“Nóà àti Ọkọ̀ náà,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2026, 46–48.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kejì 2026
Nóà àti Ọkọ̀ náà
Nóà àti ẹbí rẹ̀ gbọ́ran sí Olúwa. Gbogbo àwọn ènìyàn tó kù jẹ́ ẹni búburú. Olúwa sọ fún Nóà pé ìkún omi yíò borí ilẹ̀-ayé tí àwọn ènìyàn náà kò bá ronúpìwàdà.
Nóà sọ fún àwọn ènìyàn náà pé Olúwa fẹ́ràn wọn àti pé ó fẹ́ kí wọ́n ronúpìwàdà kí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì. Wọn kò ní fetísílẹ̀.
Olúwa sọ fún Nóà kí ó kan ọkọ̀-omi nlá tí a pè ní ọkọ̀ kan. Ọkọ̀ náà yíò pa ẹbí Nóà mọ́ láì léwu lákokò ìkún-omi.
Ẹbí Nóà gbé oúnjẹ wá sí inú ọkọ̀ náà. Olúwa rán ó kéréjù onírúurú ẹranko méjì fún Nóà láti fi sínú ọkọ̀ náà. Lẹ́hìnnáà òjò bẹ̀rẹ̀ síí rọ̀.
Òjò rọ̀ fún ogójì ọjọ́ àti ogójì òru. Ìkún-omi borí ilẹ̀-ayé, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti ṣe ìkìlọ̀.
Ẹbí Nóà àti gbogbo àwọn ẹranko inú ọkọ̀ fò láì léwu lórí omi.
Nígbàtí ìkún-omi parí, ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nóà àti ẹbí rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa fún dídá ààbò bò wọ́n. Olúwa ṣèlérí pé òun kì yíò fi ìkún omi bo ilẹ̀-ayé mọ́. Ó rán òṣùmàrè kan gẹ́gẹ́bí ìrántí ìlérí Rẹ̀.
Ojú-ewé Kíkùn
Títẹ̀lé Wòlíì Olúwa Yíò Bùkún Mi
Ìjúwe láti ọwọ́ Audrey Day
Kínni ẹ lè ṣe láti tẹ̀lé wòlíì?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2026. Yoruba. 19927 779