“Lucy Wá Àwọn Òtítọ́ náà rí,” Frẹ́ndì, Oṣù Kẹrin 2025, 26–28.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì Oṣù Kẹ́rin, 2025
Lucy Wá Àwọn Òtítọ́ náà rí
Ní ọjọ́ kan, Lucy Morley ọmọ-ọdún-márundínlógún nran aládúùgbò rẹ̀, Abigail Daniels, lọ́wọ́ láti hun aṣọ. Bí wọ́n ṣe nṣiṣẹ́, àwọn missínárì mẹ́ta kanlẹ̀kùn. Wọ́n sọ wípé Jésù Krístì ni ó rán wọn láti pín ọ̀rọ̀ kan.
Àwọn ọkùnrin náà sọ fún Abigail àti Lucy pé Jésù ti pe Joseph Smith láti jẹ́ wòlíì. Wọ́n sọ fún wọn bákannáà nípa Ìwé ti Mọ́mọ́nì.
Ó ya Lucy lẹ́nu pé, Abigail bínú. Ó mú kí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere náà kúrò.
Lucy mọ̀ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere náà jẹ́. Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n bẹ ẹbí òun wò lójú ọ̀nà.
Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere náà lọ sí ilé Morley. Àwọn òbí Lucy pe àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere náà láti kọ́ wọn àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn.
Lálẹ́ ọjọ́ náà, ènìyàn mẹ́tàdínlógún ló ṣe ìrìbọmi. Ní àwọn ọjọ́ méèlo kan síi, lílé ní àádọ́ta ènìyàn gbọ́ àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere wọ́n sì ṣe ìrìbọmi. Àní Abigail aládúùgbò Lucy yí èrò rẹ̀ padà. Òun àti ọkọ rẹ̀, lẹgbẹ pẹ̀lú Lucy àti àwọn ọmọ ẹbí rẹ̀, yàn láti tẹ̀lé Jésù Krístì nípa ṣíṣe ìrìbọmi.
Ojú-ewé Kíkùn
Nítorí Jésù Krístì, Èmi Yíò Jínde
ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert
Báwo ni ẹ ṣe nrántí Jésù ní akokò Ọdún Àjínde?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹ̀ẹ́sì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀pada-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì , Oṣù Kẹ́rin, 2025. Yoruba. 19631 779