“Ẹ̀wọ̀n Liberty,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹjọ 2025, 26–28.
Àwọn ọ̀rọ̀ oṣoòṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Kẹjọ 2025
Ẹ̀wọ̀n Liberty
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní Missouri kò fẹ́ràn àwọn ènìyàn mímọ́. Gómìnà rán àwọn ọmọ-ogun láti mú kí wọ́n lọ.
Àwọn ọmọ-ogun mú Joseph Smith àti àwọn olórí Ìjọ míràn. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ẹ̀ṣọ́ nrẹ́rin nípa àwọn ohun búburú tí wọ́n ti ṣe sí àwọn Ènìyàn-Mímọ́.
Joseph dìde ó sì kígbe, “Ìdákẹ́jẹ́!” Ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú agbára Ọlọ́run. Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà bẹ̀bẹ̀ wọ́n sì dẹ́kun ọ̀rọ̀ sísọ.
Lẹ́hìnwá, wọ́n fi Jósẹ́fù àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí ẹ̀wọ̀n ní ìlú kan tí a pè ní Liberty. Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tutù, ó kéré, ó sì dúdú. Koríko ẹlẹ́gbin nìkan ni wọ́n ní láti sùn lé lórí. Oúnjẹ tí wọ́n fún wọn mú wọn ṣàìsàn.
Joseph ṣàníyàn nìtorí àwọn Ènìyàn-Mímọ́. Ṣùgbọ́n kò le ṣe ohunkohun láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Joseph gbàdúrà púpọ̀. Ó béèrè bóyá Ọlọ́run ti gbàgbé nípa òun àti àwọn ọmọ Ìjọ.
Ọlọ́run dáhùn àdúrà Joseph. Ó wí pé, “Ọmọ mi, àlàáfíà ni fún ọkàn rẹ.” Ọlọ́run sọ fún Joseph pé àwọn ìpọ́njú rẹ̀ kì yíò wà títí láé àti pé yíò jẹ́ fún rere rẹ̀. Ó ṣèlérí pé òun yíò wà pẹ̀lú Joseph “láé àti títí láéláé” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 121:7, 46).
Ojú-ewé Kíkùn
Mo Lè Jẹ́ Bíi Ìmọ́lẹ̀ Kan Sí Àwọn Ẹlòmíràn
Ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert
Báwo ni o ṣe jẹ́ àpẹrẹ rere fún àwọn elòmíràn?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ oṣoòṣù, Oṣù Kẹjọ 2025. Yoruba. 19642 779