2025
Jane Manning Rin Ìrìnàjò lọ sí Nauvoo
Oṣù Kẹwàá 2025


“Jane Manning Rin Ìrìnàjò lọ sí Nauvoo,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹwa 2025, 26–28.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹwa 2025

Jane Manning Rin Ìrìnàjò lọ sí Nauvoo

Ọkùnrin kan nṣe ìrìbọmi Jane Manning ní àgbékalẹ̀ òde kan

Níbití Jane Manning ngbé, àwọn ènìyàn kan nhùwà búburú síi nítorí àwọ̀ ara rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, ó gbọ́ tí ìránṣẹ́ ìhìnrere kan nkọ́ni. Láìpẹ́ ó ṣe ìrìbọmi.

Jane àti ẹbí rẹ̀ dúró létí bèbè nítòsí ọkọ̀ ojú omi

Ẹbí Jane ṣe ìrìbọmi bákannáà. Gbogbo wọn nfẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Nauvoo. Nítorínáà wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

Jane àti ẹbí rẹ̀ gbé àwọn àpò wọ́n sì nwo ọkọ̀ ojú omi bí ó ti nlọ ní ìsàlẹ̀ odò

Ẹbí Jane nfẹ́ láti rin ìrìnàjò nípa ọkọ̀ ojú omi fún ara ìrìnàjò náà, ṣùgbọ́n wọn kò ní owó tó tó. Nítorínáà wọ́n rin máìlì igba mẹ́rin (ẹgbẹ̀rún ó lé ọgọ́ọ̀rún mẹ́ta kilómítà).

Jane àti ẹbí rẹ̀ nrìn nínú àwọn bàtà gbígbó àti aṣọ ẹrẹ̀

Wọ́n ní láti sọdá odò ṣíṣàn tó jìn tí wọ́n sì sùn síta nínú òtútù. Ṣùgbọ́n wọ́n pinnu láti dé Nauvoo. Wọ́n dá ara wọn lóríyá nípa kíkọrin bí wọ́n ṣe nrìn.

Jane yí bándéjì mọ́ ẹsẹ̀ ọkùnrin kan

Ẹbí Jane rìn títí tí àwọn bàtà wọn fi gbó tán tí ẹsẹ̀ wọn sì ní ìpàlára. Ṣùgbọ́n wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́, Ó si wo ẹsẹ̀ wọn sàn.

Ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn kan nwo Jane pẹ̀lú obìnrin tí ó di ọmọ tí ó nṣe àárẹ̀ mú

Wọ́n ran àwọn ènìyàn tí wọ́n pàdé ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà lọ́wọ́. Àní wọ́n ran ọmọ tí ó nṣe àárẹ̀ lọ́wọ́ nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

Jane dìmọ́ Emma Smith pẹ̀lú Joseph Smith tí ó nrẹrin

Ní ìparí, Jane àti ẹbí rẹ̀ dé Nauvoo! Nígbàtí Joseph Smith gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ti là kọjá, wí fún Jane pé, “Ọlọ́run a bùkún ọ. O wà ní àárín àwọn ọ̀rẹ́ bayìí.”

Ojú-ewé Kíkùn

Jésù Nfẹ́ Kí N Fẹ́ràn Gbogbo Ènìyàn

Ojú-ewé Kíkùn PDF ti àwọn ọmọ méjì tí wọ́n joko papọ̀ ní orí àga

Ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert

Báwo ni ẹ ṣe le fi hàn pé ẹ fẹ́ràn àwọn ẹlòmíràn?