“Joseph Smith Gba Àwọn Àwo Idẹ,” Fríẹ́ndì, Oṣù Keji 2025, 26–28.
“Mo Lè Jẹ́ Ẹlẹri Kan Pé Ìwé ti mọ́mọ́nì Jẹ́ Òtítọ́,” Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2025, 48.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Frẹ́ndì , Oṣù Kejì 2025
Joseph Smith Gba Àwọn Àwo Idẹ
Ẹ le ka ìtàn yí nínú Ìwé-ìtàn—Josèph Smith 1:28–60.
Ọdún mẹ́ta lẹ́hìn Ìran Àkọ́kọ́, Joseph Smith ní ìmọ̀lára búburú nípa àwọn àṣiṣe kan tí ó ti ṣe. Ó gbàdúrà sí Baba Ọ̀run nípa rẹ̀.
Nígbàtí Joseph ngbàdúra, ìmọ́lẹ̀ kún inú yàrá. Ó rí ángẹ́lì kan tí ó dúró nínú afẹ́fẹ́. Orúkọ ángẹ́lì náà ni Mórónì.
Mórónì wípé ìwé kan wà tí a ṣe ní àwọn ojú-ewe idẹ́, tàbí àwọn àwo. A rìí mọ́lẹ̀ nínú òkè kan nítòsí ilé Jósẹ́fù. Ìwé náà jẹ́ nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n gbé nínú àwọn Amẹ́ríkà tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn. Mórónì wípé Ọlọ́run yíò ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti ṣe ìyírọ̀padà ìwé náà.
Joseph lọ sí òkè náà ó sì rí àwọn àwò náà lábẹ́ òkúta wíwúwo kan. Mórónì wá ó sì wípé Joseph kò ṣetán láti gbà wọ́n síbẹ̀.
Nígbàtí Joseph dàgbà si, Mórónì pàdé rẹ̀ lórí òkè ó sì fún un ní àwọn àwo náà. Mórónì wí fún Joseph láti pa wọ́n mọ́ ní àìléwu.
Joseph bẹ̀rẹ̀ ìyírọ̀padà àwọn àwò náà sí Èdè-gẹ̀ẹ́sì. Ó lo àwọn ohun-èlò pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ràn án lọ́wọ́. Ìwé náà ni a tẹ̀jáde ní 1830 bí Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó kọ́ni nípa Jésù Krístì àti Ìhìnrere Rẹ̀.
Ojú-ewé Kíkùn
Èmi Lè Jẹ́ Ẹlẹri Kan Pé Ìwé ti mọ́mọ́nì Jẹ́ Òtítọ́
ìjúwe láti ọwọ́ Corey Egbert
Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Jésù Krístì nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì?
© 2025 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kejì 2025. Yoruba. 19641 779