2025
A Mú Oyè-àlùfáà Padàbọ̀sípò
Oṣù Kẹta 2025


“A Mú Oyè-àlùfáà Padàbọ̀sípò,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2025, 26–28.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹta 2025

A Mú Oyè-àlùfáà Padàbọ̀sípò

Ẹ le ka ìtàn yí nínú Ìwé-ìtàn—Josèph Smith 1:66–73 àti Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 27:12.

Joseph Smith nbá Oliver Cowdery sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bọ́bù àfinúrò tó nṣe àfihàn Krístì tó nbẹ Àwọn Ará Néfì wò.

Lẹ́hìn ti Joseph Smith ti gba àwọn àwo wúrà náà, ó bẹ̀rẹ̀ láti máa ṣe ìyírọ̀padà-èdè wọn. Oliver Cowdery kọ ohun tí ó sọ sílẹ̀. Bí wọ́n ti nṣiṣẹ́, wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ pé Jésù Krístì fẹ́ kí gbogbo ènìyàn jẹ́ rírìbọmi.

Joseph Smith àti Oliver Cowdery ngbàdúra nínú igbó àwọn igi.

Joseph àti Oliver ronú nípa ẹnití ó ní agbára Ọlọ́run láti ri àwọn ènìyàn bọmi. Wọ́n lọ sínú igbó àwọn igi láti gbàdúrà àti láti béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run.

Angẹ́lì pẹ̀lú àwọn ọwọ́ rẹ̀ ní orí Joseph Smith.

Bí wọ́n ti ngbàdúrà, ángẹ́lì kan farahàn. Ó wí pé òun ni Jòhánnù Onítẹ̀bọmi, ẹnití ó ri Jésù Krístì bọmi ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn. Ó fún Joseph àti Oliver ní Oyè Àlùfáà Áárónì kí wọn ó le ri àwọn ẹlòmíràn bọmi. Oyè-àlùfáà Jẹ́ agbára Ọlọ́run. Ó njẹ́ lílò láti bùkún àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Joseph Smith nri Oliver Cowdery bọmi

Jòhánnù Onítẹ̀bọmi sọ fún Joseph àti Oliver láti jẹ́ rírìbọmi. Wọ́n lọ sí ibi odò kan wọ́n sì ṣe ìrìbọmi fún ara wọn. Nígbàtí wọ́n jáde kúrò nínú omi, wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Inú wọn dùn gidi!

Àwọn angẹ́lì mẹ́ta gbé ọwọ́ wọn lé orí Joseph Smith.

Lẹ́hìnwá, àwọn ángẹ́lì míràn wá. Mẹ́ta nínú àwọn Àpóstélì Jésù Krístì—Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù—fún Joseph àti Oliver ní Oyè-àlùfáà Mẹlkísẹ́dẹ́kì. Nísisìyí Joseph àti Oliver le fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.

Ojú-ewé Kíkùn

Jésù Fẹ́ràn Orin inú Ọkàn

Ọkàn pẹ̀lú àwọn àkọsílẹ̀ orin

ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert

Báwo ni ẹ ṣe nmọ̀lára nígbàtí ẹ bá nkọrin nípa Jésù Krístì?