2025
Àwọn Àpóstélì Sin Míṣọ̀n kan lọ sí Great Britain
Oṣù Kárún 2025


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì , Oṣù Keje 2025

Àwọn Àpóstélì Sin Míṣọ̀n kan lọ sí Great Britain

Joseph Smith nfojú-inú wo àwòrán àwọn Àpóstélì tí wọ́n nwàásù ní Great Britain

Olúwa wí fún Joseph Smith láti rán àwọn kan lára ​​àwọn Àpóstélì lọ ní míṣọ̀n kan sí Great Britain. Ó ṣòro fún àwọn Àpóstélì láti fi àwọn ìdílé wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa ṣèlérí láti bùkún wọn.

Ẹbí Kimball ṣàìsàn lórí ibùsùn

Heber C. Kimball àti ìyàwó rẹ, Vilate, ní ẹbí ọ̀dọ́ kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn ló ṣàìsàn gan-an.

Brigham Young nwípé ó dàbọ̀ sí ẹbí rẹ̀

Brigham Young tún ṣàìsàn, àti pé ẹbí rẹ́ jẹ́ tálákà. Ṣùgbọ́n ìyàwó Brigham, Mary Ann, wí fún un pé, “Lọ ṣe iṣẹ míṣọ̀n rẹ, Olúwa yíò bùkún fún ọ.”

Heber àti Brigham nyí-kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀hìn kẹ̀kẹ́-akẹ́rù kan

Ara Heber àti Brigham yá si, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ aláìlágbára gan an. Wọ́n fẹ́ láti wàásù ìhìnrere, nítorí náà wọ́n dágbére fún àwọn ẹbí wọn, wọ́n sì gun ẹ̀hìn kẹ̀kẹ́-akẹ́rù kan láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn.

Heber àti Brigham nwàásù ìhìnrere náà fún àwọn ènìyàn ní Great Britain

Lẹ́hìn ìrin-àjò gígùn kan sọdá òkun, Heber ati Brigham dé sí Great Britain. Pẹ̀lú àwọn Àpóstélì míràn, wọ́n kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ní ìhìnrere. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn ni ó ṣe ìrìbọmi sínú Ìjọ Jésù Krístì. Ọ̀pọ̀ nínú wọn wakọ̀ sọdá òkun láti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ ní United States.

Àwọn ẹbí Heber àti Brigham nkí wọn ní ibi ìdúró

Olúwa mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ láti tọ́jú àwọn ẹbí Heber àti Brigham nígbàtí wọ́n nsìn Ín gẹ́gẹ́bí òjíṣẹ́ ìhìnrere.

Ojú-ewé Kíkùn

Ọlọ́run Dá Gbogbo Ẹ̀dá Sórí Ilẹ̀ Ayé

Ṣíṣe ìṣe kíkùn ti ológbò, labalábá, àti ojú-ìwé àwọn òdòdó PDF

ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert

Kíni ẹ̀dá tí o fẹ́ràn jùlọ?