmọ.

Mósè ní rírí Olúwa nínú igbo jíjó

Nígbàtí ó ngbé ní Mídíánì, Mósè rí igbó kan tí ó njóná, ṣùgbọ́n tí iná kò jó ìgbó náà. Olúwa farahàn nínú iná náà ó sì sọ̀rọ̀ sí Mósè.

Olúwa nsọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mósè

Olúwa wípé Òun mọ pé ará Ísráẹ́lì njìyà ní Égíptì. Ó pàṣẹ fún Mósè láti padà sí Égíptì àti láti sọfún Fáráò láti jẹ́ kí àwọn ará Ísráẹ́lì lọ ní òmìnira. Olúwa wípé Òun yíò ran Mósè lọ́wọ́ láti fún àwọn ara Ísráẹ́lì ní òmìnira kí ó sì darí wọn lọ sí ilẹ̀ ìlérí.

Ojú-ewé Kíkùn

Èmi Lè Ṣe Rere sí àwọn Ẹlòmíràn

Ojú-ewé kíkun PDF

Ìjúwe láti ọwọ́ Audrey Day A lè ṣe ẹ̀dà fún lílò Ìjọ nìkan.

Kíni ẹ lè ṣe ní ọ̀sẹ̀ yí láti jẹ́ rere?