“Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Lọ Ìwọ̀ Oòrùn,” Fríẹ̀ndì, Oṣù Kejìlá 2025, 26–28.
Ọ̀rọ̀ Oṣoṣù Fríẹ̀ndì , Oṣù Kejìlá 2025
Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Lọ Ìwọ̀ Oòrùn
Lẹ́hìn ikú Joseph Smith, Brigham Young àti àwọn Àpóstélì yókù darí Ìjọ. Brigham mọ̀ pé àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní láti lọ kúrò ní Nauvoo nítorí pé kò sí ààbò. Ṣùgbọ́n Olúwa fẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ parí kíkọ́ tẹ́mpìlì náà.
Nígbàtí a parí tẹ́mpìlì, ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn Ènìyàn Mímọ́ dá májẹ̀mú pẹ̀lú Olúwa a sì fi èdìdì di wọn gẹ́gẹ́bí àwọn ẹbí.
Báyi ó tó àkókò láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjo wọn sí ìwọ̀-oòrùn. Ojú ọjọ́ tutù, àti pé àìsàn àti ebi npa àwọn ènìyàn.
Brigham gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Olúwa wípé kí wọ́n ran ara wọ́n lọ́wọ́, àti pé Òun yíò bùkún wọn Òun yíò sì ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ìrìnàjò náà tún le púpọ̀ ṣíbẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn kú. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wọn, àwọn Ènìyàn Mímọ́ mọ̀ pé àwọn yíò tún rí àwọn ọmọ ẹbí wọn lẹ́ẹ̀kan síi.
Àwọn Ènìyàn Mímọ́ àkọ́kọ́ dé àfonífojì Salt Lake ní ọdún 1847. Ní ìhìn wọ́n lè sin Olúwa kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ Rẹ̀ ní àlàáfíà.
Ní àwọn ọdún díẹ̀, àwọn Ènìyàn Mímọ́ díẹ̀ sì dé tí wọ́n sì kọ́ àwọn tẹ́mpìlì púpọ̀ síi. Àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere rìn káàkiri àgbáyé láti kọ́ni ní ìhìnrere ti Jésù Krístì. Ìjọ Olùgbàlà tẹ̀síwájú láti dàgbà, ní bíbùkún fún àwọn ọmọ Bàbá Ọ̀run ní ibi gbogbo.
Ojú-ewé Kíkùn
Òun ni Ìmọ́lẹ̀, Ìyè, àti Ìrètí ti Àgbáyé
Ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert
Kíni ẹ̀ nṣe ní Kérésìmesì láti rántí Jésù Krístì?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejìlá 2025. Yoruba. 19637 779