2021
Jésù Kẹ́kọ̀ọ́ Ó sì Dàgbà
Oṣù Kínní (ṣẹrẹ) 2021


“Jésù Kẹ́kọ̀ọ́ Ó sì Dàgbà,” Ọ̀rẹ́, Oṣù Ìkínní (Ṣẹ́rẹ́) 2021

Àwọn Ìtàn Ìwé Mímọ́

Jésù Kẹ́kọ̀ọ́ Ó sì Dàgbà

Jésù ọmọ-ọwọ́

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Apryl Stott

A bí Jésù bí ọmọ-ọwọ́ kékeré kan. Èmi náà jẹ́ ọmọ-ọwọ́ nígbàkan!

Mary, Joseph, àti Jésù ọmọ-ọwọ́

Mary àti Joseph ṣèrànwọ́ láti tọ́jú Jésù. Tani ó nṣèrànwọ́ láti tọ́jú mi?

Joseph àti Jésù kékeré

Jésù dàgbà ní àwọn ọ̀nà kannáà tí èmi ndàgbà. Ó dàgbà nínú ọgbọ́n. Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ó kọ́ àwọn ohun titun.

Jésù kékeré

Ó dàgbà nínú ìwọ̀n. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ara Rẹ̀ tóbi si.

Jésù kékeré nṣe àṣàrò

Ó dàgbà nínú ojúrere pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ó kọ́ nípa Baba Ọ̀run. Ó kọ́ láti gbàdúrà. Ó ka àwọn ìwé mímọ

Jésù kékeré pẹ̀lú àwọn ọmọdé míràn

Ó dàgbà nínú ojúrere pẹ̀lú ènìyàn. Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ó dá àwọn ọ̀rẹ́ titun. Ó ní inúrere sí àwọn ẹlòmíràn. Ó ran ẹbí rẹ̀ lọ́wọ́.

àwọn ọmọdé nínú ọgbà kan

Èmi lè ran inú àti ara mi lọ́wọ́ láti dàgbà. Èmi lè kọ́ nípa Ọlọ́run. Èmi lè jẹ́ ọ̀rẹ́ rere kan. Èmi yíò dàgbà ní àwọn ọ̀nà rere, bí Jésù ti ṣe!

Kíkùn Ojú-ewé

Èmi Ndàgbà

kíkùn ojú-ewé