Ọ̀rọ̀ Oṣoóṣù Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹfà 2025
Kíkọ́ Tẹ́mpìlì Kirtland.
Olúwa sọ fún Joseph Smith pé ó tó àkókò láti kọ́ tẹ́mpìlì ní Kirtland, Ohio, USA. Yóò jẹ́ ibi pàtàkì kan níbi tí Olúwa yóò ti bẹ àwọn ènìyàn Rẹ̀ wò tí yóò sì ṣe àwọn ìlérí pẹ̀lú wọn.
Àwọn ènìyàn mímọ́ bẹ̀rẹ̀ láti kọ́ tẹ́mpìlì náà. Ó gba owó púpọ̀ ó sì gba iṣẹ́ púpọ̀. Ṣùgbọ́n inú wọn dùn láti gba àwọn ìbùkún Olúwa.
Bí àwọn ènìyàn mímọ́ ṣe nṣiṣẹ́ lórí tẹ́mpìlì, owó bẹ̀rẹ̀ sí í tán lọ́wọ́ wọn. Wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́.
Obìnrin kan tí ó njẹ́ Caroline Tippets àti ìdílé rẹ̀ ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó pamọ́. Wọ́n jẹ́ kí Ìjọ yá owó láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti kọ́ tẹ́mpìlì náà.
Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ṣiṣẹ́ takuntakun. Àwọn kan wa àwọn kẹ̀kẹ́-ẹrù tó kún fún òkúta. Àwọn míràn ṣe aṣọ àti oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ náà.
Àwọn ọmọdé kó àwọn àfọ́kù gíláàsì fífọ́ jọ láti jẹ́ lílọ̀ kí wọ́n sì fi sí ara àwọn ògiri tẹ́mpìlì kí wọn ó lè máa tàn yinrin nínú oòrùn.
Láìpẹ́ tẹ́mpìlì di píparí! Inú àwọn Ènìyàn Mímọ́ dùn láti lọ sínú ilé Olúwa láti gba àwọn ìbùkún tí Ó ti ṣèlérí fún wọn.
Ojú-ewé Kíkùn
Olúwa Mọ Ẹni Tí Èmi Jẹ́ Ó sì Fẹ́ràn Mi
ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert
Ẹ ya àwòrán ojú yín ní ófáàlì. Báwo ni ẹ ṣe mọ̀ pé Jésù Krístì fẹ́ràn yín?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Osù Kẹfà 2025. Yoruba. 19643 779