“Ádámù àti Éfà,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2026, 46–48.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kínní 2026
Ádámù àti Éfà
Ádámù àti Éfà ni àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọ Ọlọ́run láti wá sí ayé. Wọ́n gbé nínú Ọgbà Édẹ́nì.
Ọlọ́run jẹ́kí wọ́n jẹ èso gbogbo igi ṣùgbọ́n ọ̀kan. Bí wọ́n bá jẹ lára igi ìmọ̀ rere àti ibi, wọn yíò ní láti fi ọgba sílẹ̀ kí wọ́n sì kú nígbẹ̀hìn. Ṣùgbọ́n Sátánì purọ́ fún wọn. Ó wípé bí wọ́n bá jẹ èso, wọn yíò mọ rere kúrò nínú ibi ṣùgbọ́n wọn kò ní kú.
Éfà yàn láti jẹ èso náà.
Nígbànáà ó fún Ádámù lára èso náà Ó tún yàn láti jẹ ẹ́.
Ọlọ́run àti Jésù Krístì bẹ̀ wọ́n wò, ṣùgbọ́n Ádámù àti Éfà bẹ̀rù wọ́n sì sápamọ́. Ọlọ́run bèèrè bí wọ́n bá ti jẹ èso láti ara igi náà.
Ádámù àti Éfà wípé wọ́n jẹ́ èso. Nísisìyí wọ́n ní láti fi Ọgbà Édẹ́nì sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ní ètò kan fún wọn. Nisisìyí wọ́n mọ títọ́ kúrò nínú àṣìṣe wọ́n sì lè bí àwọn ọmọ.
Ádámù àti Éfà ṣe ìlérí láti gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run. Wọ́n kọ́ díẹ síi nípa Ọmọ Ọlọ́run, Jésù Krístì. Wọ́n ní inúdídùn nítorí Òun yíò ràn ẹbí wọ́n lọ́wọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ojú-ewé Kíkùn
Jésù Dá Ayé
Ìjúwe láti ọwọ́ Audrey Day
Kíni àwọn ohun dídùnmọ́ni jùlọ yín tí Jésù Krístì dá?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kínní 2026. Yoruba. 19919 779