“Néfì Ngbàdúrà fún àwọn Ènìyàn náà,” Friendì, Oṣù Kẹsan 2024, 26–27.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ̀ndì, Oṣù Kẹsan 2024
Néfì Ngbàdúrà fún àwọn Ènìyàn náà
Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Andrew Bosley
Néfì jẹ́ wòlíì kan. A fun lorúkọ àpètẹ̀lé Néfì ẹnití ó gba àwọn àwo ide. Ó ní ìdàmú nípa àwọn ènìyàn náà. Wọ́n ti dáwọ́dúró ní títẹ̀lé Ọlọ́rún.
Néfì lọ sínú ọgbà rẹ̀. Ó gun ilé-ìṣọ́ kan nínú ọgbà náà ó sì gbàdúrà sí Ọlọ́run níbẹ̀. Ó gbàdúrà fún àwọn ènìyàn náà.
Àwọn ènìyàn kan ṣe àkíyèsí Néfì lórí ilé-ìṣọ́. Wọ́n dúró láti fetísílẹ̀ wọ́n sì kó àwọn ẹlòmíràn jọ papọ̀ láti gbọ́. Nígbàtí Néfì parí gbígbàdúrà, ó ṣe àkíyèsí pé wọ́n nwòó ó sì bẹ̀rẹ̀sí í kọ́ wọn.
Néfì ní kí àwọn ènìyàn náà ronúpìwàdà Díẹ̀ lára wọn kò fẹ́ràn ohún tí Néfì kọ́ni. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn fetísílẹ̀! Wọ́n yàn láti ronúpìwàdà wọ́n sì yí àwọn ọ̀nà wọn padà.
Kíkùn Ojú-ewé
Jésù Kó Wa Jọ Bí Àgbébọ̀ Ti Nkó Awọn Ọmọ Rẹ̀ Jọ
Ìjúwe láti ọwọ́ Adam Koford
Báwo ni ẹ ṣe nní ìmọ̀lára ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jésù Krístì?
© 2024 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀pada ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fríẹ́ndì, Oṣù Kẹsan 2024. Yoruba. 19357 779